Ìwé Kìíní sí Tímótì 4:1-16
4 Àmọ́, ọ̀rọ̀ onímìísí* sọ ní kedere pé tó bá yá àwọn kan máa yẹsẹ̀ kúrò nínú ìgbàgbọ́, wọ́n á máa tẹ́tí sí àwọn ọ̀rọ̀ onímìísí*+ tó ń ṣini lọ́nà àti àwọn ẹ̀kọ́ àwọn ẹ̀mí èṣù,
2 nípasẹ̀ àgàbàgebè àwọn èèyàn tó ń parọ́,+ bíi pé irin ìsàmì ti dá àpá sí ẹ̀rí ọkàn wọn.
3 Wọ́n ka ìgbéyàwó léèwọ̀,+ wọ́n pàṣẹ pé kí àwọn èèyàn yẹra fún àwọn oúnjẹ+ tí Ọlọ́run dá pé kí àwọn tó ní ìgbàgbọ́+ tí wọ́n sì mọ òtítọ́ tó péye máa jẹ,+ kí wọ́n sì máa dúpẹ́.
4 Torí gbogbo ohun tí Ọlọ́run dá ló dára,+ kò sì yẹ ká kọ ohunkóhun+ tí a bá fi ìdúpẹ́ gbà á,
5 nítorí a ti sọ ọ́ di mímọ́ nípasẹ̀ ọ̀rọ̀ Ọlọ́run àti àdúrà tí a gbà sórí rẹ̀.
6 Tí o bá fún àwọn ará ní ìtọ́ni yìí, o máa jẹ́ òjíṣẹ́ rere fún Kristi Jésù, tí a fi àwọn ọ̀rọ̀ ìgbàgbọ́ bọ́ àti ẹ̀kọ́ rere, èyí tí o ti tẹ̀ lé pẹ́kípẹ́kí.+
7 Àmọ́, má ṣe tẹ́tí sí àwọn ìtàn èké+ tí kò buyì kúnni, irú èyí tí àwọn obìnrin tó ti darúgbó máa ń sọ. Kàkà bẹ́ẹ̀, kọ́ ara rẹ láti fi ìfọkànsin Ọlọ́run ṣe àfojúsùn rẹ.
8 Torí àǹfààní díẹ̀ wà nínú eré ìmárale,* àmọ́ ìfọkànsin Ọlọ́run ṣàǹfààní fún ohun gbogbo, ní ti pé ó ní ìlérí ìwàláàyè ní báyìí àti ìlérí ìwàláàyè ti ọjọ́ iwájú.+
9 Ọ̀rọ̀ náà ṣeé gbára lé, ó sì yẹ ká gbà á délẹ̀délẹ̀.
10 Ìdí nìyí tí a fi ń ṣiṣẹ́ kára, tí a sì ń sa gbogbo ipá wa,+ torí a ní ìrètí nínú Ọlọ́run alààyè, tó jẹ́ Olùgbàlà+ onírúurú èèyàn,+ ní pàtàkì àwọn olóòótọ́.
11 Máa pa àṣẹ yìí fúnni, kí o sì máa fi kọ́ni.
12 Má ṣe jẹ́ kí ẹnikẹ́ni fojú ọmọdé wò ọ́ rárá. Àmọ́, kí o jẹ́ àpẹẹrẹ fún àwọn olóòótọ́ nínú ọ̀rọ̀, nínú ìwà, nínú ìfẹ́, nínú ìgbàgbọ́, nínú ìwà mímọ́.*
13 Títí màá fi dé, máa tẹra mọ́ kíkàwé fún ìjọ,*+ máa gbani níyànjú,* kí o sì máa kọ́ni.
14 Má fojú kéré ẹ̀bùn tí o ní, èyí tí a fún ọ nípasẹ̀ àsọtẹ́lẹ̀ nígbà tí ìgbìmọ̀ àwọn alàgbà gbé ọwọ́ lé ọ.+
15 Máa ronú* lórí àwọn nǹkan yìí; jẹ́ kó gbà ọ́ lọ́kàn, kí gbogbo èèyàn lè rí i kedere pé ò ń tẹ̀ síwájú.
16 Máa kíyè sí ara rẹ àti ẹ̀kọ́ rẹ+ nígbà gbogbo. Rí i pé o ò jáwọ́ nínú ṣíṣe àwọn nǹkan yìí, torí tí o bá ń ṣe é, wàá lè gba ara rẹ àti àwọn tó ń fetí sí ọ là.+
Àlàyé Ìsàlẹ̀ Ìwé
^ Ní Grk., “ẹ̀mí.”
^ Ní Grk., “àwọn ẹ̀mí.”
^ Tàbí “ara kíkọ́.”
^ Tàbí “ìjẹ́mímọ́.”
^ Ní Grk., “ní gbangba.”
^ Tàbí “máa fúnni níṣìírí.”
^ Tàbí “Máa ṣàṣàrò.”