Ìwé Kìíní sí Àwọn Ará Kọ́ríńtì 4:1-21
4 Ó yẹ kí àwọn èèyàn kà wá sí ìránṣẹ́* Kristi àti ìríjú àwọn àṣírí mímọ́ Ọlọ́run.+
2 Nínú ọ̀rọ̀ yìí, ohun tí à ń retí lọ́dọ̀ àwọn ìríjú ni pé kí wọ́n jẹ́ olóòótọ́.
3 Lójú tèmi, kò jẹ́ nǹkan kan pé kí ẹ̀yin tàbí àwùjọ ìgbẹ́jọ́* téèyàn gbé kalẹ̀ wádìí mi wò. Kódà, èmi gan-an kò wádìí ara mi wò.
4 Nítorí mi ò rí nǹkan tó burú nínú ohun tí mo ṣe. Àmọ́, èyí kò túmọ̀ sí pé mo jẹ́ olódodo; ẹni tó ń wádìí mi wò ni Jèhófà.*+
5 Nítorí náà, ẹ má ṣèdájọ́+ ohunkóhun ṣáájú àkókò tó yẹ, títí Olúwa yóò fi dé. Yóò mú àwọn ohun ìkọ̀kọ̀ inú òkùnkùn wá sínú ìmọ́lẹ̀, á sì jẹ́ kí a mọ èrò ọkàn àwọn èèyàn, lẹ́yìn náà, kálukú á gba ìyìn rẹ̀ látọ̀dọ̀ Ọlọ́run.+
6 Ní báyìí, ẹ̀yin ará, mo ti fi èmi àti Àpólò+ ṣàpẹẹrẹ* àwọn nǹkan yìí fún ire yín, kó lè jẹ́ pé nípasẹ̀ wa, ẹ máa kọ́ ìlànà tó sọ pé: “Má ṣe kọjá àwọn ohun tó wà lákọsílẹ̀,” kí ẹ má bàa gbéra ga,+ tí ẹ ó sì máa sọ pé ẹnì kan dára ju èkejì lọ.
7 Nítorí ta ló mú ọ yàtọ̀ sí ẹlòmíràn? Ní tòótọ́, kí lo ní tí kì í ṣe pé o gbà á?+ Tó bá jẹ́ pé ńṣe lo gbà á lóòótọ́, kí ló dé tí ò ń fọ́nnu bíi pé kì í ṣe pé o gbà á?
8 Ṣé ó ti tẹ́ yín lọ́rùn báyìí? Ṣé ẹ ti lọ́rọ̀ báyìí? Ṣé ẹ ti ń ṣàkóso bí ọba+ láìsí àwa? Ì bá wù mí kí ẹ ti máa ṣàkóso bí ọba, kí àwa náà lè ṣàkóso pẹ̀lú yín bí ọba.+
9 Nítorí lójú tèmi, ó dà bíi pé Ọlọ́run ti fi àwa àpọ́sítélì sí ìgbẹ̀yìn láti fi wá hàn bí àwọn tí a ti dájọ́ ikú fún,+ nítorí a ti di ìran àpéwò fún ayé+ àti fún àwọn áńgẹ́lì àti fún àwọn èèyàn.
10 Àwa jẹ́ òmùgọ̀+ nítorí Kristi, àmọ́ ẹ̀yin jẹ́ olóye nínú Kristi; àwa jẹ́ aláìlera, àmọ́ ẹ̀yin jẹ́ alágbára; ẹ̀yin ní iyì, àmọ́ àwa kò ní iyì.
11 Títí di wákàtí yìí, ebi ń pa wá,+ òùngbẹ ń gbẹ wá,+ a ò rí aṣọ tó dáa wọ̀,* wọ́n ń nà wá,*+ a ò sì rí ilé gbé,
12 à ń ṣe làálàá, a sì ń fi ọwọ́ ara wa ṣiṣẹ́.+ Nígbà tí wọ́n ń bú wa, à ń súre;+ nígbà tí wọ́n ń ṣe inúnibíni sí wa, à ń fara dà á pẹ̀lú sùúrù;+
13 nígbà tí wọ́n bà wá lórúkọ jẹ́, a fi ohùn pẹ̀lẹ́ dáhùn;*+ a ti dà bíi pàǹtírí* ayé, èérí ohun gbogbo, títí di báyìí.
14 Kì í ṣe kí n lè dójú tì yín ni mo ṣe ń kọ àwọn nǹkan yìí sí yín, àmọ́ kí n lè gbà yín níyànjú bí àwọn ọmọ mi tó jẹ́ àyànfẹ́.
15 Nítorí bí ẹ bá tiẹ̀ ní ẹgbẹ̀rún mẹ́wàá (10,000) atọ́nisọ́nà* nínú Kristi, ẹ kò ní baba púpọ̀; torí nínú Kristi Jésù, mo di baba yín nípasẹ̀ ìhìn rere.+
16 Nítorí náà, mo rọ̀ yín, ẹ máa fara wé mi.+
17 Ìdí nìyẹn tí mo fi rán Tímótì sí yín, torí ó jẹ́ ọmọ mi ọ̀wọ́n àti olóòótọ́ nínú Olúwa. Á rán yín létí àwọn ọ̀nà tí mò ń gbà ṣe nǹkan* ní ìṣọ̀kan pẹ̀lú Kristi Jésù,+ bí mo ṣe ń kọ́ni níbi gbogbo nínú gbogbo ìjọ.
18 Àwọn kan ń gbéra ga, bíi pé mi ò ní wá sọ́dọ̀ yín.
19 Àmọ́ màá wá sọ́dọ̀ yín láìpẹ́, tí Jèhófà* bá fẹ́, kí n lè mọ agbára tí àwọn tó ń gbéra ga ní, kì í ṣe ọ̀rọ̀ ẹnu wọn.
20 Nítorí Ìjọba Ọlọ́run kì í ṣe ti ọ̀rọ̀ ẹnu, ti agbára ni.
21 Èwo lẹ fẹ́? Ṣé kí n wá sọ́dọ̀ yín pẹ̀lú ọ̀pá+ àbí kí n wá pẹ̀lú ìfẹ́ àti ẹ̀mí ìwà tútù?
Àlàyé Ìsàlẹ̀ Ìwé
^ Tàbí “ọmọ abẹ́.”
^ Tàbí “kóòtù.”
^ Tàbí “ṣàpèjúwe.”
^ Tàbí “gbá wa káàkiri.”
^ Ní Grk.,“a wà ní ìhòòhò.”
^ Ní Grk., “a wá ojú rere.”
^ Tàbí “ìdọ̀tí.”
^ Tàbí “olùkọ́.”
^ Ní Grk., “àwọn ọ̀nà mi.”