Kíróníkà Kìíní 19:1-19

  • Àwọn ọmọ Ámónì dójú ti àwọn òjíṣẹ́ Dáfídì (1-5)

  • Wọ́n ṣẹ́gun Ámónì àti Síríà (6-19)

19  Nígbà tó yá Náháṣì ọba àwọn ọmọ Ámónì kú, ọmọ rẹ̀ sì jọba ní ipò rẹ̀.+  Dáfídì bá sọ pé: “Màá fi ìfẹ́ tí kì í yẹ̀+ hàn sí Hánúnì ọmọ Náháṣì, nítorí bàbá rẹ̀ fi ìfẹ́ tí kì í yẹ̀ hàn sí mi.” Torí náà, Dáfídì rán àwọn òjíṣẹ́ láti lọ tù ú nínú nítorí bàbá rẹ̀ tó kú. Àmọ́ nígbà tí àwọn ìránṣẹ́ Dáfídì dé ilẹ̀ àwọn ọmọ Ámónì+ láti tu Hánúnì nínú,  àwọn ìjòyè àwọn ọmọ Ámónì sọ fún Hánúnì pé: “Ṣé o rò pé torí kí Dáfídì lè bọlá fún bàbá rẹ ló ṣe rán àwọn olùtùnú sí ọ? Ǹjẹ́ kì í ṣe torí kó lè wo inú ìlú yìí fínnífínní, kó lé ọ kúrò lórí oyè, kí ó sì ṣe amí ilẹ̀ yìí ni àwọn ìránṣẹ́ rẹ̀ fi wá sọ́dọ̀ rẹ?”  Nítorí náà, Hánúnì mú àwọn ìránṣẹ́ Dáfídì, ó fá irun wọn,+ ó gé ẹ̀wù wọn ní ààbọ̀ dé ìdí, ó sì ní kí wọ́n máa lọ.  Nígbà tí wọ́n sọ ohun tó ṣẹlẹ̀ sí àwọn ọkùnrin náà fún Dáfídì, kíá ló rán àwọn míì lọ pàdé wọn, nítorí wọ́n ti dójú ti àwọn ọkùnrin náà gan-an; ọba sì sọ fún wọn pé: “Ẹ dúró sí Jẹ́ríkò+ títí irùngbọ̀n yín á fi hù pa dà, lẹ́yìn náà kí ẹ pa dà wálé.”  Nígbà tó yá, àwọn ọmọ Ámónì rí i pé àwọn ti di ẹni ìkórìíra lójú Dáfídì, torí náà, Hánúnì àti àwọn ọmọ Ámónì fi ẹgbẹ̀rún (1,000) tálẹ́ńtì* fàdákà ránṣẹ́ láti háyà àwọn kẹ̀kẹ́ ẹṣin àti àwọn agẹṣin láti Mesopotámíà,* Aramu-máákà àti Sóbà.+  Bí wọ́n ṣe háyà ẹgbẹ̀rún méjìlélọ́gbọ̀n (32,000) kẹ̀kẹ́ ẹṣin nìyẹn pẹ̀lú ọba Máákà àti àwọn èèyàn rẹ̀. Ìgbà náà ni wọ́n wá, wọ́n sì pàgọ́ síwájú Médébà.+ Àwọn ọmọ Ámónì kóra jọ láti àwọn ìlú wọn, wọ́n sì jáde wá jagun.  Nígbà tí Dáfídì gbọ́, ó rán Jóábù+ lọ àti gbogbo àwọn ọmọ ogun títí kan àwọn jagunjagun rẹ̀ tó lákíkanjú jù lọ.+  Àwọn ọmọ Ámónì jáde lọ, wọ́n sì tò lọ́wọ̀ọ̀wọ́ ní àtiwọ ẹnubodè ìlú, àmọ́ àwọn ọba tó wá náà dúró sórí pápá. 10  Nígbà tí Jóábù rí i pé wọ́n ń gbé ogun bọ̀ níwájú àti lẹ́yìn, ó yan lára àwọn ọmọ ogun tó dára jù lọ ní Ísírẹ́lì, ó sì tò wọ́n lọ́wọ̀ọ̀wọ́ láti pàdé àwọn ará Síríà.+ 11  Ó fi àwọn tó kù lára àwọn ọkùnrin náà sábẹ́ àṣẹ* Ábíṣáì+ ẹ̀gbọ́n rẹ̀, kí ó lè tò wọ́n lọ́wọ̀ọ̀wọ́ láti pàdé àwọn ọmọ Ámónì. 12  Ó wá sọ pé: “Tí ọwọ́ àwọn ará Síríà+ bá le jù fún mi, kí o wá gbà mí sílẹ̀; àmọ́ tí ọwọ́ àwọn ọmọ Ámónì bá le jù fún ọ, màá gbà ọ́ sílẹ̀. 13  Kí a jẹ́ alágbára, kí a sì ní ìgboyà+ nítorí àwọn èèyàn wa àti àwọn ìlú Ọlọ́run wa, Jèhófà yóò sì ṣe ohun tó dára ní ojú rẹ̀.” 14  Ìgbà náà ni Jóábù àti àwọn ọkùnrin rẹ̀ jáde lọ pàdé àwọn ará Síríà lójú ogun, wọ́n sì sá kúrò níwájú rẹ̀.+ 15  Nígbà tí àwọn ọmọ Ámónì rí i pé àwọn ará Síríà ti fẹsẹ̀ fẹ, àwọn náà sá kúrò níwájú Ábíṣáì ẹ̀gbọ́n rẹ̀, wọ́n sì wọ inú ìlú lọ. Lẹ́yìn náà, Jóábù wá sí Jerúsálẹ́mù. 16  Nígbà tí àwọn ará Síríà rí i pé Ísírẹ́lì ti ṣẹ́gun àwọn, wọ́n rán àwọn òjíṣẹ́ láti pe àwọn ará Síríà tó wà ní agbègbè Odò*+ jọ, Ṣófákì olórí àwọn ọmọ ogun Hadadésà ló sì ń darí wọn.+ 17  Nígbà tí wọ́n ròyìn fún Dáfídì, lẹ́sẹ̀kẹsẹ̀, ó kó gbogbo Ísírẹ́lì jọ, ó sọdá Jọ́dánì, ó wá bá wọn, ó sì to àwọn jagunjagun rẹ̀ lọ́wọ̀ọ̀wọ́ láti dojú kọ wọ́n. Dáfídì to àwọn jagunjagun rẹ̀ lọ́wọ̀ọ̀wọ́ láti pàdé àwọn ará Síríà, wọ́n sì bá a jà.+ 18  Àmọ́, àwọn ará Síríà sá kúrò níwájú Ísírẹ́lì; Dáfídì pa ẹgbẹ̀rún méje (7,000) àwọn tó ń gun kẹ̀kẹ́ ẹṣin àti ọ̀kẹ́ méjì (40,000) àwọn ọmọ ogun Síríà tó ń fẹsẹ̀ rìn, ó sì pa Ṣófákì olórí àwọn ọmọ ogun wọn. 19  Nígbà tí àwọn ìránṣẹ́ Hadadésà rí i pé Ísírẹ́lì ti ṣẹ́gun àwọn,+ wọ́n tètè wá àlàáfíà lọ́dọ̀ Dáfídì, wọ́n sì di ọmọ abẹ́ rẹ̀;+ àwọn ará Síríà ò sì fẹ́ ran àwọn ọmọ Ámónì lọ́wọ́ mọ́.

Àlàyé Ìsàlẹ̀ Ìwé

Tálẹ́ńtì kan jẹ́ kìlógíráàmù 34.2. Wo Àfikún B14.
Ní Héb., “Aramu-náháráímù.”
Ní Héb., “sí ọwọ́.”
Ìyẹn, odò Yúfírétì.