Àwọn Ọba Kejì 20:1-21

  • Àìsàn Hẹsikáyà àti bí ara rẹ̀ ṣe yá (1-11)

  • Àwọn òjíṣẹ́ láti Bábílónì (12-19)

  • Ikú Hẹsikáyà (20, 21)

20  Ní àkókò náà, Hẹsikáyà ṣàìsàn dé ojú ikú.+ Wòlíì Àìsáyà ọmọ Émọ́ọ̀sì wá bá a, ó sì sọ fún un pé, “Ohun tí Jèhófà sọ nìyí: ‘Sọ ohun tí agbo ilé rẹ máa ṣe fún wọn, torí pé o máa kú; o ò ní yè é.’”+  Ni ó bá yíjú sí ògiri, ó sì bẹ̀rẹ̀ sí í gbàdúrà sí Jèhófà, ó ní:  “Mo bẹ̀ ọ́, Jèhófà, jọ̀ọ́ rántí bí mo ṣe fi òtítọ́ àti gbogbo ọkàn mi rìn níwájú rẹ, ohun tó dáa ní ojú rẹ sì ni mo ṣe.”+ Hẹsikáyà sì bẹ̀rẹ̀ sí í sunkún pẹ̀rẹ̀pẹ̀rẹ̀.  Àìsáyà kò tíì dé àgbàlá àárín nígbà tí Jèhófà bá a sọ̀rọ̀ pé:+  “Pa dà lọ sọ fún Hẹsikáyà aṣáájú àwọn èèyàn mi pé, ‘Ohun tí Jèhófà Ọlọ́run Dáfídì baba ńlá rẹ sọ nìyí: “Mo ti gbọ́ àdúrà rẹ. Mo ti rí omijé rẹ.+ Wò ó, màá mú ọ lára dá.+ Ní ọ̀túnla, wàá lọ sí ilé Jèhófà.+  Màá fi ọdún mẹ́ẹ̀ẹ́dógún (15) kún ọjọ́ ayé* rẹ, màá gba ìwọ àti ìlú yìí lọ́wọ́ ọba Ásíríà,+ màá sì gbèjà ìlú yìí nítorí orúkọ mi àti nítorí Dáfídì ìránṣẹ́ mi.”’”+  Àìsáyà wá sọ pé: “Ẹ mú ìṣù ọ̀pọ̀tọ́ gbígbẹ wá.” Nítorí náà, wọ́n mú un wá, wọ́n sì fi í sí eéwo náà, ní kẹ̀rẹ̀kẹ̀rẹ̀, ara rẹ̀ yá.+  Hẹsikáyà ti béèrè lọ́wọ́ Àìsáyà pé: “Àmì+ wo ló máa jẹ́ kó dá mi lójú pé Jèhófà máa mú mi lára dá àti pé màá lè lọ sí ilé Jèhófà ní ọjọ́ kẹta?”  Àìsáyà fèsì pé: “Àmì tí Jèhófà fún ọ nìyí láti mú un dá ọ lọ́jú pé Jèhófà máa mú ọ̀rọ̀ tó sọ ṣẹ: Ṣé o fẹ́ kí òjìji tó wà lórí àtẹ̀gùn* lọ síwájú ní ìgbésẹ̀ mẹ́wàá tàbí kó pa dà sẹ́yìn ní ìgbésẹ̀ mẹ́wàá?”+ 10  Hẹsikáyà sọ pé: “Ó rọrùn fún òjìji láti lọ síwájú ní ìgbésẹ̀ mẹ́wàá, àmọ́ kì í ṣe bíi pé kò pa dà sẹ́yìn ní ìgbésẹ̀ mẹ́wàá.” 11  Torí náà, wòlíì Àìsáyà ké pe Jèhófà, Ó sì mú kí òjìji tó wà lórí àtẹ̀gùn Áhásì pa dà sẹ́yìn ní ìgbésẹ̀ mẹ́wàá lẹ́yìn tó ti kọ́kọ́ lọ síwájú lórí àtẹ̀gùn náà.+ 12  Ní àkókò yẹn, ọba Bábílónì, ìyẹn Berodaki-báládánì ọmọ Báládánì fi àwọn lẹ́tà àti ẹ̀bùn ránṣẹ́ sí Hẹsikáyà, torí ó gbọ́ pé Hẹsikáyà ṣàìsàn.+ 13  Hẹsikáyà kí wọn káàbọ̀,* ó sì fi gbogbo ohun tó wà nínú ilé ìṣúra+ rẹ̀ hàn wọ́n, ìyẹn fàdákà, wúrà, òróró básámù àti àwọn òróró míì tó ṣeyebíye pẹ̀lú ilé tó ń kó ohun ìjà sí àti gbogbo ohun tó wà nínú àwọn ibi ìṣúra rẹ̀. Kò sí nǹkan tí Hẹsikáyà kò fi hàn wọ́n nínú ilé* rẹ̀ àti nínú gbogbo agbègbè tó wà lábẹ́ àkóso rẹ̀. 14  Lẹ́yìn náà, wòlíì Àìsáyà wá sọ́dọ̀ Ọba Hẹsikáyà, ó sì béèrè lọ́wọ́ rẹ̀ pé: “Kí ni àwọn ọkùnrin yìí sọ, ibo ni wọ́n sì ti wá?” Torí náà, Hẹsikáyà sọ pé: “Ilẹ̀ tó jìnnà ni wọ́n ti wá, láti Bábílónì.”+ 15  Ó tún béèrè pé: “Kí ni wọ́n rí nínú ilé* rẹ?” Hẹsikáyà fèsì pé: “Gbogbo ohun tó wà nínú ilé* mi ni wọ́n rí. Kò sí nǹkan kan tó wà nínú àwọn ibi ìṣúra mi tí mi ò fi hàn wọ́n.” 16  Àìsáyà wá sọ fún Hẹsikáyà pé: “Gbọ́ ọ̀rọ̀ Jèhófà,+ 17  ‘Wò ó! Ọjọ́ ń bọ̀ tí wọ́n máa kó gbogbo ohun tó wà nínú ilé* rẹ àti gbogbo ohun tí àwọn baba ńlá rẹ ti kó jọ títí di òní yìí lọ sí Bábílónì.+ Kò ní ku nǹkan kan,’ ni Jèhófà wí. 18  ‘Wọ́n á mú àwọn kan lára àwọn ọmọ tí o máa bí,+ wọ́n á sì di òṣìṣẹ́ ààfin ní ààfin ọba Bábílónì.’”+ 19  Ni Hẹsikáyà bá sọ fún Àìsáyà pé: “Ọ̀rọ̀ Jèhófà tí o sọ dára.”+ Ó wá fi kún un pé: “Tí àlàáfíà àti ìfọkànbalẹ̀* bá ti wà lásìkò* mi,+ ó ti dáa.” 20  Ní ti ìyókù ìtàn Hẹsikáyà àti gbogbo agbára rẹ̀ àti bí ó ṣe ṣe adágún odò+ àti ọ̀nà omi àti bí ó ṣe gbé omi wá sínú ìlú,+ ǹjẹ́ kò wà lákọsílẹ̀ nínú ìwé ìtàn ìgbà àwọn ọba Júdà? 21  Níkẹyìn, Hẹsikáyà sinmi pẹ̀lú àwọn baba ńlá rẹ̀;+ Mánásè+ ọmọ rẹ̀ sì jọba ní ipò rẹ̀.+

Àlàyé Ìsàlẹ̀ Ìwé

Ní Héb., “àwọn ọjọ́.”
Ó ṣeé ṣe kó jẹ́ pé àwọn àtẹ̀gùn yìí ni wọ́n fi ń ka àkókò bíi ti aago òjìji oòrùn.
Tàbí “ààfin.”
Tàbí “fetí sí wọn.”
Tàbí “ààfin.”
Tàbí “ààfin.”
Tàbí “ààfin.”
Ní Héb., “ní àwọn ọjọ́.”
Tàbí “òtítọ́.”