Kíróníkà Kìíní 7:1-40

  • Àwọn àtọmọdọ́mọ Ísákà (1-5), ti Bẹ́ńjámínì (6-12), ti Náfútálì (13), ti Mánásè (14-19), ti Éfúrémù (20-29) àti ti Áṣérì (30-40)

7  Àwọn ọmọ Ísákà ni Tólà, Púà, Jáṣúbù àti Ṣímúrónì,+ wọ́n jẹ́ mẹ́rin.  Àwọn ọmọ Tólà ni Úsáì, Refáyà, Jéríélì, Jámáì, Íbísámù àti Ṣẹ́múẹ́lì, àwọn olórí agbo ilé bàbá wọn. Àwọn àtọmọdọ́mọ Tólà jẹ́ jagunjagun tó lákíkanjú, iye wọn ní ìgbà ayé Dáfídì jẹ́ ẹgbẹ̀rún méjìlélógún ó lé ọgọ́rùn-ún mẹ́fà (22,600).  Àwọn àtọmọdọ́mọ* Úsáì ni Isiráháyà, àwọn ọmọ Isiráháyà sì ni: Máíkẹ́lì, Ọbadáyà, Jóẹ́lì àti Isiṣáyà, àwọn márààrún jẹ́ ìjòyè.*  Àwọn àti àtọmọdọ́mọ wọn tó wà ní àwọn agbo ilé bàbá wọn, ẹgbẹ̀rún mẹ́rìndínlógójì (36,000) ọmọ ogun ni ó wà ní sẹpẹ́ fún ogun, nítorí wọ́n ní ìyàwó àti ọmọ púpọ̀.  Àwọn arákùnrin wọn tó wà ní gbogbo ìdílé Ísákà jẹ́ jagunjagun tó lákíkanjú. Gbogbo wọn jẹ́ ẹgbẹ̀rún mẹ́tàdínláàádọ́rùn-ún (87,000), bí orúkọ wọn ṣe wà nínú àkọsílẹ̀ ìdílé wọn.+  Àwọn ọmọ Bẹ́ńjámínì+ ni Bélà,+ Békérì+ àti Jédáélì,+ wọ́n jẹ́ mẹ́ta.  Àwọn ọmọ Bélà ni Ésíbónì, Úsáì, Úsíélì, Jérímótì àti Íráì, àwọn márùn-ún, àwọn olórí agbo ilé bàbá wọn, àwọn jagunjagun tó lákíkanjú, orúkọ àwọn ẹgbẹ̀rún méjìlélógún ó lé mẹ́rìnlélọ́gbọ̀n (22,034) ni ó sì wà nínú àkọsílẹ̀ ìdílé wọn.+  Àwọn ọmọ Békérì ni Sémírà, Jóáṣì, Élíésérì, Élíóénáì, Ómírì, Jérémótì, Ábíjà, Ánátótì àti Álémétì, gbogbo àwọn yìí ni ọmọ Békérì.  Àwọn àtọmọdọ́mọ wọn tó wà ní agbo ilé bàbá wọn jẹ́ ọ̀kẹ́ kan ó lé igba (20,200) jagunjagun tó lákíkanjú, orúkọ wọn sì wà nínú àkọsílẹ̀ ìdílé wọn. 10  Àwọn ọmọ Jédáélì+ ni Bílíhánì, àwọn ọmọ Bílíhánì sì ni: Jéúṣì, Bẹ́ńjámínì, Éhúdù, Kénáánà, Sẹ́tánì, Táṣíṣì àti Áhíṣáhárì. 11  Gbogbo wọn ni ọmọ Jédáélì, wọ́n jẹ́ olórí agbo ilé àwọn baba ńlá wọn, àwọn ẹgbẹ̀rún mẹ́tàdínlógún ó lé igba (17,200) jagunjagun tó lákíkanjú tí wọ́n ti gbára dì láti jáde ogun. 12  Àwọn Ṣúpímù àti àwọn Húpímù ni àwọn ọmọ Írì;+ àwọn Húṣímù ni àwọn ọmọ Áhérì. 13  Àwọn ọmọ Náfútálì+ ni Jásíélì, Gúnì, Jésérì àti Ṣálúmù, àwọn àtọmọdọ́mọ* Bílíhà.+ 14  Àwọn ọmọ Mánásè+ ni: Ásíríélì, tí wáhàrì* rẹ̀ ará Síríà bí. (Ó bí Mákírù+ bàbá Gílíádì. 15  Mákírù fẹ́ ìyàwó fún Húpímù àti fún Ṣúpímù, orúkọ arábìnrin rẹ̀ sì ni Máákà.) Orúkọ ìkejì ni Sélóféhádì,+ àmọ́ àwọn ọmọbìnrin ni Sélóféhádì bí.+ 16  Máákà, ìyàwó Mákírù bí ọmọ kan, ó sì pe orúkọ rẹ̀ ní Péréṣì; orúkọ arákùnrin rẹ̀ ni Ṣéréṣì; àwọn ọmọ rẹ̀ sì ni Úlámù àti Rékémù. 17  Ọmọ* Úlámù ni Bédánì. Àwọn ni ọmọ Gílíádì ọmọ Mákírù ọmọ Mánásè. 18  Arábìnrin rẹ̀ ni Hámólékétì. Ó bí Íṣíhódù, Abi-ésérì àti Málà. 19  Àwọn ọmọ Ṣẹ́mídà ni Áhíánì, Ṣékémù, Líkíhì àti Áníámù. 20  Àwọn ọmọ Éfúrémù+ ni Ṣútélà,+ ọmọ* rẹ̀ ni Bérédì, ọmọ rẹ̀ ni Táhátì, ọmọ rẹ̀ ni Éléádà, ọmọ rẹ̀ ni Táhátì, 21  ọmọ rẹ̀ ni Sábádì, ọmọ rẹ̀ ni Ṣútélà àti Ésérì pẹ̀lú Éléádì. Àwọn ọkùnrin Gátì+ tí wọ́n bí ní ilẹ̀ náà pa wọ́n torí pé wọ́n lọ kó ẹran ọ̀sìn wọn. 22  Ọ̀pọ̀ ọjọ́ ni Éfúrémù bàbá wọn fi ṣọ̀fọ̀, àwọn arákùnrin rẹ̀ sì ń wá sọ́dọ̀ rẹ̀ láti tù ú nínú. 23  Lẹ́yìn náà, ó ní àṣepọ̀ pẹ̀lú ìyàwó rẹ̀, ó lóyún, ó sì bímọ. Àmọ́ ó pe orúkọ rẹ̀ ní Bẹráyà,* torí pé inú àjálù ni agbo ilé rẹ̀ wà nígbà tí ìyàwó rẹ̀ bímọ. 24  Ọmọbìnrin rẹ̀ ni Ṣéérà, òun ló tẹ ìlú Bẹti-hórónì Ìsàlẹ̀+ àti ti Òkè+ dó àti Useni-ṣéérà. 25  Ọmọ rẹ̀ ni Réfà àti Réṣéfù, ọmọ rẹ̀ ni Télà ọmọ rẹ̀ sì ni Táhánì, 26  ọmọ rẹ̀ ni Ládánì, ọmọ rẹ̀ ni Ámíhúdù, ọmọ rẹ̀ ni Élíṣámà, 27  ọmọ rẹ̀ ni Núnì, ọmọ rẹ̀ sì ni Jóṣúà.*+ 28  Àwọn ibi tí wọ́n ń gbé àti ohun ìní wọn ni Bẹ́tẹ́lì+ àti àwọn àrọko* rẹ̀, Nááránì ní apá ìlà oòrùn, Gésérì ní apá ìwọ̀ oòrùn àti àwọn àrọko rẹ̀ pẹ̀lú Ṣékémù àti àwọn àrọko rẹ̀ títí dé Ááyà* àti àwọn àrọko rẹ̀; 29  àwọn ilẹ̀ tó wà lẹ́gbẹ̀ẹ́ ti àwọn àtọmọdọ́mọ Mánásè ni, Bẹti-ṣéánì+ àti àwọn àrọko rẹ̀, Táánákì+ àti àwọn àrọko rẹ̀, Mẹ́gídò+ àti àwọn àrọko rẹ̀, Dórì+ àti àwọn àrọko rẹ̀. Orí àwọn ilẹ̀ yìí ni àwọn àtọmọdọ́mọ Jósẹ́fù ọmọ Ísírẹ́lì gbé. 30  Àwọn ọmọkùnrin Áṣérì ni Ímúnà, Íṣífà, Íṣífì àti Bẹráyà,+ pẹ̀lú Sírà+ arábìnrin wọn. 31  Àwọn ọmọ Bẹráyà ni Hébà àti Málíkíélì, òun ni bàbá Bísáítì. 32  Hébà bí Jáfílétì, Ṣómà, Hótámù àti Ṣúà arábìnrin wọn. 33  Àwọn ọmọ Jáfílétì ni Pásákì, Bímíhálì àti Áṣífátì. Àwọn ni ọmọ Jáfílétì. 34  Àwọn ọmọ Ṣémérì* ni Áhì, Rógà, Jéhúbà àti Árámù. 35  Àwọn ọmọ Hélémù* arákùnrin rẹ̀ ni Sófà, Ímínà, Ṣéléṣì àti Ámálì. 36  Àwọn ọmọ Sófà ni Súà, Hánéfà, Ṣúálì, Bérì, Ímúrà, 37  Bésérì, Hódì, Ṣáámà, Ṣílíṣà, Ítíránì àti Béérà. 38  Àwọn ọmọ Jétà ni Jéfúnè, Písípà àti Árà. 39  Àwọn ọmọ Úlà ni Áráhì, Háníélì àti Rísíà. 40  Gbogbo wọn ni ọmọ Áṣérì, àwọn olórí agbo ilé bàbá wọn, àwọn tí a yàn, àwọn jagunjagun tó lákíkanjú, àwọn olórí ìjòyè; iye wọn bí ó ṣe wà nínú àkọsílẹ̀ ìdílé+ wọn sì jẹ́ ẹgbẹ̀rún mẹ́rìndínlọ́gbọ̀n (26,000) ọkùnrin+ ogun tí wọ́n ti gbára dì fún ogun.

Àlàyé Ìsàlẹ̀ Ìwé

Ní Héb., “Àwọn ọmọ.”
Ní Héb., “olórí.”
Ní Héb., “àwọn ọmọ.”
Tàbí “ìyàwó onípò kejì.” Wo Àlàyé Ọ̀rọ̀, “Wáhàrì.”
Ní Héb., “Àwọn ọmọ.”
Ọ̀rọ̀ yìí ní Hébérù lè túmọ̀ sí ọmọ, ọmọ ọmọ tàbí àtọmọdọ́mọ.
Ó túmọ̀ sí “Pẹ̀lú Àjálù.”
Tàbí “Jèhóṣúà,” ó túmọ̀ sí “Jèhófà Ni Ìgbàlà.”
Tàbí “ìlú tó yí i ká.”
Tàbí kó jẹ́, “Gásà,” síbẹ̀ kì í ṣe Gásà tó wà ní Filísíà.
Wọ́n tún pè é ní Ṣómérì ní ẹsẹ 32.
Ó lè jẹ́ ìkan náà pẹ̀lú “Hótámù” ní ẹsẹ 32.