Kíróníkà Kìíní 23:1-32
23 Nígbà tí Dáfídì darúgbó, tí kò sì ní pẹ́ kú mọ́,* ó fi Sólómọ́nì ọmọ rẹ̀ jọba lórí Ísírẹ́lì.+
2 Lẹ́yìn náà, ó kó gbogbo àwọn ìjòyè Ísírẹ́lì jọ àti àwọn àlùfáà + pẹ̀lú àwọn ọmọ Léfì.+
3 Wọ́n ka iye+ àwọn ọmọ Léfì láti ẹni ọgbọ̀n (30) ọdún sókè; iye àwọn ọkùnrin tí wọ́n kà lọ́kọ̀ọ̀kan jẹ́ ẹgbẹ̀rún méjìdínlógójì (38,000).
4 Ẹgbẹ̀rún mẹ́rìnlélógún (24,000) lára wọn ń ṣe alábòójútó lórí iṣẹ́ ilé Jèhófà, ẹgbẹ̀rún mẹ́fà (6,000) sì jẹ́ aláṣẹ àti onídàájọ́,+
5 ẹgbẹ̀rún mẹ́rin (4,000) jẹ́ aṣọ́bodè,+ ẹgbẹ̀rún mẹ́rin (4,000) sì ń fi àwọn ohun ìkọrin yin+ Jèhófà, èyí tí Dáfídì sọ nípa wọn pé “mo ṣe wọ́n fún kíkọ orin ìyìn.”
6 Lẹ́yìn náà, Dáfídì ṣètò* wọn sí àwùjọ-àwùjọ+ gẹ́gẹ́ bí àwọn ọmọ Léfì ṣe wà: Gẹ́ṣónì, Kóhátì àti Mérárì.+
7 Lára àwọn ọmọ Gẹ́ṣónì ni Ládánì àti Ṣíméì.
8 Àwọn ọmọ Ládánì ni Jéhíélì tó jẹ́ olórí, Sétámù àti Jóẹ́lì,+ wọ́n jẹ́ mẹ́ta.
9 Àwọn ọmọ Ṣíméì ni Ṣẹ́lómótì, Hásíélì àti Háránì, wọ́n jẹ́ mẹ́ta. Àwọn ni olórí àwọn agbo ilé Ládánì.
10 Àwọn ọmọ Ṣíméì ni Jáhátì, Sínà, Jéúṣì àti Bẹráyà. Àwọn mẹ́rin yìí ni ọmọ Ṣíméì.
11 Jáhátì ni olórí, Sísáhì sì ni ìkejì. Ṣùgbọ́n torí pé àwọn ọmọ Jéúṣì àti ti Bẹráyà kò pọ̀, agbo ilé kan ṣoṣo ni wọ́n kà wọ́n sí, wọ́n sì yan iṣẹ́ kan fún wọn láti máa bójú tó.
12 Àwọn ọmọ Kóhátì ni Ámúrámù, Ísárì,+ Hébúrónì àti Úsíélì,+ wọ́n jẹ́ mẹ́rin.
13 Àwọn ọmọ Ámúrámù ni Áárónì+ àti Mósè.+ Àmọ́ a ya Áárónì sọ́tọ̀+ láti máa sìn ní Ibi Mímọ́ Jù Lọ títí lọ, kí òun àti àwọn ọmọ rẹ̀ máa rú ẹbọ níwájú Jèhófà, kí wọ́n máa ṣe ìránṣẹ́ fún un, kí wọ́n sì máa fi orúkọ rẹ̀ súre fún àwọn èèyàn nígbà gbogbo.+
14 Ní ti Mósè èèyàn Ọlọ́run tòótọ́, wọ́n ka àwọn ọmọ rẹ̀ mọ́ ẹ̀yà àwọn ọmọ Léfì.
15 Àwọn ọmọ Mósè ni Gẹ́ṣómù+ àti Élíésérì.+
16 Nínú àwọn ọmọ Gẹ́ṣómù, Ṣẹ́búẹ́lì+ ni olórí.
17 Nínú àtọmọdọ́mọ* Élíésérì, Rehabáyà+ ni olórí; Élíésérì kò ní ọmọkùnrin míì, àmọ́ àwọn ọmọkùnrin Rehabáyà pọ̀ gan-an.
18 Nínú àwọn ọmọ Ísárì,+ Ṣẹ́lómítì+ ni olórí.
19 Àwọn ọmọ Hébúrónì ni Jeráyà tó jẹ́ olórí, Amaráyà ìkejì, Jáhásíẹ́lì ìkẹta àti Jekaméámì+ ìkẹrin.
20 Àwọn ọmọ Úsíélì+ ni Míkà tó jẹ́ olórí àti Isiṣáyà ìkejì.
21 Àwọn ọmọ Mérárì ni Máhílì àti Múṣì.+ Àwọn ọmọ Máhílì ni Élíásárì àti Kíṣì.
22 Élíásárì kú, kò ní ọmọkùnrin, àmọ́ ó ní àwọn ọmọbìnrin. Torí náà, àwọn ọmọ Kíṣì tó jẹ́ mọ̀lẹ́bí* wọn fi wọ́n ṣe aya.
23 Àwọn ọmọ Múṣì ni Máhílì, Édérì àti Jérémótì, wọ́n jẹ́ mẹ́ta.
24 Àwọn yìí ni àwọn ọmọ Léfì, bí wọ́n ṣe wà nínú agbo ilé bàbá wọn, àwọn olórí agbo ilé bàbá wọn, àwọn tí wọ́n kà, tí orúkọ wọn sì wà lákọsílẹ̀, tí wọ́n ń ṣiṣẹ́ ìsìn ní ilé Jèhófà, láti ẹni ogún (20) ọdún sókè.
25 Nítorí Dáfídì sọ pé: “Jèhófà Ọlọ́run Ísírẹ́lì ti fún àwọn èèyàn rẹ̀ ní ìsinmi,+ yóò sì máa gbé ní Jerúsálẹ́mù títí láé.+
26 Bákan náà, àwọn ọmọ Léfì kò ní máa ru àgọ́ ìjọsìn tàbí èyíkéyìí lára àwọn nǹkan èlò rẹ̀ tí wọ́n ń lò fún ìjọsìn.”+
27 Gẹ́gẹ́ bí ohun tí Dáfídì sọ kẹ́yìn pé kí wọ́n ṣe, wọ́n ka iye àwọn ọmọ Léfì láti ẹni ogún (20) ọdún sókè.
28 Iṣẹ́ wọn ni láti máa ran àwọn ọmọ Áárónì+ lọ́wọ́ lẹ́nu iṣẹ́ ìsìn ilé Jèhófà, kí wọ́n máa bójú tó àwọn àgbàlá,+ àwọn yàrá ìjẹun, mímú kí gbogbo ohun mímọ́ wà ní mímọ́ àti iṣẹ́ èyíkéyìí tó bá yọjú nínú iṣẹ́ ìsìn ilé Ọlọ́run tòótọ́.
29 Wọ́n ń ṣe búrẹ́dì onípele*+ àti ìyẹ̀fun kíkúnná tí wọ́n ń lò fún ọrẹ ọkà, wọ́n tún ń ṣe àwọn búrẹ́dì aláìwú pẹlẹbẹ+ àti àwọn àkàrà tí wọ́n fi agbada dín, wọ́n ń po ìyẹ̀fun títí á fi rọ́,+ wọ́n sì ń díwọ̀n bí nǹkan ṣe pọ̀ tó àti bí ó ṣe tóbi tó.
30 Iṣẹ́ wọn ni láti máa dúró ní àràárọ̀ + láti máa dúpẹ́, kí wọ́n sì máa yin Jèhófà, ohun kan náà ni wọ́n sì ń ṣe ní ìrọ̀lẹ́.+
31 Wọ́n ń ṣèrànwọ́ nígbàkigbà tí wọ́n bá ń rú àwọn ẹbọ sísun sí Jèhófà ní àwọn Sábáàtì,+ ní àwọn òṣùpá tuntun+ àti ní àwọn àsìkò àjọyọ̀,+ gẹ́gẹ́ bí iye àwọn tí òfin sọ nípa àwọn nǹkan yìí, wọ́n sì ń ṣe bẹ́ẹ̀ nígbà gbogbo níwájú Jèhófà.
32 Wọ́n tún ń ṣe ojúṣe wọn ní àgọ́ ìpàdé àti ní ibi mímọ́. Wọ́n sì ń ṣèrànwọ́ fún àwọn arákùnrin wọn, àwọn ọmọ Áárónì lẹ́nu iṣẹ́ ìsìn ilé Jèhófà.
Àlàyé Ìsàlẹ̀ Ìwé
^ Ní Héb., “darúgbó, tí ọjọ́ rẹ̀ sì ti kún rẹ́rẹ́.”
^ Tàbí “pín.”
^ Ní Héb., “àwọn ọmọ.”
^ Ní Héb., “arákùnrin.”
^ Ìyẹn, búrẹ́dì àfihàn.