Ìwé Kìíní sí Tímótì 3:1-16
3 Ọ̀rọ̀ yìí ṣeé gbára lé: Tí ọkùnrin kan bá ń sapá láti di alábòójútó,+ iṣẹ́ rere ló fẹ́ ṣe.
2 Nítorí náà, alábòójútó gbọ́dọ̀ jẹ́ ẹni tí kò lẹ́gàn, tí kò ní ju ìyàwó kan lọ, tí kì í ṣe àṣejù, tó ní àròjinlẹ̀,*+ tó wà létòlétò, tó ń ṣe aájò àlejò,+ tó kúnjú ìwọ̀n láti kọ́ni,+
3 kì í ṣe ọ̀mùtí,+ kì í ṣe oníwà ipá,* àmọ́ kó máa fòye báni lò,+ kì í ṣe oníjà,+ kì í ṣe ẹni tó fẹ́ràn owó,+
4 kó jẹ́ ọkùnrin tó ń bójú tó* ilé rẹ̀ dáadáa, tí àwọn ọmọ rẹ̀ máa ń tẹrí ba, tí wọ́n sì jẹ́ onígbọràn+
5 (torí tí ọkùnrin kan ò bá mọ bó ṣe máa bójú tó* ilé ara rẹ̀, báwo ló ṣe máa bójú tó ìjọ Ọlọ́run?),
6 kì í ṣe ẹni tí a ṣẹ̀ṣẹ̀ yí lọ́kàn pa dà,+ torí ó lè bẹ̀rẹ̀ sí í gbéraga, kó sì ṣubú sínú ìdájọ́ tí a ṣe fún Èṣù.
7 Yàtọ̀ síyẹn, ó yẹ kí àwọn tó wà níta+ máa sọ̀rọ̀ rẹ̀ dáadáa* kó má bàa ṣubú sínú ẹ̀gàn* àti pańpẹ́ Èṣù.
8 Bákan náà, kí àwọn ìránṣẹ́ iṣẹ́ òjíṣẹ́ jẹ́ ẹni tó ń fọwọ́ pàtàkì mú nǹkan, kí wọ́n má ṣe jẹ́ ẹlẹ́nu méjì,* kí wọ́n má ṣe máa mu ọtí* lámujù, kí wọ́n má ṣe máa wá èrè tí kò tọ́,+
9 kí wọ́n ní ẹ̀rí ọkàn tó mọ́+ bí wọ́n ti ń rọ̀ mọ́ àṣírí mímọ́ ti ìgbàgbọ́.
10 Bákan náà, ká kọ́kọ́ dán wọn wò bóyá wọ́n kúnjú ìwọ̀n;* lẹ́yìn náà kí wọ́n di òjíṣẹ́, nítorí wọn ò ní ẹ̀sùn lọ́rùn.+
11 Kí àwọn obìnrin pẹ̀lú jẹ́ ẹni tó ń fọwọ́ pàtàkì mú nǹkan, kí wọ́n má ṣe jẹ́ abanijẹ́,+ kí wọ́n má ṣe jẹ́ aláṣejù, kí wọ́n jẹ́ olóòótọ́ nínú ohun gbogbo.+
12 Kí àwọn ìránṣẹ́ iṣẹ́ òjíṣẹ́ má ṣe ní ju ìyàwó kan lọ, kí wọ́n máa bójú tó àwọn ọmọ wọn àti ìdílé wọn dáadáa.
13 Torí àwọn ọkùnrin tó ń ṣe ìránṣẹ́ lọ́nà tó dáa ń ṣe orúkọ rere fún ara wọn, wọ́n á sì lè sọ̀rọ̀ fàlàlà nípa ìgbàgbọ́ tí a ní nínú Kristi Jésù.
14 Bí mo tiẹ̀ ń retí láti wá sọ́dọ̀ rẹ láìpẹ́, mò ń kọ àwọn nǹkan yìí sí ọ,
15 torí tí mi ò bá tètè dé, kí o lè mọ bó ṣe yẹ kí o máa hùwà nínú ilé Ọlọ́run,+ tó jẹ́ ìjọ Ọlọ́run alààyè, òpó àti ìtìlẹyìn òtítọ́.
16 Ní tòótọ́, a gbà pé àṣírí mímọ́ ti ìfọkànsin Ọlọ́run yìí ga lọ́lá: ‘A fi í hàn nínú ẹran ara,+ a kéde pé ó jẹ́ olódodo nínú ẹ̀mí,+ ó fara han àwọn áńgẹ́lì,+ a wàásù nípa rẹ̀ láàárín àwọn orílẹ̀-èdè,+ a gbà á gbọ́ ní ayé,+ a sì gbà á sókè nínú ògo.’
Àlàyé Ìsàlẹ̀ Ìwé
^ Tàbí “làákàyè; òye.”
^ Tàbí “aluni.”
^ Tàbí “tó ń tọ́jú.”
^ Tàbí “tọ́jú.”
^ Tàbí “ìtìjú.”
^ Tàbí “máa sọ pé ó níwà rere.”
^ Tàbí “fi ọ̀rọ̀ tanni jẹ.”
^ Ní Grk., “wáìnì.”
^ Tàbí “bóyá wọ́n tóótun.”