Kíróníkà Kìíní 5:1-26

  • Àwọn àtọmọdọ́mọ Rúbẹ́nì (1-10)

  • Àwọn àtọmọdọ́mọ Gádì (11-17)

  • Wọ́n ṣẹ́gun àwọn ọmọ Hágárì (18-22)

  • Ààbọ̀ ẹ̀yà Mánásè (23-26)

5  Àwọn ọmọ Rúbẹ́nì,+ àkọ́bí Ísírẹ́lì nìyí. Òun ni àkọ́bí, àmọ́ torí pé ó kó ẹ̀gàn bá ibùsùn bàbá rẹ̀,*+ ẹ̀tọ́ rẹ̀ gẹ́gẹ́ bí àkọ́bí ni a fún àwọn ọmọ Jósẹ́fù+ ọmọ Ísírẹ́lì, torí náà, wọn ò kọ orúkọ rẹ̀ sínú àkọsílẹ̀ ìdílé wọn pé òun ni àkọ́bí.  Òótọ́ ni pé Júdà+ ta yọ àwọn arákùnrin rẹ̀, ọ̀dọ̀ rẹ̀ sì ni ẹni tó máa jẹ́ aṣáájú+ ti wá, síbẹ̀ Jósẹ́fù ló ni ẹ̀tọ́ àkọ́bí.  Àwọn ọmọ Rúbẹ́nì àkọ́bí Ísírẹ́lì ni Hánókù, Pálù, Hésírónì àti Kámì.+  Àwọn ọmọ Jóẹ́lì ni Ṣemáyà, ọmọ* rẹ̀ ni Gọ́ọ̀gù, ọmọ rẹ̀ ni Ṣíméì,  ọmọ rẹ̀ ni Míkà, ọmọ rẹ̀ ni Reáyà, ọmọ rẹ̀ ni Báálì,  ọmọ rẹ̀ sì ni Bééráhì, ẹni tí Tiliga-pílínésà+ ọba Ásíríà mú lọ sí ìgbèkùn; ó jẹ́ ìjòyè àwọn ọmọ Rúbẹ́nì.  Ìdílé àwọn arákùnrin rẹ̀ bí wọ́n ṣe wà nínú àkọsílẹ̀ ìdílé wọn láti ìran dé ìran nìyí, àwọn tó jẹ́ olórí ni Jéélì, Sekaráyà 8  àti Bélà ọmọ Ásásì ọmọ Ṣímà ọmọ Jóẹ́lì, tí wọ́n ń gbé ní Áróérì+ títí dé Nébò àti Baali-méónì.+  Wọ́n gbé ní apá ìlà oòrùn títí lọ dé àtiwọ aginjù tó wà ní odò Yúfírétì,+ torí ẹran ọ̀sìn wọn ti pọ̀ gan-an ní ilẹ̀ Gílíádì.+ 10  Nígbà ayé Sọ́ọ̀lù, wọ́n bá àwọn ọmọ Hágárì jà, wọ́n sì ṣẹ́gun wọn, torí náà, wọ́n ń gbé inú àwọn àgọ́ wọn ní gbogbo ilẹ̀ tó wà ní ìlà oòrùn Gílíádì. 11  Lákòókò yìí, àwọn ọmọ Gádì ń gbé nítòsí wọn láti ilẹ̀ Báṣánì títí dé Sálékà.+ 12  Ní Báṣánì, Jóẹ́lì ni olórí, Ṣáfámù ni igbá kejì, Jánáì àti Ṣáfátì náà wà níbẹ̀. 13  Àwọn arákùnrin wọn tó wá láti agbo ilé bàbá wọn ni Máíkẹ́lì, Méṣúlámù, Ṣébà, Jóráì, Jákánì, Sáyà àti Ébérì, gbogbo wọn jẹ́ méje. 14  Àwọn ni àwọn ọmọ Ábíháílì ọmọ Húúrì, ọmọ Járóà, ọmọ Gílíádì, ọmọ Máíkẹ́lì, ọmọ Jéṣíṣáì, ọmọ Jádò, ọmọ Búsì. 15  Áhì ọmọ Ábídíélì, ọmọ Gúnì ni olórí ẹbí wọn. 16  Wọ́n gbé ní Gílíádì,+ ní Báṣánì+ àti ní àwọn àrọko* rẹ̀ àti ní gbogbo àwọn ibi ìjẹko Ṣárónì títí dé ibi tí wọ́n fẹ̀ dé. 17  Gbogbo wọn ni orúkọ wọn wà nínú àkọsílẹ̀ ìdílé wọn nígbà ayé Jótámù+ ọba Júdà àti nígbà ayé Jèróbóámù*+ ọba Ísírẹ́lì. 18  Àwọn ọmọ Rúbẹ́nì àti àwọn ọmọ Gádì pẹ̀lú ààbọ̀ ẹ̀yà Mánásè ní ẹgbẹ̀rún mẹ́rìnlélógójì ó lé ọgọ́rùn-ún méje àti ọgọ́ta (44,760) jagunjagun tó lákíkanjú, wọ́n ń gbé apata, wọ́n ń lo idà, wọ́n mọ ọfà lò,* wọ́n sì ti kọ́ iṣẹ́ ogun. 19  Wọ́n bá àwọn ọmọ Hágárì,+ Jétúrì, Náfíṣì+ àti Nódábù jagun. 20  Ọlọ́run ràn wọ́n lọ́wọ́ láti bá wọn jà, tó fi jẹ́ pé a fi àwọn ọmọ Hágárì àti gbogbo àwọn tó wà pẹ̀lú wọn lé wọn lọ́wọ́, torí pé wọ́n ké pe Ọlọ́run fún ìrànlọ́wọ́ nínú ogun náà, ó sì gbọ́ ẹ̀bẹ̀ wọn torí pé wọ́n gbẹ́kẹ̀ lé e.+ 21  Wọ́n kó àwọn ẹran ọ̀sìn wọn, ọ̀kẹ́ méjì ààbọ̀ (50,000) ràkúnmí, ọ̀kẹ́ méjìlá ààbọ̀ (250,000) àgùntàn, ẹgbẹ̀rún méjì (2,000) kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ àti ọ̀kẹ́ márùn-ún (100,000) èèyàn.* 22  Ọ̀pọ̀ ló kú, nítorí Ọlọ́run tòótọ́ ló ja ìjà náà.+ Wọ́n gba àyè wọn, wọ́n sì ń gbé ibẹ̀ títí dìgbà tí wọ́n lọ sí ìgbèkùn.+ 23  Àtọmọdọ́mọ ààbọ̀ ẹ̀yà Mánásè+ gbé ilẹ̀ náà láti Báṣánì dé Baali-hámónì àti Sénírì àti Òkè Hámónì.+ Wọ́n pọ̀ gan-an. 24  Àwọn olórí agbo ilé bàbá wọn nìyí: Éférì, Íṣì, Élíélì, Ásíríẹ́lì, Jeremáyà, Hodafáyà àti Jádíẹ́lì; jagunjagun tó lákíkanjú ni wọ́n, wọ́n lókìkí, àwọn sì ni olórí agbo ilé bàbá wọn. 25  Àmọ́ wọ́n hùwà àìṣòótọ́ sí Ọlọ́run àwọn baba ńlá wọn, wọ́n sì ń bá àwọn ọlọ́run àwọn èèyàn ilẹ̀ náà+ ṣe àgbèrè, àwọn tí Ọlọ́run pa run kúrò níwájú wọn. 26  Nítorí náà, Ọlọ́run Ísírẹ́lì fi èrò kan sọ́kàn* Púlì ọba Ásíríà+ (ìyẹn, Tiliga-pílínésà+ ọba Ásíríà), tí ó fi kó àwọn ọmọ Rúbẹ́nì àti àwọn ọmọ Gádì pẹ̀lú ààbọ̀ ẹ̀yà Mánásè lọ sí ìgbèkùn, ó kó wọn wá sí Hálà, Hábórì, Hárà àti odò Gósánì,+ ibẹ̀ ni wọ́n sì ń gbé títí di òní yìí.

Àlàyé Ìsàlẹ̀ Ìwé

Tàbí “sọ ibùsùn bàbá rẹ̀ di ẹlẹ́gbin.”
Ọ̀rọ̀ yìí ní Hébérù lè túmọ̀ sí ọmọ, ọmọ ọmọ tàbí àtọmọdọ́mọ.
Tàbí “ìlú tó yí i ká.”
Ìyẹn, Jèróbóámù Kejì.
Ní Héb., “wọ́n mọ bí a ṣe ń fi okùn sí ọrun.”
Tàbí “ọkàn èèyàn.”
Ní Héb., “ru ẹ̀mí Púlì ọba Ásíríà sókè.”