Àwọn Ọba Kejì 1:1-18

  • Èlíjà sọ tẹ́lẹ̀ pé Ahasáyà máa kú (1-18)

1  Lẹ́yìn ikú Áhábù, Móábù+ ṣọ̀tẹ̀ sí Ísírẹ́lì.  Nígbà náà, Ahasáyà já bọ́ láti ibi asẹ́ tó wà ní yàrá òrùlé rẹ̀ ní Samáríà, ó sì fara pa. Torí náà, ó rán àwọn òjíṣẹ́, ó sì sọ fún wọn pé: “Ẹ lọ wádìí lọ́dọ̀ Baali-sébúbù ọlọ́run Ẹ́kírónì+ bóyá ibi tí mo fi ṣèṣe yìí máa san.”+  Àmọ́, áńgẹ́lì Jèhófà sọ fún Èlíjà*+ ará Tíṣíbè pé: “Gbéra, lọ pàdé àwọn òjíṣẹ́ ọba Samáríà, kí o sọ fún wọn pé, ‘Ṣé kò sí Ọlọ́run ní Ísírẹ́lì ni, tí ẹ fi ń lọ wádìí lọ́dọ̀ Baali-sébúbù ọlọ́run Ẹ́kírónì?+  Nítorí náà, ohun tí Jèhófà sọ nìyí: “O ò ní kúrò lórí ibùsùn tí o wà yìí, torí ó dájú pé wàá kú.”’” Èlíjà sì bá tirẹ̀ lọ.  Nígbà tí àwọn òjíṣẹ́ náà pa dà sọ́dọ̀ rẹ̀, lẹ́sẹ̀kẹsẹ̀, ó béèrè lọ́wọ́ wọn pé: “Kí ló dé tí ẹ fi pa dà?”  Wọ́n dá a lóhùn pé: “Ọkùnrin kan wá pàdé wa, ó sọ fún wa pé, ‘Ẹ pa dà sọ́dọ̀ ọba tó rán yín, kí ẹ sì sọ fún un pé, “Ohun tí Jèhófà sọ nìyí: ‘Ṣé kò sí Ọlọ́run ní Ísírẹ́lì ni, tí o fi ní kí wọ́n lọ wádìí lọ́dọ̀ Baali-sébúbù ọlọ́run Ẹ́kírónì? Nítorí náà, o ò ní kúrò lórí ibùsùn tí o wà yìí, torí ó dájú pé wàá kú.’”’”+  Ó wá béèrè lọ́wọ́ wọn pé: “Báwo ni ọkùnrin tó wá pàdé yín, tó sọ ọ̀rọ̀ yìí fún yín ṣe rí?”  Torí náà, wọ́n sọ fún un pé: “Ọkùnrin náà wọ aṣọ onírun,+ ó sì de àmùrè awọ mọ́ ìbàdí rẹ̀.”+ Lẹ́sẹ̀kẹsẹ̀, ó sọ pé: “Èlíjà ará Tíṣíbè ni.”  Ọba wá rán olórí àádọ́ta (50) ọmọ ogun sí i pẹ̀lú àádọ́ta (50) ọkùnrin rẹ̀. Nígbà tó lọ bá Èlíjà, ó rí i tó jókòó sórí òkè. Ó sọ fún un pé: “Èèyàn Ọlọ́run tòótọ́,+ ọba sọ pé, ‘Sọ̀ kalẹ̀ wá.’” 10  Àmọ́ Èlíjà dá olórí àádọ́ta (50) ọmọ ogun náà lóhùn pé: “Ó dáa, tó bá jẹ́ pé èèyàn Ọlọ́run ni mí lóòótọ́, kí iná bọ́ láti ọ̀run,+ kó sì jó ìwọ àti àádọ́ta (50) ọkùnrin rẹ run.” Ni iná bá bọ́ láti ọ̀run, ó sì jó òun àti àádọ́ta (50) ọkùnrin rẹ̀ run. 11  Nítorí náà, ọba tún rán olórí àádọ́ta (50) ọmọ ogun míì sí i pẹ̀lú àádọ́ta (50) ọkùnrin rẹ̀. Ó lọ, ó sì sọ fún un pé: “Èèyàn Ọlọ́run tòótọ́, ohun tí ọba sọ nìyí, ‘Sọ̀ kalẹ̀ wá kíákíá.’” 12  Àmọ́ Èlíjà dá wọn lóhùn pé: “Tó bá jẹ́ pé èèyàn Ọlọ́run tòótọ́ ni mí lóòótọ́, kí iná bọ́ láti ọ̀run, kó sì jó ìwọ àti àádọ́ta (50) ọkùnrin rẹ run.” Ni iná Ọlọ́run bá bọ́ láti ọ̀run, ó sì jó òun àti àádọ́ta (50) ọkùnrin rẹ̀ run. 13  Lẹ́yìn náà, ọba rán olórí àádọ́ta (50) ọmọ ogun kẹta sí i pẹ̀lú àádọ́ta (50) ọkùnrin rẹ̀. Àmọ́ olórí àádọ́ta (50) ọmọ ogun kẹta jáde lọ, ó sì tẹrí ba lórí ìkúnlẹ̀ níwájú Èlíjà, ó bẹ̀rẹ̀ sí í bẹ̀ ẹ́ pé kó ṣojú rere sí òun, ó ní: “Èèyàn Ọlọ́run tòótọ́, jọ̀wọ́, jẹ́ kí ẹ̀mí mi àti ẹ̀mí* àádọ́ta (50) ìránṣẹ́ rẹ yìí ṣeyebíye lójú rẹ. 14  Iná ti bọ́ láti ọ̀run, ó sì ti jó àwọn olórí àádọ́ta (50) ọmọ ogun méjì tó ṣáájú run pẹ̀lú àádọ́ta (50) wọn, ṣùgbọ́n ní báyìí, jẹ́ kí ẹ̀mí* mi ṣeyebíye lójú rẹ.” 15  Áńgẹ́lì Jèhófà wá sọ fún Èlíjà pé: “Sọ̀ kalẹ̀ tẹ̀ lé e. Má bẹ̀rù rẹ̀.” Torí náà, ó dìde, ó sọ̀ kalẹ̀, ó sì tẹ̀ lé e lọ sọ́dọ̀ ọba. 16  Èlíjà wá sọ fún ọba pé, “Ohun tí Jèhófà sọ nìyí: ‘O rán àwọn òjíṣẹ́ pé kí wọ́n lọ wádìí lọ́dọ̀ Baali-sébúbù ọlọ́run Ẹ́kírónì.+ Ṣé kò sí Ọlọ́run ní Ísírẹ́lì ni?+ Kí ló dé tí o ò fi wádìí lọ́dọ̀ rẹ̀? Torí náà, o ò ní kúrò lórí ibùsùn tí o wà yìí, torí ó dájú pé wàá kú.’” 17  Torí náà, ó kú, gẹ́gẹ́ bí ọ̀rọ̀ tí Jèhófà gbẹnu Èlíjà sọ. Àmọ́ torí pé kò ní ọmọkùnrin kankan, Jèhórámù*+ jọba ní ipò rẹ̀, ní ọdún kejì Jèhórámù+ ọmọ Jèhóṣáfátì ọba Júdà. 18  Ní ti ìyókù ìtàn Ahasáyà+ àti ohun tí ó ṣe, ǹjẹ́ kò wà lákọsílẹ̀ nínú ìwé ìtàn ìgbà àwọn ọba Ísírẹ́lì?

Àlàyé Ìsàlẹ̀ Ìwé

Ó túmọ̀ sí “Jèhófà Ni Ọlọ́run Mi.”
Tàbí “jẹ́ kí ọkàn mi àti ọkàn.”
Tàbí “ọkàn.”
Ìyẹn, àbúrò Ahasáyà.