Ìwé Kìíní sí Àwọn Ará Tẹsalóníkà 5:1-28
5 Ẹ̀yin ará, ní ti àwọn ìgbà àti àwọn àsìkò, ẹ ò nílò kí a kọ nǹkan kan ránṣẹ́ sí yín.
2 Nítorí ẹ̀yin fúnra yín mọ̀ dáadáa pé ọjọ́ Jèhófà*+ ń bọ̀ bí olè ní òru.+
3 Nígbàkigbà tí wọ́n bá ń sọ pé, “Àlàáfíà àti ààbò!” ìgbà náà ni ìparun òjijì yóò dé lọ́gán sórí wọn,+ bí ìgbà tí obìnrin tó lóyún bá bẹ̀rẹ̀ sí í rọbí, wọn ò sì ní yè bọ́ lọ́nàkọnà.
4 Àmọ́, ẹ̀yin ará, ẹ ò sí nínú òkùnkùn, tí ọjọ́ yẹn á fi dé bá yín lójijì bí ìgbà tí ilẹ̀ mọ́ bá olè,
5 nítorí gbogbo yín jẹ́ ọmọ ìmọ́lẹ̀ àti ọmọ ọ̀sán.+ Àwa kì í ṣe ti òru tàbí ti òkùnkùn.+
6 Torí náà, ẹ má ṣe jẹ́ kí a máa sùn bí àwọn yòókù ti ń ṣe,+ àmọ́ ẹ jẹ́ kí a wà lójúfò,+ kí a sì máa ronú bó ṣe tọ́.+
7 Nítorí àwọn tó ń sùn máa ń sùn ní òru, àwọn tó sì ń mutí yó máa ń mutí yó ní òru.+
8 Àmọ́ ní ti àwa tí a jẹ́ ti ọ̀sán, ẹ jẹ́ kí a máa ronú bó ṣe tọ́, kí a gbé àwo ìgbàyà ìgbàgbọ́ àti ìfẹ́ wọ̀, kí a sì dé ìrètí ìgbàlà bí akoto*+
9 nítorí Ọlọ́run kò yàn wá fún ìrunú, bí kò ṣe láti rí ìgbàlà+ nípasẹ̀ Jésù Kristi Olúwa wa.
10 Ó kú fún wa,+ kó lè jẹ́ pé, bóyá a sùn* tàbí a ò sùn, a máa lè wà láàyè pẹ̀lú rẹ̀.+
11 Nítorí náà, ẹ máa fún ara yín níṣìírí,* kí ẹ sì máa gbé ara yín ró,+ bí ẹ ti ń ṣe ní tòótọ́.
12 Ní báyìí, ẹ̀yin ará, a fẹ́ kí ẹ máa bọ̀wọ̀ fún àwọn tó ń ṣiṣẹ́ kára láàárín yín, tí wọ́n ń ṣe àbójútó yín nínú Olúwa, tí wọ́n sì ń gbà yín níyànjú;
13 ẹ máa kà wọ́n sí lọ́nà àrà ọ̀tọ̀ nínú ìfẹ́ nítorí iṣẹ́ wọn.+ Ẹ wà ní àlàáfíà pẹ̀lú ara yín.+
14 Lẹ́sẹ̀ kan náà, ẹ̀yin ará, à ń rọ̀ yín pé kí ẹ máa kìlọ̀ fún àwọn tó ń ṣe ségesège,*+ ẹ máa sọ̀rọ̀ ìtùnú fún àwọn tó sorí kọ́,* ẹ máa ran àwọn aláìlera lọ́wọ́, ẹ máa mú sùúrù fún gbogbo èèyàn.+
15 Ẹ rí i pé ẹnikẹ́ni ò fi búburú san búburú fún ẹnì kankan,+ kí ẹ sì máa fìgbà gbogbo wá ohun rere fún ara yín àti fún gbogbo àwọn míì.+
16 Ẹ máa yọ̀ nígbà gbogbo.+
17 Ẹ máa gbàdúrà nígbà gbogbo.+
18 Ẹ máa dúpẹ́ ohun gbogbo.+ Ohun tí Ọlọ́run fẹ́ fún yín nìyí nínú Kristi Jésù.
19 Ẹ má ṣe pa iná ẹ̀mí.+
20 Ẹ má ṣe kó àwọn ọ̀rọ̀ àsọtẹ́lẹ̀ dà nù.+
21 Ẹ máa wádìí ohun gbogbo dájú;+ ẹ di èyí tó dára mú ṣinṣin.
22 Ẹ yẹra fún gbogbo ìwà burúkú.+
23 Kí Ọlọ́run àlàáfíà fúnra rẹ̀ sọ yín di mímọ́ pátápátá. Kí ẹ̀mí àti ọkàn* àti ara ẹ̀yin ará, tó dára ní gbogbo ọ̀nà, jẹ́ aláìlẹ́bi nígbà tí Olúwa wa Jésù Kristi bá wà níhìn-ín.+
24 Ẹni tó ń pè yín jẹ́ olóòótọ́, ó sì dájú pé ó máa ṣe bẹ́ẹ̀.
25 Ẹ̀yin ará, ẹ máa gbàdúrà fún wa.+
26 Ẹ fi ìfẹnukonu mímọ́ kí gbogbo àwọn ará.
27 Mò ń fi dandan lé e fún yín ní orúkọ Olúwa pé kí ẹ ka lẹ́tà yìí fún gbogbo àwọn ará.+
28 Kí inú rere àìlẹ́tọ̀ọ́sí Olúwa wa Jésù Kristi wà pẹ̀lú yín.
Àlàyé Ìsàlẹ̀ Ìwé
^ Irú èyí tí àwọn ọmọ ogun máa ń dé.
^ Tàbí “sùn nínú ikú.”
^ Tàbí “tu ara yín nínú.”
^ Tàbí “gba àwọn tó ń ṣe ségesège níyànjú.”
^ Tàbí “àwọn tó rẹ̀wẹ̀sì.” Ní Grk., “àwọn tó ní ọkàn kékeré.”
^ Tàbí “ẹ̀mí.” Wo Àlàyé Ọ̀rọ̀.