Kíróníkà Kìíní 3:1-24

  • Àwọn àtọmọdọ́mọ Dáfídì (1-9)

  • Àwọn ọmọ tó wá láti ìdílé ọba Dáfídì (10-24)

3  Àwọn ọmọkùnrin tí wọ́n bí fún Dáfídì ní Hébúrónì+ nìyí: Ámínónì+ àkọ́bí, ìyá rẹ̀ ni Áhínóámù+ ará Jésírẹ́lì; ìkejì ni Dáníẹ́lì, ìyá rẹ̀ ni Ábígẹ́lì+ ará Kámẹ́lì;  ìkẹta ni Ábúsálómù+ ọmọ Máákà ọmọbìnrin Tálímáì ọba Géṣúrì; ìkẹrin ni Ádóníjà+ ọmọ Hágítì;  ìkarùn-ún ni Ṣẹfatáyà, ìyá rẹ̀ ni Ábítálì; ìkẹfà sì ni Ítíréámù, ìyá rẹ̀ ní Ẹ́gílà ìyàwó Dáfídì.  Àwọn mẹ́fà yìí ni wọ́n bí fún un ní Hébúrónì; ọdún méje àti oṣù mẹ́fà ló fi jọba níbẹ̀, ó sì fi ọdún mẹ́tàlélọ́gbọ̀n (33) jọba ní Jerúsálẹ́mù.+  Àwọn tí wọ́n bí fún un ní Jerúsálẹ́mù+ nìyí: Ṣíméà, Ṣóbábù, Nátánì+ àti Sólómọ́nì;+ ìyá àwọn mẹ́rin yìí ni Bátí-ṣébà+ ọmọbìnrin Ámíélì.  Àwọn ọmọ mẹ́sàn-án míì ni Íbárì, Élíṣámà, Élífélétì,  Nógà, Néfégì, Jáfíà,  Élíṣámà, Élíádà àti Élífélétì.  Gbogbo àwọn yìí ni ọmọ Dáfídì, yàtọ̀ sí àwọn ọmọ àwọn wáhàrì,* Támárì+ sì ni arábìnrin wọn. 10  Ọmọ Sólómọ́nì ni Rèhóbóámù;+ ọmọ* rẹ̀ ni Ábíjà,+ ọmọ rẹ̀ ni Ásà,+ ọmọ rẹ̀ ni Jèhóṣáfátì,+ 11  ọmọ rẹ̀ ni Jèhórámù,+ ọmọ rẹ̀ ni Ahasáyà,+ ọmọ rẹ̀ ni Jèhóáṣì,+ 12  ọmọ rẹ̀ ni Amasááyà,+ ọmọ rẹ̀ ni Asaráyà,+ ọmọ rẹ̀ ni Jótámù,+ 13  ọmọ rẹ̀ ni Áhásì,+ ọmọ rẹ̀ ni Hẹsikáyà,+ ọmọ rẹ̀ ni Mánásè,+ 14  ọmọ rẹ̀ ni Ámọ́nì,+ ọmọ rẹ̀ ni Jòsáyà.+ 15  Àwọn ọmọ Jòsáyà ni Jóhánánì àkọ́bí, ìkejì ni Jèhóákímù,+ ìkẹta ni Sedekáyà,+ ìkẹrin ni Ṣálúmù. 16  Ọmọ* Jèhóákímù ni Jekonáyà,+ Sedekáyà sì ni ọmọ rẹ̀. 17  Àwọn ọmọ Jekonáyà ẹlẹ́wọ̀n ni Ṣéálítíẹ́lì, 18  Málíkírámù, Pedáyà, Ṣẹ́násà, Jekamáyà, Hóṣámà àti Nedabáyà. 19  Àwọn ọmọ Pedáyà ni Serubábélì+ àti Ṣíméì; àwọn ọmọ Serubábélì sì ni Méṣúlámù àti Hananáyà (Ṣẹ́lómítì ni arábìnrin wọn); 20  àwọn ọmọ márùn-ún míì ni Háṣúbà, Óhélì, Berekáyà, Hasadáyà àti Juṣabi-hésédì. 21  Àwọn ọmọ Hananáyà ni Pẹlatáyà àti Jeṣáyà; ọmọ* Jeṣáyà ni Refáyà; ọmọ* Refáyà ni Áánánì; ọmọ* Áánánì ni Ọbadáyà; ọmọ* Ọbadáyà ni Ṣẹkanáyà; 22  ọmọ* Ṣẹkanáyà ni Ṣemáyà, àwọn ọmọ Ṣemáyà sì ni: Hátúṣì, Ígálì, Baráyà, Nearáyà àti Ṣáfátì, gbogbo wọn jẹ́ mẹ́fà. 23  Àwọn ọmọ Nearáyà ni Élíóénáì, Hisikáyà àti Ásíríkámù, àwọn mẹ́ta. 24  Àwọn ọmọ Élíóénáì sì ni Hodafáyà, Élíáṣíbù, Pẹláyà, Ákúbù, Jóhánánì, Deláyà àti Ánáánì, àwọn méje.

Àlàyé Ìsàlẹ̀ Ìwé

Tàbí “ìyàwó onípò kejì.” Wo Àlàyé Ọ̀rọ̀, “Wáhàrì.”
Ọ̀rọ̀ yìí ní Hébérù lè túmọ̀ sí ọmọ, ọmọ ọmọ tàbí àtọmọdọ́mọ.
Ní Héb., “Àwọn ọmọ.”
Ní Héb., “àwọn ọmọ.”
Ní Héb., “àwọn ọmọ.”
Ní Héb., “àwọn ọmọ.”
Ní Héb., “àwọn ọmọ.”
Ní Héb., “àwọn ọmọ.”