Àwọn Ọba Kejì 16:1-20
16 Ní ọdún kẹtàdínlógún Pékà ọmọ Remaláyà, Áhásì+ ọmọ Jótámù ọba Júdà di ọba.
2 Ẹni ogún (20) ọdún ni Áhásì nígbà tó jọba, ọdún mẹ́rìndínlógún (16) ló sì fi ṣàkóso ní Jerúsálẹ́mù. Kò ṣe ohun tí ó tọ́ ní ojú Jèhófà Ọlọ́run rẹ̀ bí Dáfídì baba ńlá rẹ̀ ti ṣe.+
3 Kàkà bẹ́ẹ̀, ó rìn ní ọ̀nà àwọn ọba Ísírẹ́lì,+ kódà ó sun ọmọ rẹ̀ nínú iná,+ ó tipa bẹ́ẹ̀ ṣe ohun ìríra tí àwọn orílẹ̀-èdè+ tí Jèhófà lé kúrò níwájú àwọn ọmọ Ísírẹ́lì ń ṣe.
4 Ó tún ń rúbọ, ó sì ń mú ẹbọ rú èéfín lórí àwọn ibi gíga,+ lórí àwọn òkè àti lábẹ́ gbogbo igi tó gbẹ̀rẹ̀gẹ̀jigẹ̀.+
5 Ìgbà náà ni Résínì ọba Síríà àti Pékà ọmọ Remaláyà ọba Ísírẹ́lì wá gbógun ja Jerúsálẹ́mù.+ Wọ́n dó ti Áhásì, àmọ́ wọn ò rí ìlú náà gbà.
6 Ní àkókò yẹn, Résínì ọba Síríà gba Élátì + pa dà fún Édómù, lẹ́yìn náà, ó lé àwọn Júù* kúrò ní Élátì. Àwọn ọmọ Édómù wọ Élátì, wọ́n sì ń gbé ibẹ̀ títí di òní yìí.
7 Nítorí náà, Áhásì rán àwọn òjíṣẹ́ sí Tigilati-pílésà+ ọba Ásíríà, ó ní: “Ìránṣẹ́ rẹ ni mí, ọmọ rẹ sì ni mo jẹ́. Wá gbà mí lọ́wọ́ ọba Síríà àti lọ́wọ́ ọba Ísírẹ́lì tí wọ́n ń gbéjà kò mí.”
8 Áhásì wá kó fàdákà àti wúrà tí wọ́n rí ní ilé Jèhófà àti ní àwọn ibi ìṣúra ilé* ọba, ó sì fi àbẹ̀tẹ́lẹ̀ ránṣẹ́ sí ọba Ásíríà.+
9 Ọba Ásíríà gbọ́ ẹ̀bẹ̀ rẹ̀, ó lọ sí Damásíkù, ó sì gbà á, ó kó àwọn èèyàn inú rẹ̀ lọ sí ìgbèkùn ní Kírì,+ ó sì pa Résínì.+
10 Lẹ́yìn náà, Ọba Áhásì lọ pàdé Tigilati-pílésà ọba Ásíríà ní Damásíkù. Nígbà tó rí pẹpẹ tó wà ní Damásíkù, Ọba Áhásì fi àwòrán pẹpẹ náà ránṣẹ́ sí àlùfáà Úríjà, iṣẹ́ ọnà pẹpẹ náà àti bí wọ́n ṣe mọ ọ́n ló wà nínú àwòrán náà.+
11 Àlùfáà Úríjà+ mọ pẹpẹ+ kan gẹ́gẹ́ bí gbogbo ìlànà tí Ọba Áhásì fi ránṣẹ́ láti Damásíkù. Àlùfáà Úríjà parí mímọ pẹpẹ náà kí Ọba Áhásì tó dé láti Damásíkù.
12 Nígbà tí ọba dé láti Damásíkù tó sì rí pẹpẹ náà, ó lọ sídìí rẹ̀, ó sì rú àwọn ẹbọ lórí rẹ̀.+
13 Orí pẹpẹ náà ló ti mú àwọn ẹbọ sísun rẹ̀ àti àwọn ọrẹ ọkà rẹ̀ rú èéfín; ó tún da àwọn ọrẹ ohun mímu rẹ̀ jáde, ó sì wọ́n ẹ̀jẹ̀ àwọn ẹbọ ìrẹ́pọ̀ rẹ̀ sórí pẹpẹ náà.
14 Nígbà náà, ó gbé pẹpẹ bàbà+ tó wà níwájú Jèhófà kúrò ní àyè rẹ̀ níwájú ilé náà, ìyẹn láti àárín pẹpẹ rẹ̀ àti ilé Jèhófà, ó sì gbé e sí apá àríwá pẹpẹ rẹ̀.
15 Ọba Áhásì pàṣẹ fún àlùfáà Úríjà+ pé: “Mú ẹbọ sísun àárọ̀ rú èéfín lórí pẹpẹ ńlá,+ ohun kan náà ni kí o ṣe sí ọrẹ ọkà ìrọ̀lẹ́,+ ẹbọ sísun ọba àti ọrẹ ọkà rẹ̀, títí kan àwọn ẹbọ sísun gbogbo àwọn èèyàn náà, àwọn ọrẹ ọkà wọn àti àwọn ọrẹ ohun mímu wọn. Kí o wọ́n gbogbo ẹ̀jẹ̀ àwọn ẹbọ sísun àti gbogbo ẹ̀jẹ̀ àwọn ẹbọ yòókù sórí rẹ̀. Ní ti pẹpẹ bàbà náà, jẹ́ kí n pinnu ohun tí màá ṣe nípa rẹ̀.”
16 Àlùfáà Úríjà ṣe gbogbo ohun tí Ọba Áhásì pa láṣẹ.+
17 Yàtọ̀ síyẹn, Ọba Áhásì gé àwọn iṣẹ́ ọnà pẹlẹbẹ-pẹlẹbẹ+ tó wà lẹ́gbẹ̀ẹ́ àwọn kẹ̀kẹ́ ẹrù sí wẹ́wẹ́, ó sì gbé bàsíà kúrò lórí àwọn kẹ̀kẹ́ ẹrù náà,+ ó sọ Òkun kalẹ̀ lórí àwọn akọ màlúù+ tó gbé e dúró, ó sì gbé e sórí ibi tí a fi òkúta tẹ́.+
18 Ibi tó ní ìbòrí tí wọ́n ń lò ní Sábáàtì, èyí tí wọ́n kọ́ sí ilé náà àti ọ̀nà àbáwọlé ọba tó wà ní ìta ló gbé kúrò ní ilé Jèhófà lọ sí ibòmíì; ó ṣe bẹ́ẹ̀ nítorí ọba Ásíríà.
19 Ní ti ìyókù ìtàn Áhásì, ohun tí ó ṣe, ǹjẹ́ kò wà lákọsílẹ̀ nínú ìwé ìtàn ìgbà àwọn ọba Júdà?+
20 Níkẹyìn, Áhásì sinmi pẹ̀lú àwọn baba ńlá rẹ̀, wọ́n sì sin ín pẹ̀lú àwọn baba ńlá rẹ̀ sí Ìlú Dáfídì; Hẹsikáyà*+ ọmọ rẹ̀ sì jọba ní ipò rẹ̀.