Ìwé Kìíní sí Tímótì 5:1-25

  • Bí o ṣe máa hùwà sí àwọn ọ̀dọ́ àtàwọn àgbà (1, 2)

  • Máa ran àwọn opó lọ́wọ́ (3-16)

    • Pèsè fún ìdílé rẹ (8)

  • Bọlá fún àwọn alàgbà tó ń ṣiṣẹ́ kára (17-25)

    • ‘Máa mu wáìnì díẹ̀ torí inú rẹ’ (23)

5  Má ṣe fi ọ̀rọ̀ líle bá àgbà ọkùnrin wí.+ Kàkà bẹ́ẹ̀, ṣe ni kí o pàrọwà fún un bíi bàbá, pàrọwà fún àwọn ọ̀dọ́kùnrin bí ọmọ ìyá,  àwọn àgbà obìnrin bí ìyá, àwọn ọ̀dọ́bìnrin bí ọmọ ìyá, pẹ̀lú gbogbo ìwà mímọ́.  Máa gba ti àwọn opó rò,* àwọn tí wọ́n jẹ́ opó lóòótọ́.*+  Àmọ́ tí opó èyíkéyìí bá ní àwọn ọmọ tàbí ọmọ ọmọ, kí wọ́n kọ́kọ́ fi ìfọkànsin Ọlọ́run hùwà nínú ilé tiwọn,+ kí wọ́n sì san àwọn ohun tó yẹ pa dà fún àwọn òbí wọn àti àwọn òbí wọn àgbà,+ torí inú Ọlọ́run dùn sí èyí.+  Obìnrin tó jẹ́ opó lóòótọ́, tí a sì fi sílẹ̀ láìní nǹkan kan, nírètí nínú Ọlọ́run,+ ó túbọ̀ ń rawọ́ ẹ̀bẹ̀, ó sì ń gbàdúrà tọ̀sántòru.+  Àmọ́ èyí tó ń tẹ́ ìfẹ́kúfẹ̀ẹ́ ara rẹ̀ lọ́rùn ti kú bó tiẹ̀ ṣì wà láàyè.  Torí náà, máa fún wọn ní àwọn ìtọ́ni* yìí, kí wọ́n má bàa ní ẹ̀gàn.  Ó dájú pé tí ẹnikẹ́ni kò bá pèsè fún àwọn tirẹ̀, pàápàá fún ìdílé rẹ̀, ó ti sẹ́ ìgbàgbọ́, ó sì burú ju ẹni tí kò ní ìgbàgbọ́.+  Kí ẹ kọ orúkọ opó tí ọjọ́ orí rẹ̀ kò bá dín ní ọgọ́ta (60) ọdún sílẹ̀, tó jẹ́ ìyàwó ọkùnrin kan tẹ́lẹ̀, 10  tí wọ́n mọ̀ sí ẹni tó ń ṣe àwọn iṣẹ́ rere,+ tó bá tọ́ àwọn ọmọ,+ tó bá ṣe aájò àlejò,+ tó bá fọ ẹsẹ̀ àwọn ẹni mímọ́,+ tó bá ṣèrànwọ́ fún àwọn tí ìyà ń jẹ,+ tó sì ń ṣe gbogbo iṣẹ́ rere tọkàntọkàn. 11  Àmọ́ ṣá o, ẹ má kọ orúkọ àwọn opó tí ọjọ́ orí wọn ṣì kéré sílẹ̀, torí tí ìfẹ́ láti ní ìbálòpọ̀ bá ń dí wọn lọ́wọ́ ìfẹ́ ti Kristi, wọ́n á fẹ́ ní ọkọ. 12  A máa dá wọn lẹ́jọ́ torí wọ́n ti pa ìgbàgbọ́ tí wọ́n kọ́kọ́ ní* tì. 13  Bákan náà, wọ́n tún sọ ara wọn di aláìníṣẹ́, wọ́n ń tọ ojúlé kiri; àní, kì í ṣe pé wọn ò níṣẹ́ nìkan, wọ́n tún ń ṣòfófó, wọ́n sì ń tojú bọ ọ̀rọ̀ ọlọ́rọ̀,+ wọ́n ń sọ àwọn nǹkan tí kò yẹ kí wọ́n sọ. 14  Torí náà, ó wù mí kí àwọn opó tí ọjọ́ orí wọn ṣì kéré ní ọkọ,+ kí wọ́n bímọ,+ kí wọ́n máa tọ́jú ilé, kí wọ́n má bàa fàyè gba àwọn alátakò láti fẹ̀sùn kàn wọ́n. 15  Kódà, àwọn kan ti fi ọ̀nà òtítọ́ sílẹ̀ kí wọ́n lè tẹ̀ lé Sátánì. 16  Tí obìnrin èyíkéyìí tó jẹ́ onígbàgbọ́ bá ní àwọn mọ̀lẹ́bí tó jẹ́ opó, kó ràn wọ́n lọ́wọ́, kí wọ́n má bàa di ẹrù ìjọ. Ìjọ á sì lè ṣèrànwọ́ fún àwọn tó jẹ́ opó ní tòótọ́.*+ 17  Ó yẹ ká fún àwọn alàgbà tó ń ṣe àbójútó lọ́nà tó dáa+ ní ọlá ìlọ́po méjì,+ pàápàá àwọn tó ń ṣiṣẹ́ kára nínú ọ̀rọ̀ sísọ àti kíkọ́ni.+ 18  Torí ìwé mímọ́ sọ pé, “O ò gbọ́dọ̀ di ẹnu akọ màlúù nígbà tó bá ń pa ọkà,”+ àti pé, “Owó iṣẹ́ tọ́ sí òṣìṣẹ́.”+ 19  Má ṣe gba ẹ̀sùn tí wọ́n fi kan àgbà ọkùnrin,* àfi tí ẹni méjì tàbí mẹ́ta bá jẹ́rìí sí i.+ 20  Bá àwọn tó sọ ẹ̀ṣẹ̀ dàṣà++ níṣojú gbogbo àwùjọ náà, kó lè jẹ́ ìkìlọ̀ fún àwọn yòókù.* 21  Mo pàṣẹ tó rinlẹ̀ yìí fún ọ níwájú Ọlọ́run àti Kristi Jésù àti àwọn áńgẹ́lì àyànfẹ́ pé kí o máa tẹ̀ lé àwọn ìtọ́ni yìí láìṣe ẹ̀tanú tàbí ojúsàájú.+ 22  Má fi ìkánjú gbé ọwọ́ lé ọkùnrin èyíkéyìí láé;*+ má sì pín nínú ẹ̀ṣẹ̀ àwọn ẹlòmíì; jẹ́ oníwà mímọ́. 23  Má mu omi mọ́,* àmọ́ máa mu wáìnì díẹ̀ nítorí inú rẹ àti àìsàn rẹ tó ń ṣe lemọ́lemọ́. 24  Àwọn kan wà tí ẹ̀ṣẹ̀ wọn máa ń hàn sí ọ̀pọ̀ èèyàn, ó sì máa ń yọrí sí ìdájọ́ lẹ́sẹ̀kẹsẹ̀, àmọ́ ẹ̀ṣẹ̀ àwọn míì máa ń hàn síta nígbà tó bá yá.+ 25  Bákan náà, iṣẹ́ rere máa ń hàn síta,+ a ò sì lè fi àwọn tí kò hàn síta pa mọ́ lọ títí.+

Àlàyé Ìsàlẹ̀ Ìwé

Ní Grk., “Máa bọlá fún àwọn opó.”
Tàbí “àwọn opó tí wọ́n nílò ìrànwọ́ lóòótọ́”; ìyẹn, àwọn tí kò ní ẹni tó lè ràn wọ́n lọ́wọ́.
Tàbí “àṣẹ.”
Tàbí “ìlérí tí wọ́n kọ́kọ́ ṣe.”
Tàbí “àwọn opó tí wọ́n nílò ìrànwọ́ lóòótọ́”; ìyẹn, àwọn tí kò ní ẹni tó lè ràn wọ́n lọ́wọ́.
Tàbí “alàgbà.”
Ní Grk., “kí ẹ̀rù lè ba àwọn yòókù.”
Ìyẹn, má ṣe fi ìkánjú yan ọkùnrin èyíkéyìí sípò.
Tàbí “Má mu omi nìkan mọ́.”