Kíróníkà Kìíní 2:1-55
2 Àwọn ọmọ Ísírẹ́lì+ nìyí: Rúbẹ́nì,+ Síméónì,+ Léfì,+ Júdà,+ Ísákà,+ Sébúlúnì,+
2 Dánì,+ Jósẹ́fù,+ Bẹ́ńjámínì,+ Náfútálì,+ Gádì+ àti Áṣérì.+
3 Àwọn ọmọ Júdà ni Éérì, Ónánì àti Ṣélà. Àwọn mẹ́ta yìí ni ọmọbìnrin Ṣúà ará Kénáánì+ bí fún un. Àmọ́, inú Jèhófà ò dùn sí Éérì àkọ́bí Júdà, torí náà Ó pa á.+
4 Támárì+ ìyàwó ọmọ Júdà bí Pérésì+ àti Síírà fún un. Gbogbo àwọn ọmọ Júdà jẹ́ márùn-ún.
5 Àwọn ọmọ Pérésì ni Hésírónì àti Hámúlù.+
6 Àwọn ọmọ Síírà ni Símírì, Étánì, Hémánì, Kálíkólì àti Dárà. Gbogbo wọn jẹ́ márùn-ún.
7 Ọmọ* Kámì ni Ákárì,* ẹni tó mú àjálù* bá Ísírẹ́lì+ nígbà tó hùwà àìṣòótọ́ torí ó mú ohun tí wọ́n fẹ́ pa run.+
8 Ọmọ* Étánì ni Asaráyà.
9 Àwọn ọmọ Hésírónì ni Jéráméélì,+ Rámù+ àti Kélúbáì.*
10 Rámù bí Ámínádábù. Ámínádábù+ bí Náṣónì,+ ìjòyè àwọn ọmọ Júdà.
11 Náṣónì bí Sálímà.+ Sálímà bí Bóásì.+
12 Bóásì bí Óbédì. Óbédì bí Jésè.+
13 Jésè bí àkọ́bí rẹ̀ Élíábù, ìkejì Ábínádábù,+ ìkẹta Ṣíméà,+
14 ìkẹrin Nétánélì, ìkarùn-ún Rádáì,
15 ìkẹfà Ósémù àti ìkeje Dáfídì.+
16 Àwọn arábìnrin wọn ni Seruáyà àti Ábígẹ́lì.+ Àwọn ọmọ Seruáyà ni Ábíṣáì,+ Jóábù+ àti Ásáhélì,+ àwọn mẹ́ta.
17 Ábígẹ́lì bí Ámásà,+ bàbá Ámásà sì ni Jétà ọmọ Íṣímáẹ́lì.
18 Ásúbà ìyàwó Kélẹ́bù* ọmọ Hésírónì bí àwọn ọmọ fún un, Jéríótì tún bímọ fún un; àwọn ọmọ rẹ̀ ni: Jéṣà, Ṣóbábù àti Árídónì.
19 Nígbà tí Ásúbà kú, Kélẹ́bù fẹ́ Éfúrátì,+ ó sì bí Húrì+ fún un.
20 Húrì bí Úráì. Úráì bí Bẹ́sálẹ́lì.+
21 Lẹ́yìn náà, Hésírónì ní àṣepọ̀ pẹ̀lú ọmọbìnrin Mákírù+ bàbá Gílíádì,+ ó sì bí Ségúbù fún un. Ẹni ọgọ́ta (60) ọdún ni Hésírónì nígbà tí ó fẹ́ ẹ.
22 Ségúbù bí Jáírì,+ ẹni tó ní ìlú mẹ́tàlélógún (23) ní ilẹ̀ Gílíádì.+
23 Lẹ́yìn náà, Géṣúrì+ àti Síríà+ gba Hafotu-jáírì+ lọ́wọ́ wọn, pẹ̀lú Kénátì+ àti àwọn àrọko rẹ̀,* ọgọ́ta (60) ìlú. Gbogbo àwọn yìí ni àtọmọdọ́mọ Mákírù bàbá Gílíádì.
24 Lẹ́yìn tí Hésírónì+ kú ní Kelẹbu-éfúrátà, Ábíjà ìyàwó Hésírónì bí Áṣíhúrì+ bàbá Tékóà+ fún un.
25 Àwọn ọmọ Jéráméélì àkọ́bí Hésírónì ni Rámù àkọ́bí, Búnà, Órénì, Ósémù àti Áhíjà.
26 Jéráméélì ní ìyàwó míì, orúkọ rẹ̀ ni Átárà. Òun ni ìyá Ónámù.
27 Àwọn ọmọ Rámù àkọ́bí Jéráméélì ni Máásì, Jámínì àti Ékérì.
28 Àwọn ọmọ Ónámù ni Ṣámáì àti Jádà. Àwọn ọmọ Ṣámáì ni Nádábù àti Ábíṣúrì.
29 Orúkọ ìyàwó Ábíṣúrì ni Ábíháílì, òun ló bí Ábánì àti Mólídì fún un.
30 Àwọn ọmọ Nádábù ni Sélédì àti Ápáímù. Àmọ́ Sélédì kú láìní ọmọ.
31 Ọmọ* Ápáímù ni Íṣì. Ọmọ* Íṣì ni Ṣéṣánì, ọmọ* Ṣéṣánì sì ni Áláì.
32 Àwọn ọmọ Jádà àbúrò Ṣámáì ni Jétà àti Jónátánì. Àmọ́, Jétà kú láìní ọmọ.
33 Àwọn ọmọ Jónátánì ni Péléétì àti Sásà. Àwọn yìí ni àtọmọdọ́mọ Jéráméélì.
34 Ṣéṣánì kò ní ọmọkùnrin kankan, àfi àwọn ọmọbìnrin. Ṣéṣánì ní ìránṣẹ́ kan tó jẹ́ ará Íjíbítì, Jááhà ni orúkọ rẹ̀.
35 Ṣéṣánì wá fún Jááhà ìránṣẹ́ rẹ̀ ní ọmọbìnrin rẹ̀ pé kó fi ṣe aya, ó sì bí Átáì fún un.
36 Átáì bí Nátánì. Nátánì bí Sábádì.
37 Sábádì bí Éfílálì. Éfílálì bí Óbédì.
38 Óbédì bí Jéhù. Jéhù bí Asaráyà.
39 Asaráyà bí Hélésì. Hélésì bí Éléásà.
40 Éléásà bí Sísímáì. Sísímáì bí Ṣálúmù.
41 Ṣálúmù bí Jekamáyà. Jekamáyà bí Élíṣámà.
42 Àwọn ọmọ Kélẹ́bù*+ àbúrò Jéráméélì ni Méṣà àkọ́bí rẹ̀ tí ó jẹ́ bàbá Sífù àti àwọn ọmọ Máréṣà bàbá Hébúrónì.
43 Àwọn ọmọ Hébúrónì ni Kórà, Tápúà, Rékémù àti Ṣímà.
44 Ṣímà bí Ráhámù bàbá Jọ́kéámù. Rékémù bí Ṣámáì.
45 Ọmọ Ṣámáì ni Máónì. Máónì sì ni bàbá Bẹti-súrì.+
46 Eéfà wáhàrì* Kélẹ́bù bí Háránì, Mósà àti Gásésì. Háránì bí Gásésì.
47 Àwọn ọmọ Jáádáì ni Régémù, Jótámù, Géṣánì, Pélétì, Eéfà àti Ṣááfà.
48 Máákà wáhàrì Kélẹ́bù bí Ṣébérì àti Tíhánà.
49 Nígbà tó yá, ó bí Ṣááfà bàbá Mádímánà+ àti Ṣéfà bàbá Mákíbénà pẹ̀lú Gíbéà.+ Ọmọbìnrin Kélẹ́bù+ sì ni Ákúsà.+
50 Àwọn yìí ni àtọmọdọ́mọ Kélẹ́bù.
Àwọn ọmọ Húrì+ àkọ́bí Éfúrátà+ ni Ṣóbálì bàbá Kiriati-jéárímù,+
51 Sálímà bàbá Bẹ́tílẹ́hẹ́mù+ àti Háréfì bàbá Bẹti-gádérì.
52 Ṣóbálì bàbá Kiriati-jéárímù ní àwọn ọmọ, àwọn ni: Háróè àti ìdajì àwọn Mẹ́núhótì.
53 Àwọn ìdílé Kiriati-jéárímù ni àwọn Ítírì,+ àwọn Púútì, àwọn Ṣúmátì àti àwọn Míṣíráì. Inú àwọn yìí ni àwọn Sórátì+ àti àwọn ará Éṣítáólì+ ti wá.
54 Àwọn ọmọ Sálímà ni Bẹ́tílẹ́hẹ́mù,+ àwọn ará Nétófà, Atiroti-bẹti-jóábù, ìdajì àwọn ọmọ Mánáhátì àti àwọn Sórítì.
55 Ìdílé àwọn akọ̀wé òfin tó ń gbé ní Jábésì ni àwọn Tírátì, àwọn Ṣímíátì àti àwọn Súkátì. Àwọn yìí ni àwọn Kénì+ tó wá láti Hémátì bàbá ilé Rékábù.+
Àlàyé Ìsàlẹ̀ Ìwé
^ Tàbí “wàhálà; ìtanù.”
^ Ní Héb., “Àwọn ọmọ.”
^ Ní Héb., “Àwọn ọmọ.”
^ Wọ́n tún pè é ní Kélẹ́bù ní ẹsẹ 18, 19, 42.
^ Tí wọ́n pè ní Kélúbáì ní ẹsẹ 9.
^ Tàbí “àwọn ìlú tó yí i ká.”
^ Ní Héb., “Àwọn ọmọ.”
^ Ní Héb., “Àwọn ọmọ.”
^ Ní Héb., “Àwọn ọmọ.”
^ Wọ́n tún pè é ní Kélúbáì ní ẹsẹ 9.
^ Tàbí “ìyàwó onípò kejì.” Wo Àlàyé Ọ̀rọ̀, “Wáhàrì.”