Àwọn Ọba Kejì 15:1-38
15 Ní ọdún kẹtàdínlọ́gbọ̀n Jèróbóámù* ọba Ísírẹ́lì, Asaráyà*+ ọmọ Amasááyà+ ọba Júdà di ọba.+
2 Ọmọ ọdún mẹ́rìndínlógún (16) ni nígbà tó jọba, ọdún méjìléláàádọ́ta (52) ló sì fi ṣàkóso ní Jerúsálẹ́mù. Orúkọ ìyá rẹ̀ ni Jekoláyà tó wá láti Jerúsálẹ́mù.
3 Ó ń ṣe ohun tí ó tọ́ ní ojú Jèhófà bí Amasááyà bàbá rẹ̀ ti ṣe.+
4 Àmọ́ kò mú àwọn ibi gíga kúrò,+ àwọn èèyàn náà ṣì ń rúbọ, wọ́n sì ń mú ẹbọ rú èéfín ní àwọn ibi gíga.+
5 Jèhófà fi àrùn kọ lu ọba, ó sì ya adẹ́tẹ̀+ títí di ọjọ́ ikú rẹ̀; inú ilé kan tó wà lọ́tọ̀ ló ń gbé,+ lásìkò yìí Jótámù+ ọmọ ọba ló ń bójú tó ilé,* ó sì ń dá ẹjọ́ àwọn èèyàn ilẹ̀ náà.+
6 Ní ti ìyókù ìtàn Asaráyà+ àti gbogbo ohun tí ó ṣe, ǹjẹ́ kò wà lákọsílẹ̀ nínú ìwé ìtàn ìgbà àwọn ọba Júdà?
7 Níkẹyìn, Asaráyà sinmi pẹ̀lú àwọn baba ńlá rẹ̀,+ wọ́n sì sin ín pẹ̀lú àwọn baba ńlá rẹ̀ ní Ìlú Dáfídì; Jótámù ọmọ rẹ̀ sì jọba ní ipò rẹ̀.
8 Ní ọdún kejìdínlógójì Asaráyà+ ọba Júdà, Sekaráyà+ ọmọ Jèróbóámù di ọba lórí Ísírẹ́lì ní Samáríà, ó sì fi oṣù mẹ́fà ṣàkóso.
9 Ó ṣe ohun tó burú lójú Jèhófà bí àwọn baba ńlá rẹ̀ ti ṣe. Kò jáwọ́ nínú àwọn ẹ̀ṣẹ̀ tí Jèróbóámù ọmọ Nébátì mú kí Ísírẹ́lì dá.+
10 Ìgbà náà ni Ṣálúmù ọmọ Jábéṣì dìtẹ̀ mọ́ ọn, ó sì pa á+ ní Íbíléámù.+ Lẹ́yìn tó pa á, ó jọba ní ipò rẹ̀.
11 Ní ti ìyókù ìtàn Sekaráyà, ó wà lákọsílẹ̀ nínú ìwé ìtàn ìgbà àwọn ọba Ísírẹ́lì.
12 Èyí mú kí ọ̀rọ̀ tí Jèhófà sọ fún Jéhù ṣẹ pé: “Àwọn ọmọ rẹ títí dé ìran kẹrin+ yóò máa jókòó lórí ìtẹ́ Ísírẹ́lì.”+ Bó sì ṣe ṣẹlẹ̀ nìyẹn.
13 Ṣálúmù ọmọ Jábéṣì di ọba ní ọdún kọkàndínlógójì Ùsáyà+ ọba Júdà, oṣù kan ló sì fi ṣàkóso ní Samáríà.
14 Ìgbà náà ni Ménáhémù ọmọ Gádì wá láti Tírísà+ sí Samáríà, ó sì pa Ṣálúmù+ ọmọ Jábéṣì ní Samáríà. Lẹ́yìn tó pa á, ó jọba ní ipò rẹ̀.
15 Ní ti ìyókù ìtàn Ṣálúmù àti ọ̀tẹ̀ tó dì, ó wà lákọsílẹ̀ nínú ìwé ìtàn ìgbà àwọn ọba Ísírẹ́lì.
16 Ìgbà náà ni Ménáhémù wá láti Tírísà, ó sì ṣẹ́gun Tífísà àti gbogbo àwọn tó wà nínú rẹ̀ àti ìpínlẹ̀ rẹ̀, nítorí pé wọn kò ṣí ẹnubodè rẹ̀ fún un. Ó pa ìlú náà run, ó sì la inú àwọn aboyún tó wà níbẹ̀.
17 Ní ọdún kọkàndínlógójì Asaráyà ọba Júdà, Ménáhémù ọmọ Gádì di ọba lórí Ísírẹ́lì, ó sì fi ọdún mẹ́wàá ṣàkóso ní Samáríà.
18 Ó ń ṣe ohun tó burú lójú Jèhófà. Kò jáwọ́ nínú gbogbo ẹ̀ṣẹ̀ tí Jèróbóámù ọmọ Nébátì mú kí Ísírẹ́lì dá,+ ní gbogbo ọjọ́ rẹ̀.
19 Púlì+ ọba Ásíríà wá sí ilẹ̀ náà, Ménáhémù sì fún Púlì ní ẹgbẹ̀rún kan (1,000) tálẹ́ńtì* fàdákà nítorí ó tì í lẹ́yìn kí ìjọba má bàa bọ́ mọ́ ọn lọ́wọ́.+
20 Nítorí náà, Ménáhémù gba fàdákà náà jọ ní Ísírẹ́lì látọwọ́ àwọn ọlọ́rọ̀ tó lókìkí.+ Ó fún ọba Ásíríà ní àádọ́ta (50) ṣékélì* fàdákà lórí ọkùnrin kọ̀ọ̀kan. Ni ọba Ásíríà bá yíjú pa dà, kò sì dúró ní ilẹ̀ náà.
21 Ní ti ìyókù ìtàn Ménáhémù+ àti gbogbo ohun tí ó ṣe, ǹjẹ́ kò wà lákọsílẹ̀ nínú ìwé ìtàn ìgbà àwọn ọba Ísírẹ́lì?
22 Níkẹyìn, Ménáhémù sinmi pẹ̀lú àwọn baba ńlá rẹ̀; Pekaháyà ọmọ rẹ̀ sì jọba ní ipò rẹ̀.
23 Ní àádọ́ta ọdún Asaráyà ọba Júdà, Pekaháyà ọmọ Ménáhémù di ọba lórí Ísírẹ́lì ní Samáríà, ọdún méjì ló sì fi ṣàkóso.
24 Ó ń ṣe ohun tó burú ní ojú Jèhófà. Kò jáwọ́ nínú àwọn ẹ̀ṣẹ̀ tí Jèróbóámù ọmọ Nébátì mú kí Ísírẹ́lì dá.+
25 Lẹ́yìn náà, olùrànlọ́wọ́ rẹ̀ lójú ogun, ìyẹn Pékà+ ọmọ Remaláyà dìtẹ̀ mọ́ ọn, ó sì pa á ní Samáríà nínú ilé gogoro tó láàbò tó wà ní ilé* ọba, pẹ̀lú Ágóbù àti Áríè. Àádọ́ta (50) ọkùnrin láti ilẹ̀ Gílíádì sì wà pẹ̀lú rẹ̀; lẹ́yìn tó pa á, ó jọba ní ipò rẹ̀.
26 Ní ti ìyókù ìtàn Pekaháyà àti gbogbo ohun tí ó ṣe, ó wà lákọsílẹ̀ nínú ìwé ìtàn ìgbà àwọn ọba Ísírẹ́lì.
27 Ní ọdún kejìléláàádọ́ta Asaráyà ọba Júdà, Pékà+ ọmọ Remaláyà di ọba lórí Ísírẹ́lì ní Samáríà, ogún (20) ọdún ló sì fi ṣàkóso.
28 Ó ń ṣe ohun tó burú ní ojú Jèhófà. Kò sì jáwọ́ nínú àwọn ẹ̀ṣẹ̀ tí Jèróbóámù ọmọ Nébátì mú kí Ísírẹ́lì dá.+
29 Nígbà ayé Pékà ọba Ísírẹ́lì, Tigilati-pílésà+ ọba Ásíríà kógun wọ Íjónì, Ebẹli-bẹti-máákà,+ Jánóà, Kédéṣì,+ Hásórì, Gílíádì+ àti Gálílì, ìyẹn gbogbo ilẹ̀ Náfútálì,+ ó sì gbà á, ó wá kó àwọn tó ń gbé ibẹ̀ lọ sí ìgbèkùn ní Ásíríà.+
30 Lẹ́yìn náà, Hóṣéà+ ọmọ Élà dìtẹ̀ mọ́ Pékà ọmọ Remaláyà, ó ṣá a balẹ̀, ó sì pa á; ó jọba ní ipò rẹ̀ ní ogún ọdún Jótámù+ ọmọ Ùsáyà.
31 Ní ti ìyókù ìtàn Pékà àti gbogbo ohun tí ó ṣe, ó wà lákọsílẹ̀ nínú ìwé ìtàn ìgbà àwọn ọba Ísírẹ́lì.
32 Ní ọdún kejì Pékà ọmọ Remaláyà ọba Ísírẹ́lì, Jótámù+ ọmọ Ùsáyà+ ọba Júdà jọba.
33 Ẹni ọdún mẹ́ẹ̀ẹ́dọ́gbọ̀n (25) ni nígbà tó jọba, ọdún mẹ́rìndínlógún (16) ló sì fi ṣàkóso ní Jerúsálẹ́mù. Orúkọ ìyá rẹ̀ ni Jẹ́rúṣà ọmọ Sádókù.+
34 Ó ń ṣe ohun tí ó tọ́ lójú Jèhófà bí Ùsáyà bàbá rẹ̀ ti ṣe.+
35 Àmọ́ kò mú àwọn ibi gíga kúrò, àwọn èèyàn náà ṣì ń rúbọ, wọ́n sì ń mú ẹbọ rú èéfín ní àwọn ibi gíga.+ Òun ló kọ́ ẹnubodè apá òkè tó wà ní ilé Jèhófà.+
36 Ní ti ìyókù ìtàn Jótámù, ohun tí ó ṣe, ǹjẹ́ kò wà lákọsílẹ̀ nínú ìwé ìtàn ìgbà àwọn ọba Júdà?
37 Lákòókò yẹn, Jèhófà bẹ̀rẹ̀ sí í rán Résínì ọba Síríà àti Pékà+ ọmọ Remaláyà láti gbógun ti Júdà.+
38 Níkẹyìn, Jótámù sinmi pẹ̀lú àwọn baba ńlá rẹ̀, wọ́n sì sin ín pẹ̀lú àwọn baba ńlá rẹ̀ sí Ìlú Dáfídì baba ńlá rẹ̀. Áhásì ọmọ rẹ̀ sì jọba ní ipò rẹ̀.
Àlàyé Ìsàlẹ̀ Ìwé
^ Ìyẹn, Jèróbóámù Kejì.
^ Ó túmọ̀ sí “Jèhófà Ti Ṣèrànwọ́.” Wọ́n pè é ní Ùsáyà ní 2Ọb 15:13; 2Kr 26:1-23; Ais 6:1 àti Sek 14:5.
^ Tàbí “ààfin.”
^ Tálẹ́ńtì kan jẹ́ kìlógíráàmù 34.2. Wo Àfikún B14.
^ Ṣékélì kan jẹ́ gíráàmù 11.4. Wo Àfikún B14.
^ Tàbí “ààfin.”