Ìwé Kìíní Pétérù 1:1-25
1 Pétérù, àpọ́sítélì+ Jésù Kristi, sí ẹ̀yin olùgbé fún ìgbà díẹ̀* tí ẹ wà káàkiri Pọ́ńtù, Gálátíà, Kapadókíà,+ Éṣíà àti Bítíníà, sí ẹ̀yin àyànfẹ́
2 gẹ́gẹ́ bí ohun tí Ọlọ́run tó jẹ́ Baba ti mọ̀ tẹ́lẹ̀,+ tí ẹ̀mí sọ di mímọ́,+ kí ẹ lè ṣègbọràn, kí a sì wọ́n ẹ̀jẹ̀ Jésù Kristi sí yín lára:+
Kí inú rere àìlẹ́tọ̀ọ́sí àti àlàáfíà yín máa pọ̀ sí i.
3 Ẹ yin Ọlọ́run àti Baba Olúwa wa Jésù Kristi, torí nínú àánú rẹ̀ tó pọ̀, ó fún wa ní ìbí tuntun+ ká lè ní ìrètí tó wà láàyè+ nípasẹ̀ àjíǹde Jésù Kristi kúrò nínú ikú,+
4 ká lè ní ogún tí kì í bà jẹ́, tí kò lábààwọ́n, tí kò sì lè ṣá.+ A tọ́jú rẹ̀ sí ọ̀run de ẹ̀yin+
5 tí agbára Ọlọ́run dáàbò bò nípasẹ̀ ìgbàgbọ́ fún ìgbàlà kan tí a ṣe tán láti ṣí payá ní àkókò ìkẹyìn.
6 Ẹ̀ ń yọ̀ gidigidi nítorí èyí, bó tiẹ̀ jẹ́ pé fún ìgbà díẹ̀, ó lè pọn dandan kí oríṣiríṣi àdánwò kó ìdààmú bá yín,+
7 kí ìgbàgbọ́ yín tí a dán wò+ ní ti bó ṣe jẹ́ ojúlówó tó, èyí tó níye lórí gidigidi ju wúrà tó máa ń ṣègbé láìka pé a fi iná dá an wò* sí, lè jẹ́ orísun ìyìn àti ògo àti ọlá nígbà ìfihàn Jésù Kristi.+
8 Bí ẹ ò tiẹ̀ rí i rí, ẹ nífẹ̀ẹ́ rẹ̀. Bí ẹ ò tiẹ̀ rí i báyìí, síbẹ̀ ẹ ní ìgbàgbọ́ nínú rẹ̀, inú yín sì ń dùn gan-an, ayọ̀ yín kọjá àfẹnusọ, ó sì jẹ́ ológo,
9 bí ọwọ́ yín ṣe ń tẹ èrè ìgbàgbọ́ yín, ìgbàlà yín.*+
10 Ní ti ìgbàlà yìí, àwọn wòlíì tí wọ́n sọ tẹ́lẹ̀ nípa inú rere àìlẹ́tọ̀ọ́sí tó jẹ́ tiyín, fara balẹ̀ wádìí, wọ́n sì fẹ̀sọ̀ wá a.+
11 Wọn ò yéé wádìí àkókò náà gan-an tàbí ìgbà tí ẹ̀mí tó wà nínú wọn ń tọ́ka sí nípa Kristi,+ bó ṣe jẹ́rìí ṣáájú nípa àwọn ìyà tí Kristi máa jẹ+ àti ògo tó máa tẹ̀ lé e.
12 A ṣí i payá fún wọn pé wọ́n ń ṣe òjíṣẹ́, kì í ṣe fún ara wọn, àmọ́ fún yín, nípa àwọn ohun tí àwọn tó kéde ìhìn rere fún yín ti wá sọ fún yín nípasẹ̀ ẹ̀mí mímọ́ tó wá láti ọ̀run.+ Ó wu àwọn áńgẹ́lì gan-an pé kí wọ́n wo àwọn nǹkan yìí fínnífínní.
13 Nítorí náà, ẹ múra ọkàn yín sílẹ̀ láti ṣiṣẹ́;+ ẹ máa ronú bó ṣe tọ́ nígbà gbogbo; + ẹ máa retí inú rere àìlẹ́tọ̀ọ́sí tí a máa fún yín nígbà ìfihàn Jésù Kristi.
14 Bí ọmọ tó ń ṣègbọràn, ẹ má ṣe jẹ́ kí àwọn ohun tí ẹ nífẹ̀ẹ́ sí tẹ́lẹ̀ torí àìmọ̀kan yín tún máa darí yín,*
15 àmọ́ bíi ti Ẹni Mímọ́ tó pè yín, kí ẹ̀yin náà di mímọ́ nínú gbogbo ìwà yín,+
16 nítorí a ti kọ ọ́ pé: “Ẹ gbọ́dọ̀ jẹ́ mímọ́, torí èmi jẹ́ mímọ́.”+
17 Tí ẹ bá sì ń ké pe Baba tó ń fi iṣẹ́ ọwọ́ ẹnì kọ̀ọ̀kan ṣèdájọ́ láìṣe ojúsàájú,+ ẹ máa fi ìbẹ̀rù hùwà+ ní àkókò tí ẹ fi jẹ́ olùgbé fún ìgbà díẹ̀.*
18 Torí ẹ mọ̀ pé kì í ṣe àwọn ohun tó lè bà jẹ́, bíi fàdákà tàbí wúrà la fi tú yín sílẹ̀,*+ kúrò nínú ìgbésí ayé asán tí àwọn baba ńlá yín fi lé yín lọ́wọ́.*
19 Ẹ̀jẹ̀ iyebíye ni,+ bí ẹ̀jẹ̀ ọ̀dọ́ àgùntàn tí kò ní àbààwọ́n, tí kò sì ní èérí kankan,+ ìyẹn ẹ̀jẹ̀ Kristi.+
20 Lóòótọ́, a ti mọ̀ ọ́n tẹ́lẹ̀, ká tó fi ìpìlẹ̀ ayé lélẹ̀,+ àmọ́ nítorí yín, a wá fi hàn kedere ní ìparí àwọn àkókò.+
21 Nípasẹ̀ rẹ̀ lẹ gba Ọlọ́run gbọ́,+ ẹni tó jí i dìde nínú ikú,+ tó sì fún un ní ògo,+ kí ìgbàgbọ́ àti ìrètí yín lè wà nínú Ọlọ́run.
22 Ní báyìí tí ẹ ti fi ìgbọràn yín sí òtítọ́ wẹ ara yín* mọ́, tí èyí sì mú kí ẹ ní ìfẹ́ ará láìsí ẹ̀tàn,+ kí ẹ ní ìfẹ́ tó jinlẹ̀ sí ara yín látọkàn wá.+
23 Torí a ti fún yín ní ìbí tuntun,+ kì í ṣe nípasẹ̀ irúgbìn* tó lè bà jẹ́, àmọ́ nípasẹ̀ irúgbìn tí kò lè bà jẹ́,+ nípasẹ̀ ọ̀rọ̀ Ọlọ́run alààyè, tó wà títí láé.+
24 Torí “gbogbo ẹran ara* dà bíi koríko, gbogbo ògo rẹ̀ sì dà bí ìtànná àwọn ewéko; koríko máa ń gbẹ, òdòdó sì máa ń rẹ̀ dà nù,
25 àmọ́ ọ̀rọ̀* Jèhófà* wà títí láé.”+ “Ọ̀rọ̀”* yìí ni ìhìn rere tí a kéde rẹ̀ fún yín.+
Àlàyé Ìsàlẹ̀ Ìwé
^ Tàbí “àtìpó.”
^ Tàbí “yọ́ ọ mọ́.”
^ Tàbí “ìgbàlà ọkàn yín.”
^ Tàbí “tún máa sún yín ṣe nǹkan.”
^ Tàbí “àtìpó.”
^ Ní Grk., “la fi rà yín pa dà; dá yín nídè.”
^ Tàbí “tí ẹ jogún bá.”
^ Tàbí “ọkàn yín.”
^ Ìyẹn, irúgbìn tó lè méso jáde tàbí kó bí sí i.
^ Tàbí “gbogbo èèyàn.”
^ Ní Grk., “àsọjáde.”
^ Ní Grk., “Àsọjáde.”