Ìwé Kìíní sí Àwọn Ará Kọ́ríńtì 7:1-40

  • Ìmọ̀ràn fún àwọn tí kò gbéyàwó àti àwọn tó ti gbéyàwó (1-16)

  • Ẹ wà ní ipò tí ẹ wà nígbà tí a pè yín (17-24)

  • Àwọn tí kò gbéyàwó àti àwọn opó (25-40)

    • Àǹfààní tó wà nínú kéèyàn wà láìgbéyàwó (32-35)

    • Gbéyàwó “kìkì nínú Olúwa” (39)

7  Ní báyìí, ní ti àwọn ohun tí ẹ kọ̀wé nípa rẹ̀, ó sàn kí ọkùnrin má fọwọ́ kan* obìnrin;  àmọ́ nítorí ìṣekúṣe* tó gbòde kan, kí ọkùnrin kọ̀ọ̀kan ní aya tirẹ̀,+ kí obìnrin kọ̀ọ̀kan sì ní ọkọ tirẹ̀.+  Kí ọkọ máa fún aya rẹ̀ ní ẹ̀tọ́ rẹ̀, kí aya sì máa ṣe bẹ́ẹ̀ fún ọkọ rẹ̀.+  Aya kò láṣẹ lórí ara rẹ̀, ọkọ rẹ̀ ló láṣẹ; bákan náà, ọkọ kò láṣẹ lórí ara rẹ̀, aya rẹ̀ ló láṣẹ.  Ẹ má ṣe máa fi du ara yín àfi tó bá jẹ́ àjọgbà fún àkókò kan, kí ẹ lè ya àkókò sọ́tọ̀ fún àdúrà, kí ẹ sì pa dà wà pa pọ̀, kí Sátánì má bàa máa dẹ yín wò torí pé ẹ ò lè mára dúró.  Àmọ́, mi ò pa á láṣẹ o, mo kàn ń sọ ohun tí ẹ lè ṣe ni.  Ì bá wù mí kí gbogbo èèyàn dà bíi tèmi. Síbẹ̀, kálukú ló ní ẹ̀bùn tirẹ̀+ látọ̀dọ̀ Ọlọ́run, ọ̀kan lọ́nà yìí, òmíràn lọ́nà yẹn.  Tóò, mo sọ fún àwọn tí kò gbéyàwó àti àwọn opó pé ó sàn kí wọ́n wà bí mo ṣe wà.+  Àmọ́ tí wọn ò bá lè mára dúró, kí wọ́n gbéyàwó, torí ó sàn láti gbéyàwó ju kí ara ẹni máa gbóná nítorí ìfẹ́ ìbálòpọ̀.+ 10  Mo fún àwọn tó ti ṣègbéyàwó ní ìtọ́sọ́nà, àmọ́ kì í ṣe èmi, Olúwa ni, pé kí aya má ṣe kúrò lọ́dọ̀ ọkọ rẹ̀.+ 11  Àmọ́ tó bá kúrò lọ́dọ̀ rẹ̀, kí ó wà láìlọ́kọ, àìjẹ́ bẹ́ẹ̀ kó pa dà sọ́dọ̀ ọkọ rẹ̀; kí ọkọ má sì fi aya rẹ̀ sílẹ̀.+ 12  Àmọ́ mo sọ fún àwọn yòókù, bẹ́ẹ̀ ni, èmi ni, kì í ṣe Olúwa+ pé: Tí arákùnrin èyíkéyìí bá ní aya tó jẹ́ aláìgbàgbọ́, tí obìnrin náà sì gbà láti máa bá a gbé, kí ó má fi obìnrin náà sílẹ̀; 13  tí obìnrin kan bá sì ní ọkọ tó jẹ́ aláìgbàgbọ́, tí ọkùnrin náà gbà láti máa bá a gbé, kí ó má fi ọkọ rẹ̀ sílẹ̀. 14  Nítorí ọkọ tó jẹ́ aláìgbàgbọ́ ni a sọ di mímọ́ nítorí aya rẹ̀, aya tó sì jẹ́ aláìgbàgbọ́ ni a sọ di mímọ́ nítorí arákùnrin náà; àìjẹ́ bẹ́ẹ̀, àwọn ọmọ yín á jẹ́ aláìmọ́, àmọ́ ní báyìí wọ́n jẹ́ mímọ́. 15  Ṣùgbọ́n tí aláìgbàgbọ́ náà bá pinnu láti lọ,* jẹ́ kó máa lọ; irú ipò bẹ́ẹ̀ kò de arákùnrin kan tàbí arábìnrin kan, àmọ́ Ọlọ́run ti pè yín sí àlàáfíà.+ 16  Ìwọ aya, ṣé o mọ̀ bóyá wàá gba ọkọ rẹ là?+ Ìwọ ọkọ, ṣé o mọ̀ bóyá wàá gba aya rẹ là? 17  Síbẹ̀, gẹ́gẹ́ bí Jèhófà* ṣe fún kálukú ní ìpín tirẹ̀, kí kálukú máa rìn bí Ọlọ́run ṣe pè é.+ Torí náà, mo fi àṣẹ yìí lélẹ̀ nínú gbogbo ìjọ. 18  Ǹjẹ́ ọkùnrin kan wà tó ti dádọ̀dọ́* nígbà tí a pè é?+ Kí ó má pa dà di aláìdádọ̀dọ́.* Ǹjẹ́ ọkùnrin kan wà tó jẹ́ aláìdádọ̀dọ́ nígbà tí a pè é? Kí ó má ṣe dádọ̀dọ́.+ 19  Ìdádọ̀dọ́* kò túmọ̀ sí nǹkan kan, àìdádọ̀dọ́* kò sì túmọ̀ sí nǹkan kan;+ pípa àwọn àṣẹ Ọlọ́run mọ́ ni ohun tó ṣe pàtàkì.+ 20  Ipòkípò tí kálukú wà nígbà tí a pè é, kí ó wà bẹ́ẹ̀.+ 21  Ṣé ẹrú ni ọ́ nígbà tí a pè ọ́? Má ṣe jẹ́ kí ìyẹn dà ọ́ láàmú;+ àmọ́ tí o bá lè di òmìnira, tètè gbá àǹfààní náà mú. 22  Nítorí ẹnikẹ́ni tí a pè nínú Olúwa nígbà tó jẹ́ ẹrú ti di òmìnira nínú Olúwa; + bákan náà, ẹnikẹ́ni tí a pè nígbà tó wà ní òmìnira jẹ́ ẹrú Kristi. 23  A ti rà yín ní iye kan;+ ẹ má ṣe ẹrú èèyàn mọ́. 24  Ipòkípò tí kálukú wà nígbà tí a pè é, ẹ̀yin ará, kí ó wà bẹ́ẹ̀ níwájú Ọlọ́run. 25  Ní ti àwọn wúńdíá,* mi ò ní àṣẹ kankan látọ̀dọ̀ Olúwa, àmọ́ mo sọ èrò mi+ gẹ́gẹ́ bí ẹni tí Olúwa fi àánú hàn sí láti jẹ́ olóòótọ́. 26  Nítorí náà, mo rò pé ohun tó dáa jù lọ ni pé kí ọkùnrin kan wà bó ṣe wà nítorí ìṣòro ìsinsìnyí. 27  Ṣé o ti gbéyàwó? Má ṣe wá ọ̀nà láti fi í sílẹ̀.+ Ṣé o ò níyàwó mọ́? Má ṣe máa wá ìyàwó. 28  Àmọ́ tí o bá tiẹ̀ gbéyàwó, o ò dẹ́ṣẹ̀ kankan. Tí wúńdíá kan bá sì ṣègbéyàwó, irú ẹni bẹ́ẹ̀ kò dẹ́ṣẹ̀ kankan. Síbẹ̀, àwọn tó ṣe bẹ́ẹ̀ máa ní ìpọ́njú nínú ara wọn. Àmọ́ mi ò fẹ́ kí ẹ kó sínú ìṣòro. 29  Yàtọ̀ síyẹn, mo sọ èyí, ẹ̀yin ará, pé àkókò tó ṣẹ́ kù ti dín kù.+ Láti ìsinsìnyí lọ, kí àwọn tó níyàwó dà bíi pé wọn kò ní, 30  kí àwọn tó ń sunkún dà bí àwọn tí kò sunkún, kí àwọn tó ń yọ̀ dà bí àwọn tí kò yọ̀, kí àwọn tó ń rà dà bí àwọn tí kò ní, 31  kí àwọn tó ń lo ayé dà bí àwọn tí kò lò ó dé ẹ̀kúnrẹ́rẹ́; nítorí ìrísí* ayé yìí ń yí pa dà. 32  Ní tòótọ́, mi ò fẹ́ kí ẹ máa ṣàníyàn. Ọkùnrin tí kò gbéyàwó máa ń ṣàníyàn nípa àwọn ohun ti Olúwa, bó ṣe máa rí ìtẹ́wọ́gbà Olúwa. 33  Àmọ́ ọkùnrin tó gbéyàwó máa ń ṣàníyàn nípa àwọn ohun ti ayé,+ bó ṣe máa rí ìtẹ́wọ́gbà aya rẹ̀, 34  ó sì ní ìpínyà ọkàn. Yàtọ̀ síyẹn, obìnrin tí kò lọ́kọ àti wúńdíá, máa ń ṣàníyàn nípa àwọn ohun ti Olúwa,+ kí ó lè jẹ́ mímọ́ nínú ara àti nínú ẹ̀mí. Àmọ́, obìnrin tó ti lọ́kọ máa ń ṣàníyàn nípa àwọn ohun ti ayé, bó ṣe máa rí ìtẹ́wọ́gbà ọkọ rẹ̀. 35  mò ń sọ èyí nítorí àǹfààní ara yín, kì í ṣe kí n lè dín òmìnira yín kù,* àmọ́ kí n lè mú kí ẹ ṣe ohun tí ó tọ́, kí ẹ sì lè gbájú mọ́ iṣẹ́ Olúwa láìsí ìpínyà ọkàn. 36  Àmọ́ tí ẹnì kan bá rí i pé òun ti ń hùwà tí kò yẹ torí pé òun kò gbéyàwó,* tí onítọ̀hún sì ti kọjá ìgbà ìtànná èwe,* ohun tó yẹ kó ṣe nìyí: Kí ó ṣe ohun tí ó fẹ́; kò dẹ́ṣẹ̀. Kí wọ́n gbéyàwó.+ 37  Àmọ́ tí ẹnikẹ́ni bá ti pinnu nínú ọkàn rẹ̀, tí kò sì sídìí tó fi gbọ́dọ̀ yí i pa dà, ṣùgbọ́n tó ní àṣẹ lórí ohun tó fẹ́, tó sì ti pinnu nínú ọkàn rẹ̀ láti wà láìgbéyàwó,* yóò ṣe dáadáa.+ 38  Bákan náà, ẹni tó bá gbéyàwó* ṣe dáadáa, àmọ́ ẹni tí kò bá gbéyàwó ṣe dáadáa jù.+ 39  Òfin de aya ní gbogbo ìgbà tí ọkọ rẹ̀ bá wà láàyè.+ Àmọ́ tí ọkọ rẹ̀ bá sùn nínú ikú, ó ní òmìnira láti ṣe ìgbéyàwó pẹ̀lú ẹni tó bá wù ú, kìkì nínú Olúwa.+ 40  Àmọ́ lérò tèmi, ó máa láyọ̀ jù tó bá wà bó ṣe wà; ó sì dá mi lójú pé èmi náà ní ẹ̀mí Ọlọ́run.

Àlàyé Ìsàlẹ̀ Ìwé

Ìyẹn, ní ìbálòpọ̀ pẹ̀lú.
Ó ń tọ́ka sí ọ̀rọ̀ Gíríìkì náà, por·neiʹa tí wọ́n bá lò ó fún ohun tó ju ẹyọ kan lọ. Wo Àlàyé Ọ̀rọ̀.
Tàbí “pínyà.”
Tàbí “kọlà.”
Tàbí “aláìkọlà.”
Tàbí “àìkọlà.”
Tàbí “Ìkọlà.”
Tàbí “àwọn tí kò tíì lọ́kọ tàbí láya.”
Ní Grk., “ìran.”
Ní Grk., “dẹ okùn mú yín.”
Tàbí “hùwà tí kò yẹ sí ipò wúńdíá òun.”
Ó ń tọ́ka sí ìgbà tí ìfẹ́ ìbálòpọ̀ máa ń lágbára lára ọ̀dọ́.
Tàbí “láti pa ipò wúńdíá rẹ̀ mọ́.”
Tàbí “tó bá fi ipò wúńdíá rẹ̀ fúnni nínú ìgbéyàwó.”