Àwọn Ọba Kejì 18:1-37

  • Hẹsikáyà di ọba Júdà (1-8)

  • Bí wọ́n ṣe ṣẹ́gun Ísírẹ́lì (9-12)

  • Senakérúbù wá gbéjà ko Júdà (13-18)

  • Rábúṣákè pẹ̀gàn Jèhófà (19-37)

18  Ní ọdún kẹta Hóṣéà+ ọmọ Élà ọba Ísírẹ́lì, Hẹsikáyà+ ọmọ Áhásì+ ọba Júdà di ọba.  Ẹni ọdún mẹ́ẹ̀ẹ́dọ́gbọ̀n (25) ni nígbà tó jọba, ọdún mọ́kàndínlọ́gbọ̀n (29) ló sì fi ṣàkóso ní Jerúsálẹ́mù. Orúkọ ìyá rẹ̀ ni Ábì* ọmọ Sekaráyà.+  Ó ń ṣe ohun tí ó tọ́ ní ojú Jèhófà+ bí Dáfídì baba ńlá rẹ̀ ti ṣe.+  Òun ló mú àwọn ibi gíga kúrò,+ tó fọ́ àwọn ọwọ̀n òrìṣà sí wẹ́wẹ́, tó sì gé òpó òrìṣà*+ lulẹ̀. Ó tún fọ́ ejò bàbà tí Mósè ṣe;+ torí pé títí di àkókò yẹn ni àwọn ọmọ Ísírẹ́lì ń mú ẹbọ rú èéfín sí i, tí wọ́n sì ń pè é ní òrìṣà ejò bàbà.*  Ó gbẹ́kẹ̀ lé Jèhófà+ Ọlọ́run Ísírẹ́lì; kò sí ẹnì kankan tó dà bíi rẹ̀ nínú gbogbo àwọn ọba Júdà tó wà ṣáájú rẹ̀ àti àwọn tí wọ́n jẹ lẹ́yìn rẹ̀.  Kò fi Jèhófà sílẹ̀.+ Kò yà kúrò lẹ́yìn rẹ̀; ó ń pa àwọn àṣẹ tí Jèhófà fún Mósè mọ́.  Jèhófà sì wà pẹ̀lú rẹ̀. Ó ń hùwà ọgbọ́n níbikíbi tó bá lọ. Ó ṣọ̀tẹ̀ sí ọba Ásíríà, ó sì kọ̀ láti sìn ín.+  Ó tún ṣẹ́gun àwọn Filísínì+ títí dé Gásà àti àwọn ìpínlẹ̀ rẹ̀, láti ilé ìṣọ́ títí dé ìlú olódi.*  Ní ọdún kẹrin Ọba Hẹsikáyà, ìyẹn ní ọdún keje Hóṣéà+ ọmọ Élà ọba Ísírẹ́lì, Ṣálímánésà ọba Ásíríà wá gbéjà ko Samáríà, ó sì bẹ̀rẹ̀ sí í dó tì í.+ 10  Wọ́n gbà á+ ní òpin ọdún mẹ́ta; ní ọdún kẹfà Hẹsikáyà, ìyẹn ní ọdún kẹsàn-án Hóṣéà ọba Ísírẹ́lì, wọ́n gba Samáríà. 11  Lẹ́yìn ìyẹn, ọba Ásíríà kó Ísírẹ́lì lọ sí ìgbèkùn+ ní Ásíríà, ó sì ní kí wọ́n máa gbé ní Hálà àti ní Hábórì níbi odò Gósánì àti ní àwọn ìlú àwọn ará Mídíà.+ 12  Ohun tó fa èyí ni pé wọn kò fetí sí ohùn Jèhófà Ọlọ́run wọn, wọ́n ń da májẹ̀mú rẹ̀, ìyẹn gbogbo ohun tí Mósè ìránṣẹ́ Jèhófà pa láṣẹ.+ Wọn ò fetí sílẹ̀, wọn ò sì ṣègbọràn. 13  Ní ọdún kẹrìnlá Ọba Hẹsikáyà, Senakérúbù ọba Ásíríà+ wá gbéjà ko gbogbo ìlú olódi Júdà, ó sì gbà wọ́n.+ 14  Nítorí náà, Hẹsikáyà ọba Júdà ránṣẹ́ sí ọba Ásíríà ní Lákíṣì pé: “Èmi ni mo jẹ̀bi. Má ṣe bá mi jà mọ́, ohunkóhun tí o bá ní kí n san ni màá san.” Ni ọba Ásíríà bá bu ọgọ́rùn-ún mẹ́ta (300) tálẹ́ńtì* fàdákà àti ọgbọ̀n (30) tálẹ́ńtì wúrà lé Hẹsikáyà ọba Júdà. 15  Torí náà, Hẹsikáyà fi gbogbo fàdákà tí wọ́n rí ní ilé Jèhófà àti ní àwọn ibi ìṣúra ilé* ọba+ lélẹ̀. 16  Lákòókò yẹn, Hẹsikáyà yọ* àwọn ilẹ̀kùn tẹ́ńpìlì+ Jèhófà kúrò àti àwọn òpó ilẹ̀kùn tí Hẹsikáyà ọba Júdà fúnra rẹ̀ fi wúrà bò,+ ó sì kó wọn fún ọba Ásíríà. 17  Ọba Ásíríà wá rán àwọn mẹ́ta tí orúkọ oyè wọn ń jẹ́ Tátánì* àti Rábúsárísì* àti Rábúṣákè* pẹ̀lú ọ̀pọ̀lọpọ̀ ọmọ ogun láti Lákíṣì+ sí Ọba Hẹsikáyà ní Jerúsálẹ́mù.+ Wọ́n lọ sí Jerúsálẹ́mù, wọ́n sì dúró síbi tí adágún omi tó wà lápá òkè ń gbà, èyí tó wà lójú ọ̀nà tó lọ sí pápá alágbàfọ̀.+ 18  Nígbà tí wọ́n pe ọba pé kó jáde, Élíákímù+ ọmọ Hilikáyà, ẹni tó ń bójú tó agbo ilé* àti Ṣẹ́bínà+ akọ̀wé pẹ̀lú Jóà ọmọ Ásáfù akọ̀wé ìrántí jáde wá bá wọn. 19  Torí náà, Rábúṣákè sọ fún wọn pé: “Ẹ jọ̀ọ́, ẹ sọ fún Hẹsikáyà pé, ‘Ohun tí ọba ńlá, ọba Ásíríà sọ nìyí: “Kí lo gbọ́kàn lé?+ 20  Ò ń sọ pé, ‘Mo ní ọgbọ́n àti agbára láti jagun,’ àmọ́ ọ̀rọ̀ ẹnu lásán nìyẹn. Ta lo gbẹ́kẹ̀ lé, tí o fi gbójúgbóyà ṣọ̀tẹ̀ sí mi?+ 21  Wò ó! Ṣé Íjíbítì+ tó dà bí esùsú* fífọ́ yìí lo gbẹ́kẹ̀ lé, tó jẹ́ pé bí èèyàn bá fara tì í, ṣe ló máa wọ àtẹ́lẹwọ́ rẹ̀, tí á sì gún un yọ? Bí Fáráò ọba Íjíbítì ṣe rí nìyẹn sí gbogbo àwọn tó gbẹ́kẹ̀ lé e. 22  Tí ẹ bá sì sọ fún mi pé, ‘Jèhófà Ọlọ́run wa ni a gbẹ́kẹ̀ lé,’+ ṣé òun kọ́ ni Hẹsikáyà mú àwọn ibi gíga rẹ̀ àti àwọn pẹpẹ rẹ̀ kúrò,+ tó sì sọ fún Júdà àti Jerúsálẹ́mù pé, ‘Iwájú pẹpẹ tó wà ní Jerúsálẹ́mù yìí ni kí ẹ ti máa forí balẹ̀’?”’+ 23  Ní báyìí, ẹ wò ó, olúwa mi ọba Ásíríà pè yín níjà: Ẹ jẹ́ kí n fún yín ní ẹgbẹ̀rún méjì (2,000) ẹṣin, ká wá wò ó bóyá ẹ máa lè rí àwọn agẹṣin tó máa gùn wọ́n.+ 24  Báwo wá ni ẹ ṣe lè borí gómìnà kan ṣoṣo tó kéré jù lára àwọn ìránṣẹ́ olúwa mi, nígbà tó jẹ́ pé Íjíbítì lẹ gbẹ́kẹ̀ lé pé ó máa fún yín ní àwọn kẹ̀kẹ́ ẹṣin àti àwọn agẹṣin? 25  Ṣé láìgba àṣẹ lọ́wọ́ Jèhófà ni mo wá gbéjà ko ibí yìí láti pa á run ni? Jèhófà fúnra rẹ̀ sọ fún mi pé, ‘Lọ gbéjà ko ilẹ̀ yìí, kí o sì pa á run.’” 26  Ni Élíákímù ọmọ Hilikáyà àti Ṣẹ́bínà+ pẹ̀lú Jóà bá sọ fún Rábúṣákè+ pé: “Jọ̀ọ́, bá àwa ìránṣẹ́ rẹ sọ̀rọ̀ ní èdè Árámáíkì*+ torí a gbọ́ èdè náà; má fi èdè àwọn Júù bá wa sọ̀rọ̀ lójú àwọn èèyàn tó wà lórí ògiri.”+ 27  Ṣùgbọ́n Rábúṣákè sọ fún wọn pé: “Ṣé ẹ̀yin àti olúwa yín nìkan ni olúwa mi ní kí n sọ ọ̀rọ̀ yìí fún ni? Ṣé kò tún rán mi sí àwọn ọkùnrin tó ń jókòó lórí ògiri, àwọn tó máa jẹ ìgbẹ́ ara wọn, tí wọ́n sì máa mu ìtọ̀ ara wọn pẹ̀lú yín?” 28  Rábúṣákè bá dìde, ó gbé ohùn rẹ̀ sókè, ó sì fi èdè àwọn Júù sọ̀rọ̀, ó ní: “Ẹ gbọ́ ọ̀rọ̀ ọba ńlá, ọba Ásíríà.+ 29  Ohun tí ọba sọ nìyí, ‘Ẹ má ṣe jẹ́ kí Hẹsikáyà tàn yín jẹ, nítorí kò lè gbà yín kúrò lọ́wọ́ mi.+ 30  Ẹ má sì jẹ́ kí Hẹsikáyà mú kí ẹ gbẹ́kẹ̀ lé Jèhófà, bó ṣe ń sọ pé: “Ó dájú pé Jèhófà máa gbà wá, a ò sì ní fi ìlú yìí lé ọba Ásíríà lọ́wọ́.”+ 31  Ẹ má fetí sí Hẹsikáyà, torí ohun tí ọba Ásíríà sọ nìyí: “Ẹ bá mi ṣe àdéhùn àlàáfíà, kí ẹ sì túúbá,* kálukú yín á máa jẹ látinú àjàrà rẹ̀ àti igi ọ̀pọ̀tọ́ rẹ̀, á sì máa mu omi látinú kòtò omi rẹ̀, 32  títí màá fi wá kó yín lọ sí ilẹ̀ tó dà bí ilẹ̀ yín,+ ilẹ̀ ọkà àti ti wáìnì tuntun, ilẹ̀ oúnjẹ àti ti àwọn ọgbà àjàrà, ilẹ̀ àwọn igi ólífì àti ti oyin. Kí ẹ lè máa wà láàyè nìṣó, kí ẹ má sì kú. Ẹ má fetí sí Hẹsikáyà, nítorí ṣe ló ń ṣì yín lọ́nà bó ṣe ń sọ pé, ‘Jèhófà máa gbà wá.’ 33  Ǹjẹ́ ìkankan lára ọlọ́run àwọn orílẹ̀-èdè ti gba ilẹ̀ wọn kúrò lọ́wọ́ ọba Ásíríà? 34  Ibo ni àwọn ọlọ́run Hámátì+ àti ti Áápádì wà? Ibo ni àwọn ọlọ́run Séfáfáímù,+ Hénà àti ti Ífà wà? Ǹjẹ́ wọ́n gba Samáríà kúrò lọ́wọ́ mi?+ 35  Èwo nínú gbogbo ọlọ́run àwọn ilẹ̀ náà ló ti gba ilẹ̀ wọn kúrò lọ́wọ́ mi, tí Jèhófà yóò fi gba Jerúsálẹ́mù kúrò lọ́wọ́ mi?”’”+ 36  Àmọ́ àwọn èèyàn náà dákẹ́, wọn ò fún un lésì kankan, nítorí àṣẹ ọba ni pé, “Ẹ ò gbọ́dọ̀ dá a lóhùn.”+ 37  Ṣùgbọ́n Élíákímù ọmọ Hilikáyà, ẹni tó ń bójú tó agbo ilé* àti Ṣẹ́bínà akọ̀wé pẹ̀lú Jóà ọmọ Ásáfù akọ̀wé ìrántí wá sọ́dọ̀ Hẹsikáyà, pẹ̀lú ẹ̀wù yíya lọ́rùn wọn, wọ́n sì sọ àwọn ọ̀rọ̀ Rábúṣákè fún un.

Àlàyé Ìsàlẹ̀ Ìwé

Ìkékúrú orúkọ Ábíjà.
Tàbí “Néhúṣítánì.”
Ìyẹn, ní ibi gbogbo, ì báà jẹ́ ibi tí èèyàn kéréje ń gbé tàbí ọ̀pọ̀ èèyàn.
Tálẹ́ńtì kan jẹ́ kìlógíráàmù 34.2. Wo Àfikún B14.
Tàbí “ààfin.”
Ní Héb., “gé.”
Tàbí “olórí agbọ́tí.”
Tàbí “olórí àwọn òṣìṣẹ́ láàfin.”
Tàbí “olórí ọmọ ogun.”
Tàbí “ààfin.”
Ìyẹn, koríko etí omi.
Tàbí “Síríà.”
Ní Héb., “Ẹ wá ìbùkún lọ́dọ̀ mi, kí ẹ sì jáde wá bá mi.”
Tàbí “ààfin.”