Àwọn Ọba Kejì 2:1-25

  • Ọlọ́run fi ìjì gbé Èlíjà lọ sókè (1-18)

    • Èlíṣà rí ẹ̀wù Èlíjà gbà (13, 14)

  • Èlíṣà wo omi Jẹ́ríkò sàn (19-22)

  • Àwọn bíárì pa àwọn ọmọdékùnrin tó jáde wá láti Bẹ́tẹ́lì (23-25)

2  Nígbà tó kù díẹ̀ tí Jèhófà máa fi ìjì+ gbé Èlíjà+ lọ sí ọ̀run,* Èlíjà àti Èlíṣà+ jáde kúrò ní Gílígálì.+  Èlíjà sọ fún Èlíṣà pé: “Jọ̀ọ́, dúró sí ibí yìí, nítorí pé Jèhófà ti rán mi lọ sí Bẹ́tẹ́lì.” Àmọ́ Èlíṣà sọ pé: “Bí Jèhófà ti wà láàyè, tí ìwọ náà* sì wà láàyè, mi ò ní fi ọ́ sílẹ̀.” Nítorí náà, wọ́n lọ sí Bẹ́tẹ́lì.+  Ìgbà náà ni àwọn ọmọ wòlíì* ní Bẹ́tẹ́lì jáde wá bá Èlíṣà, wọ́n sì sọ fún un pé: “Ṣé o mọ̀ pé òní ni Jèhófà máa mú ọ̀gá rẹ lọ, tí kò sì ní ṣe olórí rẹ mọ́?”+ Ó dá wọn lóhùn pé: “Mo mọ̀. Ẹ dákẹ́.”  Èlíjà wá sọ fún un pé: “Èlíṣà, jọ̀ọ́ dúró sí ibí yìí, nítorí pé, Jèhófà ti rán mi lọ sí Jẹ́ríkò.”+ Àmọ́ ó sọ pé: “Bí Jèhófà ti wà láàyè, tí ìwọ náà* sì wà láàyè, mi ò ní fi ọ́ sílẹ̀.” Nítorí náà, wọ́n lọ sí Jẹ́ríkò.  Àwọn ọmọ wòlíì tó wà ní Jẹ́ríkò wá bá Èlíṣà, wọ́n sì sọ fún un pé: “Ṣé o mọ̀ pé òní ni Jèhófà máa mú ọ̀gá rẹ lọ, tí kò sì ní ṣe olórí rẹ mọ́?” Ó dá wọn lóhùn pé: “Mo mọ̀. Ẹ dákẹ́.”  Èlíjà wá sọ fún un pé: “Jọ̀ọ́, dúró sí ibí yìí, nítorí pé Jèhófà ti rán mi lọ sí Jọ́dánì.” Àmọ́ ó sọ pé: “Bí Jèhófà ti wà láàyè, tí ìwọ náà* sì wà láàyè, mi ò ní fi ọ́ sílẹ̀.” Nítorí náà, àwọn méjèèjì jọ ń lọ.  Bákan náà, àádọ́ta (50) lára àwọn ọmọ wòlíì jáde lọ, wọ́n dúró lọ́ọ̀ọ́kán, wọ́n sì ń wo àwọn méjèèjì bí wọ́n ṣe dúró lẹ́gbẹ̀ẹ́ Jọ́dánì.  Nígbà náà, Èlíjà mú ẹ̀wù oyè rẹ̀,+ ó ká a, ó sì lu omi náà, ó pín sápá ọ̀tún àti sápá òsì, tó fi jẹ́ pé àwọn méjèèjì gba orí ilẹ̀ gbígbẹ sọdá.+  Gẹ́rẹ́ lẹ́yìn tí wọ́n sọdá, Èlíjà sọ fún Èlíṣà pé: “Béèrè ohun tí o bá fẹ́ kí n ṣe fún ọ kí Ọlọ́run tó mú mi kúrò lọ́dọ̀ rẹ.” Torí náà, Èlíṣà sọ pé: “Jọ̀ọ́, fún mi ní ìpín*+ méjì nínú ẹ̀mí rẹ.”+ 10  Ó fèsì pé: “Ohun tí o béèrè yìí kò rọrùn. Tí o bá rí mi nígbà tí Ọlọ́run bá mú mi kúrò lọ́dọ̀ rẹ, á rí bẹ́ẹ̀ fún ọ; àmọ́ tí o ò bá rí mi, kò ní rí bẹ́ẹ̀.” 11  Bí wọ́n ṣe ń rìn lọ, wọ́n ń sọ̀rọ̀, lójijì kẹ̀kẹ́ ẹṣin oníná àti àwọn ẹṣin oníná+ ya àwọn méjèèjì sọ́tọ̀, ìjì sì gbé Èlíjà lọ sí ọ̀run.*+ 12  Bí Èlíṣà ṣe ń wò ó, ó ké jáde pé: “Bàbá mi, bàbá mi! Kẹ̀kẹ́ ẹṣin Ísírẹ́lì àti àwọn agẹṣin rẹ̀!”+ Nígbà tí kò rí i mọ́, ó di ẹ̀wù ara rẹ̀ mú, ó sì fà á ya sí méjì.+ 13  Lẹ́yìn náà, ó mú ẹ̀wù oyè+ Èlíjà tó já bọ́ lára rẹ̀, ó pa dà, ó sì dúró lẹ́gbẹ̀ẹ́ etí odò Jọ́dánì. 14  Ló bá mú ẹ̀wù oyè Èlíjà tó já bọ́ lára rẹ̀, ó fi lu omi náà, ó sì sọ pé: “Jèhófà Ọlọ́run Èlíjà dà?” Nígbà tó lu omi náà, ó pín sí apá ọ̀tún àti sí apá òsì, tí Èlíṣà fi lè sọdá.+ 15  Nígbà tí àwọn ọmọ wòlíì tó wà ní Jẹ́ríkò rí i lókèèrè, wọ́n sọ pé: “Ẹ̀mí Èlíjà ti bà lé Èlíṣà.”+ Torí náà, wọ́n wá pàdé rẹ̀, wọ́n sì tẹrí ba mọ́lẹ̀ níwájú rẹ̀. 16  Wọ́n sọ fún un pé: “Àádọ́ta (50) géńdé ọkùnrin wà níbí pẹ̀lú àwọn ìránṣẹ́ rẹ. Jọ̀ọ́, jẹ́ kí wọ́n lọ wá ọ̀gá rẹ. Ó lè jẹ́ pé, nígbà tí ẹ̀mí* Jèhófà gbé e, orí ọ̀kan nínú àwọn òkè tàbí àwọn àfonífojì ni ó jù ú sí.”+ Àmọ́ ó sọ pé: “Ẹ má ṣe rán wọn.” 17  Síbẹ̀, wọ́n ń rọ̀ ọ́ ṣáá títí ó fi sú u, torí náà ó ní: “Ẹ rán wọn lọ.” Wọ́n wá rán àádọ́ta (50) ọkùnrin, ọjọ́ mẹ́ta ni wọ́n sì fi wá a, ṣùgbọ́n wọn ò rí i. 18  Nígbà tí wọ́n pa dà sọ́dọ̀ rẹ̀, ó ṣì wà ní Jẹ́ríkò.+ Ó wá sọ fún wọn pé: “Ṣé mi ò sọ fún yín pé kí ẹ má lọ?” 19  Nígbà tó yá, àwọn ọkùnrin ìlú náà sọ fún Èlíṣà pé: “Ọ̀gá wa, bí ìwọ náà ṣe mọ̀, ibi tí ìlú yìí wà dáa;+ àmọ́ omi rẹ̀ kò dáa, ilẹ̀ rẹ̀ sì ti ṣá.”* 20  Ló bá sọ pé: “Ẹ mú abọ́ kékeré tuntun kan wá, kí ẹ sì bu iyọ̀ sínú rẹ̀.” Nítorí náà, wọ́n gbé e wá fún un. 21  Ó wá lọ sí orísun omi náà, ó da iyọ̀ sínú rẹ̀,+ ó sì sọ pé: “Ohun tí Jèhófà sọ nìyí, ‘Mo ti wo omi yìí sàn. Kò ní fa ikú, kò sì ní sọni di àgàn* mọ́.’” 22  Ìwòsàn sì bá omi náà títí di òní yìí, gẹ́gẹ́ bí ọ̀rọ̀ tí Èlíṣà sọ. 23  Ó gòkè láti ibẹ̀ lọ sí Bẹ́tẹ́lì. Bó ṣe ń lọ lójú ọ̀nà, àwọn ọmọkùnrin kan jáde wá láti inú ìlú náà, wọ́n sì bẹ̀rẹ̀ sí í fi ṣe yẹ̀yẹ́,+ wọ́n ń sọ fún un pé: “Gòkè lọ, apárí! Gòkè lọ, apárí!” 24  Níkẹyìn, ó bojú wẹ̀yìn, ó wò wọ́n, ó sì gégùn-ún fún wọn ní orúkọ Jèhófà. Ni abo bíárì+ méjì bá jáde láti inú igbó, wọ́n sì fa méjìlélógójì (42) lára àwọn ọmọ náà ya pẹ́rẹpẹ̀rẹ.+ 25  Ó kúrò níbẹ̀ lọ sí Òkè Kámẹ́lì,+ láti ibẹ̀, ó pa dà sí Samáríà.

Àlàyé Ìsàlẹ̀ Ìwé

Tàbí “sánmà.”
Tàbí “ọkàn rẹ.”
“Àwọn ọmọ wòlíì” ṣeé ṣe kó máa tọ́ka sí ilé ẹ̀kọ́ tí àwọn wòlíì ti ń gba ìtọ́ni tàbí ẹgbẹ́ àwọn wòlíì.
Tàbí “ọkàn rẹ.”
Tàbí “ọkàn rẹ.”
Tàbí “apá.”
Tàbí “sánmà.”
Tàbí “ìjì.”
Tàbí kó jẹ́, “ń ba oyún jẹ́.”
Tàbí kó jẹ́, “kò sì ní ba oyún jẹ́.”