Ìwé Kìíní sí Àwọn Ará Kọ́ríńtì 1:1-31

  • Ìkíni (1-3)

  • Pọ́ọ̀lù dúpẹ́ lọ́wọ́ Ọlọ́run nítorí àwọn ará Kọ́ríńtì (4-9)

  • Ó gbà wọ́n níyànjú pé kí wọ́n wà níṣọ̀kan (10-17)

  • Kristi, agbára àti ọgbọ́n Ọlọ́run (18-25)

  • Ẹ máa yangàn nínú Jèhófà nìkan (26-31)

1  Pọ́ọ̀lù, tí a pè láti jẹ́ àpọ́sítélì+ Kristi Jésù nípa ìfẹ́ Ọlọ́run pẹ̀lú Sótínésì arákùnrin wa,  sí ìjọ Ọlọ́run tó wà ní Kọ́ríńtì,+ sí ẹ̀yin tí a ti sọ di mímọ́ nínú Kristi Jésù,+ tí a pè láti jẹ́ ẹni mímọ́, ẹ̀yin àti gbogbo àwọn tó ń ké pe orúkọ Olúwa wa, Jésù Kristi+ níbi gbogbo, ẹni tó jẹ́ Olúwa wa àti tiwọn:  Kí inú rere àìlẹ́tọ̀ọ́sí àti àlàáfíà láti ọ̀dọ̀ Baba wa Ọlọ́run àti Jésù Kristi Olúwa wa, wà pẹ̀lú yín.  Ìgbà gbogbo ni mò ń dúpẹ́ lọ́wọ́ Ọlọ́run mi nítorí yín lórí inú rere àìlẹ́tọ̀ọ́sí Ọlọ́run tí a fún yín nípasẹ̀ Kristi Jésù;  torí Ọlọ́run ti sọ yín di ọlọ́rọ̀ nínú ohun gbogbo nítorí rẹ̀, ẹ ti lè sọ̀rọ̀ dáadáa, ẹ sì ti ní ìmọ̀ tó kún rẹ́rẹ́,+  gẹ́gẹ́ bí a ṣe fìdí ẹ̀rí nípa Kristi+ múlẹ̀ láàárín yín,  kí ẹ má bàa ṣaláìní ẹ̀bùn èyíkéyìí, bí ẹ ṣe ń dúró de ìfihàn Olúwa wa Jésù Kristi+ lójú méjèèjì.  Bákan náà, á mú kí ẹ dúró gbọn-in títí dé òpin, kí ẹ̀sùn kankan má bàa wà lọ́rùn yín ní ọjọ́ Olúwa wa Jésù Kristi.+  Ọlọ́run jẹ́ olóòótọ́,+ ẹni tó pè yín sínú àjọṣe* pẹ̀lú Ọmọ rẹ̀, Jésù Kristi Olúwa wa. 10  Ní báyìí, mo fi orúkọ Olúwa wa Jésù Kristi rọ̀ yín, ẹ̀yin ará, pé kí gbogbo yín máa fohùn ṣọ̀kan àti pé kí ìyapa má ṣe sí láàárín yín,+ àmọ́ kí ẹ ní inú kan náà àti èrò kan náà.+ 11  Nítorí àwọn kan láti ilé Kílóè ti sọ fún mi nípa yín, ẹ̀yin ará mi, pé ìyapa wà láàárín yín. 12  Ohun tí mo ní lọ́kàn ni pé, kálukú yín ń sọ pé: “Èmi jẹ́ ti Pọ́ọ̀lù,” “Èmi jẹ́ ti Àpólò,”+ “Èmi jẹ́ ti Kéfà,”* “Èmi jẹ́ ti Kristi.” 13  Ṣé Kristi pín yẹ́lẹyẹ̀lẹ ni? Wọn ò kan Pọ́ọ̀lù mọ́gi* fún yín, àbí òun ni wọ́n kàn? Àbí ṣé a batisí yín ní orúkọ Pọ́ọ̀lù ni? 14  Mo dúpẹ́ lọ́wọ́ Ọlọ́run pé mi ò batisí ìkankan lára yín àfi Kírípọ́sì+ àti Gáyọ́sì,+ 15  kí ẹnì kankan má bàa sọ pé a batisí yín ní orúkọ mi. 16  Bẹ́ẹ̀ ni, mo tún batisí agbo ilé Sítéfánásì.+ Àmọ́ ní ti àwọn tó kù, mi ò mọ̀ bóyá mo batisí ẹnì kankan nínú wọn. 17  Nítorí Kristi ò rán mi pé kí n lọ máa batisí, iṣẹ́ kíkéde ìhìn rere ló rán mi;+ kì í sì í ṣe pẹ̀lú ọgbọ́n ọ̀rọ̀ sísọ,* kí a má bàa sọ igi oró* Kristi di ohun tí kò wúlò. 18  Torí ọ̀rọ̀ nípa igi oró* jẹ́ ọ̀rọ̀ òmùgọ̀ lójú àwọn tó ń ṣègbé,+ àmọ́ lójú àwa tí à ń gbà là, ó jẹ́ agbára Ọlọ́run.+ 19  Nítorí ó wà lákọsílẹ̀ pé: “Màá mú kí ọgbọ́n àwọn ọlọ́gbọ́n ṣègbé, làákàyè àwọn amòye ni màá sì kọ̀ sílẹ̀.”*+ 20  Ibo ni ọlọ́gbọ́n wà? Ibo ni akọ̀wé òfin* wà? Ibo ni òjiyàn ọ̀rọ̀ ètò àwọn nǹkan yìí* wà? Ṣé Ọlọ́run kò ti sọ ọgbọ́n ayé di òmùgọ̀ ni? 21  Torí nígbà tó ti jẹ́ pé, nínú ọgbọ́n Ọlọ́run, ayé kò fi ọgbọ́n tirẹ̀+ mọ Ọlọ́run,+ inú Ọlọ́run dùn sí ọ̀rọ̀ òmùgọ̀+ tí à ń wàásù láti gba àwọn tó nígbàgbọ́ là. 22  Nítorí àwọn Júù ń béèrè àmì,+ àwọn Gíríìkì sì ń wá ọgbọ́n; 23  àmọ́ àwa ń wàásù Kristi tí wọ́n kàn mọ́gi,* lójú àwọn Júù, ó jẹ́ ohun tó ń fa ìkọ̀sẹ̀ àmọ́ lójú àwọn orílẹ̀-èdè, ó jẹ́ ọ̀rọ̀ òmùgọ̀.+ 24  Ṣùgbọ́n lójú àwọn tí a pè, ì báà jẹ́ Júù tàbí Gíríìkì, Kristi ni agbára Ọlọ́run àti ọgbọ́n Ọlọ́run.+ 25  Nítorí ohun òmùgọ̀ ti Ọlọ́run gbọ́n ju èèyàn lọ, ohun aláìlera ti Ọlọ́run sì lágbára ju èèyàn lọ.+ 26  Nítorí ẹ rí bó ṣe pè yín, ẹ̀yin ará, pé kì í ṣe ọ̀pọ̀ ọlọ́gbọ́n nípa ti ara* ni a pè,+ kì í ṣe ọ̀pọ̀ alágbára, kì í ṣe ọ̀pọ̀ àwọn tí a bí ní ilé ọlá,*+ 27  àmọ́, Ọlọ́run yan àwọn ohun òmùgọ̀ ayé, kí ó lè dójú ti àwọn ọlọ́gbọ́n; Ọlọ́run sì yan àwọn ohun aláìlera ayé, kí ó lè dójú ti àwọn ohun tó lágbára;+ 28  Ọlọ́run yan àwọn ohun tí kò já mọ́ nǹkan kan nínú ayé àti àwọn ohun tí wọ́n ń fojú àbùkù wò, àwọn ohun tí kò sí, kí ó lè sọ àwọn ohun tó wà di asán,+ 29  kí ẹnì* kankan má bàa yangàn níwájú Ọlọ́run. 30  Ṣùgbọ́n òun ló mú kí ẹ wà ní ìṣọ̀kan pẹ̀lú Kristi Jésù, ẹni tó fi ọgbọ́n Ọlọ́run àti òdodo rẹ̀+ hàn wá, ó sọ wá di mímọ́,+ ó sì tú wa sílẹ̀ nípasẹ̀ ìràpadà,+ 31  kí ó lè rí bó ṣe wà lákọsílẹ̀ pé: “Ẹni tó bá ń yangàn, kó máa yangàn nínú Jèhófà.”*+

Àlàyé Ìsàlẹ̀ Ìwé

Tàbí “àjọpín.”
Wọ́n tún ń pè é ní Pétérù.
Tàbí “mọ́ òpó igi.” Wo Àlàyé Ọ̀rọ̀.
Tàbí “ọ̀rọ̀ ọgbọ́n àlùmọ̀kọ́rọ́yí.”
Tàbí “tì sí ẹ̀gbẹ́ kan.”
Ìyẹn, ọ̀jáfáfá nínú Òfin.
Tàbí “àsìkò yìí.” Wo Àlàyé Ọ̀rọ̀.
Tàbí “mọ́ òpó igi.” Wo Àlàyé Ọ̀rọ̀.
Tàbí “lójú èèyàn.”
Tàbí “nínú ìdílé tó lórúkọ.”
Ní Grk., “ẹlẹ́ran ara.”