Àwọn Ọba Kejì 22:1-20

  • Jòsáyà di ọba Júdà (1, 2)

  • Bí wọ́n ṣe máa tún tẹ́ńpìlì ṣe (3-7)

  • Wọ́n rí ìwé Òfin (8-13)

  • Húlídà sọ tẹ́lẹ̀ pé àjálù máa ṣẹlẹ̀ (14-20)

22  Ọmọ ọdún mẹ́jọ ni Jòsáyà+ nígbà tó jọba, ọdún mọ́kànlélọ́gbọ̀n (31) ló sì fi ṣàkóso ní Jerúsálẹ́mù.+ Orúkọ ìyá rẹ̀ ni Jédídà ọmọ Ádáyà láti Bósíkátì.+  Ó ṣe ohun tí ó tọ́ ní ojú Jèhófà, ó rìn ní gbogbo ọ̀nà Dáfídì baba ńlá rẹ̀,+ kò sì yà sí ọ̀tún tàbí sí òsì.  Ní ọdún kejìdínlógún Ọba Jòsáyà, ọba rán Ṣáfánì akọ̀wé tó jẹ́ ọmọ Asaláyà ọmọ Méṣúlámù sí ilé Jèhófà,+ ó ní:  “Lọ bá Hilikáyà+ àlùfáà àgbà, ní kó gba gbogbo owó tí wọ́n mú wá sí ilé Jèhófà+ jọ, èyí tí àwọn aṣọ́nà gbà lọ́wọ́ àwọn èèyàn náà.+  Ní kí wọ́n kó o fún àwọn tí wọ́n yàn láti máa bójú tó iṣẹ́ ilé Jèhófà, àwọn yìí ló máa fún àwọn tó ń ṣiṣẹ́ nínú ilé Jèhófà láti tún àwọn ibi tó bà jẹ́* lára ilé náà ṣe,+  ìyẹn àwọn oníṣẹ́ ọnà àti àwọn kọ́lékọ́lé àti àwọn mọlémọlé; owó yìí ni kí wọ́n fi ra àwọn ẹ̀là gẹdú àti àwọn òkúta gbígbẹ́ tí wọ́n á fi tún ilé náà ṣe.+  Àmọ́, a ò ní sọ pé kí wọ́n ṣe ìṣírò owó tí wọ́n fún wọn, torí pé wọ́n ṣeé fọkàn tán.”+  Lẹ́yìn náà, Hilikáyà àlùfáà àgbà sọ fún Ṣáfánì akọ̀wé+ pé: “Mo ti rí ìwé Òfin+ ní ilé Jèhófà.” Torí náà, Hilikáyà fún Ṣáfánì ní ìwé náà, ó sì bẹ̀rẹ̀ sí í kà á.+  Lẹ́yìn náà, Ṣáfánì akọ̀wé lọ sọ́dọ̀ ọba, ó sì sọ fún un pé: “Àwọn ìránṣẹ́ rẹ ti kó owó tí wọ́n rí nínú ilé náà,* wọ́n sì ti kó o fún àwọn tí wọ́n yàn láti máa bójú tó iṣẹ́ ilé Jèhófà.”+ 10  Ṣáfánì akọ̀wé tún sọ fún ọba pé: “Ìwé kan+ wà tí àlùfáà Hilikáyà fún mi.” Ṣáfánì sì bẹ̀rẹ̀ sí í kà á níwájú ọba. 11  Gbàrà tí ọba gbọ́ àwọn ọ̀rọ̀ inú ìwé Òfin náà, ó fa aṣọ rẹ̀ ya.+ 12  Ọba wá pa àṣẹ yìí fún àlùfáà Hilikáyà, Áhíkámù+ ọmọ Ṣáfánì, Ákíbórì ọmọ Mikáyà, Ṣáfánì akọ̀wé àti Ásáyà ìránṣẹ́ ọba pé: 13  “Ẹ lọ wádìí lọ́dọ̀ Jèhófà nítorí tèmi àti nítorí àwọn èèyàn yìí àti nítorí gbogbo Júdà nípa àwọn ọ̀rọ̀ inú ìwé tí a rí yìí; torí ìbínú Jèhófà tó ń jó bí iná lórí wa kò kéré,+ nítorí àwọn baba ńlá wa kò tẹ̀ lé àwọn ọ̀rọ̀ inú ìwé yìí láti ṣe gbogbo ohun tó wà lákọsílẹ̀ fún wa.” 14  Torí náà, àlùfáà Hilikáyà, Áhíkámù, Ákíbórì, Ṣáfánì àti Ásáyà lọ sọ́dọ̀ wòlíì obìnrin+ tó ń jẹ́ Húlídà. Òun ni ìyàwó Ṣálúmù ọmọ Tíkífà ọmọ Háhásì, ẹni tó ń bójú tó ibi tí wọ́n ń kó aṣọ sí. Ó ń gbé ní Apá Kejì Jerúsálẹ́mù; wọ́n sì bá a sọ̀rọ̀ níbẹ̀.+ 15  Ó sọ fún wọn pé: “Ohun tí Jèhófà Ọlọ́run Ísírẹ́lì sọ nìyí, ‘Ẹ sọ fún ọkùnrin tó rán yín wá sọ́dọ̀ mi pé: 16  “Ohun tí Jèhófà sọ nìyí, ‘Màá mú àjálù bá ibí yìí àti àwọn tó ń gbé ibẹ̀, gbogbo ohun tó wà nínú ìwé tí ọba Júdà kà ni màá ṣe.+ 17  Nítorí pé wọ́n ti fi mí sílẹ̀, wọ́n sì ń mú ẹbọ rú èéfín sí àwọn ọlọ́run míì+ láti fi gbogbo iṣẹ́ ọwọ́ wọn mú mi bínú,+ ìbínú mi máa bẹ̀rẹ̀ sí í jó bí iná lórí ibí yìí, kò sì ní ṣeé pa.’”+ 18  Àmọ́, ní ti ọba Júdà tó rán yín pé kí ẹ lọ wádìí lọ́dọ̀ Jèhófà, ẹ sọ fún un pé, “Ohun tí Jèhófà Ọlọ́run Ísírẹ́lì sọ nìyí: ‘Ní ti àwọn ọ̀rọ̀ tí o gbọ́, 19  nítorí pé ọlọ́kàn tútù ni ọ́* tí o sì rẹ ara rẹ sílẹ̀+ níwájú Jèhófà bí o ṣe gbọ́ ohun tí mo sọ pé màá ṣe sí ibí yìí àti sí àwọn tó ń gbé ibẹ̀, pé wọ́n á di ohun àríbẹ̀rù àti ẹni ègún, tí o sì fa aṣọ rẹ ya,+ tí ò ń sunkún níwájú mi, èmi náà ti gbọ́ ohun tí o sọ, ni Jèhófà wí. 20  Ìdí nìyẹn tí màá fi kó ọ jọ sọ́dọ̀ àwọn baba ńlá rẹ,* a ó tẹ́ ọ sínú sàréè rẹ ní àlàáfíà, ojú rẹ ò ní rí gbogbo àjálù tí màá mú bá ibí yìí.’”’” Lẹ́yìn náà, wọ́n mú èsì náà wá fún ọba.

Àlàyé Ìsàlẹ̀ Ìwé

Tàbí “tó sán.”
Ní Héb., “da owó tí wọ́n rí nínú ilé náà jáde.”
Ní Héb., “ọkàn rẹ rọ̀.”
Àkànlò èdè yìí ni wọ́n fi ń sọ pé èèyàn kú.