Sámúẹ́lì Kìíní 3:1-21

  • Ọlọ́run pe Sámúẹ́lì, ó sì sọ ọ́ di wòlíì (1-21)

3  Ní gbogbo àkókò yìí, ọmọdékùnrin náà Sámúẹ́lì ń ṣe ìránṣẹ́+ fún Jèhófà níwájú Élì, àmọ́ ọ̀rọ̀ látọ̀dọ̀ Jèhófà ṣọ̀wọ́n lásìkò yẹn; ìran+ rírí kò sì wọ́pọ̀.  Lọ́jọ́ kan, Élì ń sùn nínú yàrá rẹ̀, ojú rẹ̀ ti di bàìbàì; kò sì lè rí nǹkan kan.+  Wọn kò tíì pa fìtílà Ọlọ́run,+ Sámúẹ́lì sì ń sùn nínú tẹ́ńpìlì*+ Jèhófà, níbi tí Àpótí Ọlọ́run wà.  Jèhófà pe Sámúẹ́lì. Ó sì dáhùn pé: “Èmi nìyí.”  Ó sáré lọ sọ́dọ̀ Élì, ó sì sọ pé: “Èmi nìyí, torí o pè mí.” Àmọ́ ó sọ pé: “Mi ò pè ọ́. Pa dà lọ sùn.” Torí náà, ó lọ sùn.  Jèhófà pè é lẹ́ẹ̀kan sí i pé: “Sámúẹ́lì!” Torí náà, Sámúẹ́lì dìde, ó sì lọ sọ́dọ̀ Élì, ó sọ pé: “Èmi nìyí, torí o pè mí.” Àmọ́ ó sọ pé: “Mi ò pè ọ́, ọmọ mi. Pa dà lọ sùn.”  (Sámúẹ́lì kò tíì mọ Jèhófà dáadáa, nítorí Jèhófà kò tíì bẹ̀rẹ̀ sí í bá a sọ̀rọ̀.)+  Nítorí náà, Jèhófà tún pè é ní ìgbà kẹta pé: “Sámúẹ́lì!” Ó tún dìde, ó lọ sọ́dọ̀ Élì, ó sì sọ̀ pé: “Èmi nìyí, torí o pè mí.” Élì wá mọ̀ pé Jèhófà ló ń pe ọmọdékùnrin náà.  Nítorí náà, Élì sọ fún Sámúẹ́lì pé: “Lọ sùn, bí ó bá tún pè ọ́, kí o sọ pé, ‘Sọ̀rọ̀, Jèhófà, nítorí ìránṣẹ́ rẹ ń gbọ́.’” Torí náà, Sámúẹ́lì lọ, ó sì sùn sí àyè rẹ̀. 10  Jèhófà wá, ó dúró níbẹ̀, ó sì pè é bíi ti àtẹ̀yìnwá pé: “Sámúẹ́lì, Sámúẹ́lì!” Sámúẹ́lì bá sọ pé: “Sọ̀rọ̀, nítorí ìránṣẹ́ rẹ ń gbọ́.” 11  Jèhófà sọ fún Sámúẹ́lì pé: “Wò ó! Màá ṣe ohun kan ní Ísírẹ́lì tó jẹ́ pé ẹnikẹ́ni tó bá gbọ́ nípa rẹ̀, etí rẹ̀ méjèèjì á hó yee.+ 12  Ní ọjọ́ yẹn, màá ṣe gbogbo ohun tí mo sọ nípa Élì àti nípa ilé rẹ̀, láti ìbẹ̀rẹ̀ dé òpin.+ 13  Sọ fún un pé màá ṣe ìdájọ́ tó máa wà títí láé fún ilé rẹ̀ nítorí ẹ̀ṣẹ̀ tí ó mọ̀ nípa rẹ̀,+ torí àwọn ọmọ rẹ̀ ń sọ̀rọ̀ òdì sí Ọlọ́run,+ àmọ́ kò bá wọn wí.+ 14  Ìdí nìyẹn tí mo fi búra fún ilé Élì pé ẹbọ tàbí ọrẹ kò ní lè pẹ̀tù sí ẹ̀ṣẹ̀ ilé Élì láé.”+ 15  Sámúẹ́lì sùn títí di àárọ̀, lẹ́yìn náà ó ṣí àwọn ilẹ̀kùn ilé Jèhófà. Ẹ̀rù ń ba Sámúẹ́lì láti sọ ìran náà fún Élì. 16  Ṣùgbọ́n Élì pe Sámúẹ́lì, ó ní: “Sámúẹ́lì, ọmọ mi!” Ó dáhùn pé: “Èmi nìyí.” 17  Ó bi í pé: “Ọ̀rọ̀ wo ló sọ fún ọ? Jọ̀wọ́, má fi pa mọ́ fún mi. Kí Ọlọ́run fi ìyà jẹ ọ́ gan-an, tí o bá fi ọ̀rọ̀ kan pa mọ́ fún mi nínú gbogbo ohun tó sọ fún ọ.” 18  Torí náà, Sámúẹ́lì sọ gbogbo ọ̀rọ̀ náà fún un, kò sì fi ohunkóhun pa mọ́ fún un. Élì sọ pé: “Jèhófà ni. Kí ó ṣe ohun tó dára ní ojú rẹ̀.” 19  Sámúẹ́lì ń dàgbà sí i, Jèhófà fúnra rẹ̀ wà pẹ̀lú rẹ̀,+ kò sì jẹ́ kí èyíkéyìí nínú gbogbo ọ̀rọ̀ rẹ̀ lọ láìṣẹ.* 20  Gbogbo Ísírẹ́lì láti Dánì títí dé Bíá-ṣébà sì wá mọ̀ pé Sámúẹ́lì ti di wòlíì Jèhófà. 21  Jèhófà sì ń fara hàn ní Ṣílò, nítorí Jèhófà ti jẹ́ kí Sámúẹ́lì mọ òun ní Ṣílò nípasẹ̀ ọ̀rọ̀ Jèhófà.+

Àlàyé Ìsàlẹ̀ Ìwé

Ìyẹn, àgọ́ ìjọsìn.
Ní Héb., “bọ́ sí ilẹ̀.”