Sámúẹ́lì Kìíní 8:1-22
8 Nígbà tí Sámúẹ́lì darúgbó, ó yan àwọn ọmọkùnrin rẹ̀ láti máa ṣe onídàájọ́ Ísírẹ́lì.
2 Orúkọ ọmọkùnrin rẹ̀ àkọ́bí ni Jóẹ́lì, orúkọ èkejì sì ni Ábíjà;+ wọ́n jẹ́ onídàájọ́ ní Bíá-ṣébà.
3 Àmọ́ àwọn ọmọ rẹ̀ kò tẹ̀ lé àpẹẹrẹ rẹ̀; ọkàn wọn ń fà sí jíjẹ èrè tí kò tọ́,+ wọ́n ń gba àbẹ̀tẹ́lẹ̀,+ wọ́n sì ń yí ìdájọ́ po.+
4 Nígbà tó yá, gbogbo àgbààgbà Ísírẹ́lì kóra jọ, wọ́n sì wá sọ́dọ̀ Sámúẹ́lì ní Rámà.
5 Wọ́n sọ fún un pé: “Wò ó! O ti darúgbó, ṣùgbọ́n àwọn ọmọ rẹ kò tẹ̀ lé àpẹẹrẹ rẹ. Ní báyìí, yan ọba fún wa tí á máa ṣe ìdájọ́ wa bíi ti gbogbo orílẹ̀-èdè yòókù.”+
6 Àmọ́, kò dùn mọ́ Sámúẹ́lì nínú* bí wọ́n ṣe sọ pé: “Fún wa ní ọba tí á máa ṣe ìdájọ́ wa.” Sámúẹ́lì wá gbàdúrà sí Jèhófà,
7 Jèhófà sì sọ fún Sámúẹ́lì pé: “Fetí sí gbogbo ohun tí àwọn èèyàn náà sọ fún ọ; nítorí kì í ṣe ìwọ ni wọ́n kọ̀, àmọ́ èmi ni wọ́n kọ̀ ní ọba wọn.+
8 Bí wọ́n ti ń ṣe láti ọjọ́ tí mo ti mú wọn jáde kúrò ní Íjíbítì ni wọ́n ń ṣe títí di òní yìí; wọ́n á fi mí sílẹ̀,+ wọ́n á sì lọ máa sin àwọn ọlọ́run míì,+ ohun kan náà ni wọ́n ń ṣe sí ọ báyìí.
9 Ní báyìí fetí sí wọn. Síbẹ̀, kìlọ̀ fún wọn gidigidi; sọ ohun tí ọba tó máa jẹ lé wọn lórí máa lẹ́tọ̀ọ́ láti gbà.”
10 Torí náà, Sámúẹ́lì sọ gbogbo ọ̀rọ̀ Jèhófà fún àwọn èèyàn tí wọ́n ní kí Sámúẹ́lì fún àwọn ní ọba.
11 Ó ní: “Ohun tí ọba tó bá jẹ lórí yín máa lẹ́tọ̀ọ́ láti gbà nìyí:+ Á mú àwọn ọmọkùnrin yín,+ á sì fi wọ́n sínú àwọn kẹ̀kẹ́ ẹṣin rẹ̀,+ á wá sọ wọ́n di agẹṣin rẹ̀,+ àwọn kan á sì ní láti máa sáré níwájú àwọn kẹ̀kẹ́ ẹṣin rẹ̀.
12 Á yan àwọn olórí ẹgbẹẹgbẹ̀rún+ àti àwọn olórí àràádọ́ta+ fún ara rẹ̀, àwọn kan á máa bá a túlẹ̀,+ wọ́n á máa bá a kórè,+ wọ́n á sì máa ṣe ohun ìjà fún un àti àwọn ohun èlò kẹ̀kẹ́ ẹṣin rẹ̀.+
13 Á mú àwọn ọmọbìnrin yín, á sì sọ wọ́n di olùpo òróró ìpara,* alásè àti olùṣe búrẹ́dì.+
14 Á gba èyí tó dára jù lára àwọn oko yín àti àwọn ọgbà àjàrà+ yín àti àwọn oko ólífì yín, á sì fún àwọn ìránṣẹ́ rẹ̀.
15 Á gba ìdá mẹ́wàá àwọn oko ọkà yín àti àwọn ọgbà àjàrà yín, á sì fún àwọn òṣìṣẹ́ ààfin rẹ̀ àti àwọn ìránṣẹ́ rẹ̀.
16 Á gba àwọn ìránṣẹ́ yín lọ́kùnrin àti lóbìnrin, àwọn ọ̀wọ́ ẹran yín tó dára jù àti àwọn kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ yín, á sì máa lò wọ́n fún iṣẹ́ tirẹ̀.+
17 Á gba ìdá mẹ́wàá agbo ẹran yín,+ ẹ ó sì di ìránṣẹ́ rẹ̀.
18 Ọjọ́ náà ń bọ̀ tí ẹ máa ké jáde nítorí ọba tí ẹ yàn fún ara yín,+ àmọ́ Jèhófà kò ní dá yín lóhùn ní ọjọ́ yẹn.”
19 Síbẹ̀, àwọn èèyàn náà kò fetí sí ohun tí Sámúẹ́lì sọ fún wọn, wọ́n ní: “Àní sẹ́, a ti pinnu láti ní ọba tiwa.
20 A ó sì wá dà bíi gbogbo orílẹ̀-èdè yòókù, ọba wa yóò sì máa ṣe ìdájọ́ wa, yóò máa darí wa, yóò sì máa jagun fún wa.”
21 Lẹ́yìn tí Sámúẹ́lì gbọ́ gbogbo ọ̀rọ̀ tí àwọn èèyàn náà sọ, ó tún ọ̀rọ̀ náà sọ fún* Jèhófà.
22 Jèhófà sọ fún Sámúẹ́lì pé: “Fetí sí wọn, kí o sì fi ọba jẹ lé wọn lórí.”+ Sámúẹ́lì wá sọ fún àwọn ọkùnrin Ísírẹ́lì pé: “Kí kálukú yín pa dà sí ìlú rẹ̀.”
Àlàyé Ìsàlẹ̀ Ìwé
^ Ní Héb., “ó burú lójú Sámúẹ́lì.”
^ Tàbí “àwọn olùṣe lọ́fíńdà.”
^ Ní Héb., “ní etí.”