Àwọn Ọba Kejì 9:1-37
9 Lẹ́yìn náà, wòlíì Èlíṣà pe ọ̀kan lára àwọn ọmọ wòlíì, ó sì sọ fún un pé: “Ká aṣọ rẹ mọ́ra, kí o sì yára mú ṣágo* òróró yìí lọ sí Ramoti-gílíádì.+
2 Tí o bá ti dé ibẹ̀, kí o wá Jéhù+ ọmọ Jèhóṣáfátì ọmọ Nímúṣì; wọlé lọ bá a, kí o ní kó dìde kúrò láàárín àwọn arákùnrin rẹ̀, kí o sì mú un lọ sínú yàrá inú lọ́hùn-ún.
3 Kí o mú ṣágo òróró náà, kí o sì dà á sí i lórí, kí o wá sọ pé, ‘Ohun tí Jèhófà sọ nìyí: “Mo fòróró yàn ọ́ ṣe ọba lórí Ísírẹ́lì.”’+ Lẹ́yìn náà, ṣí ilẹ̀kùn, kí o sì tètè sá lọ.”
4 Torí náà, ìránṣẹ́ wòlíì náà bọ́ sọ́nà, ó sì forí lé Ramoti-gílíádì.
5 Nígbà tó dé ibẹ̀, àwọn olórí ọmọ ogun wà ní ìjókòó. Ló bá sọ pé: “Iṣẹ́ kan wà tí wọ́n ní kí n jẹ́ fún ọ, balógun.” Jéhù béèrè pé: “Èwo nínú wa?” Ó dáhùn pé: “Balógun, ìwọ ni.”
6 Nítorí náà, Jéhù dìde, ó wọnú ilé; ìránṣẹ́ náà da òróró sí i lórí, ó sì sọ fún un pé,“Ohun tí Jèhófà Ọlọ́run Ísírẹ́lì sọ nìyí: ‘Mo fòróró yàn ọ́ ṣe ọba lórí àwọn èèyàn Jèhófà, lórí Ísírẹ́lì.+
7 Kí o pa àwọn ará ilé Áhábù olúwa rẹ, màá sì gbẹ̀san ẹ̀jẹ̀ àwọn ìránṣẹ́ mi wòlíì àti ti gbogbo ìránṣẹ́ Jèhófà tí Jésíbẹ́lì pa.+
8 Gbogbo ilé Áhábù ló máa ṣègbé; màá sì pa gbogbo ọkùnrin* ilé Áhábù run, títí kan àwọn aláìní àti àwọn aláìníláárí ní Ísírẹ́lì.+
9 Màá ṣe ilé Áhábù bí ilé Jèróbóámù+ ọmọ Nébátì àti bí ilé Bááṣà+ ọmọ Áhíjà.
10 Ní ti Jésíbẹ́lì, àwọn ajá ló máa jẹ ẹ́ ní ilẹ̀ tó wà ní Jésírẹ́lì,+ ẹnì kankan ò ní sin ín.’” Ló bá ṣí ilẹ̀kùn, ó sì sá lọ.+
11 Nígbà tí Jéhù pa dà sọ́dọ̀ àwọn ìránṣẹ́ olúwa rẹ̀, wọ́n béèrè lọ́wọ́ rẹ̀ pé: “Ṣé kò sí o? Kí nìdí tí ayírí yìí fi wá bá ọ?” Ó dá wọn lóhùn pé: “Ẹ̀yin náà mọ irú èèyàn tí ọkùnrin náà jẹ́, ẹ sì mọ ohun tí irú wọn máa ń sọ.”
12 Ṣùgbọ́n wọ́n sọ pé: “Irọ́ ni! Jọ̀ọ́, sòótọ́ fún wa.” Nígbà náà, ó sọ pé: “Báyìí-báyìí ló sọ fún mi, ó sì fi kún un pé, ‘Ohun tí Jèhófà sọ nìyí: “Mo fòróró yàn ọ́ ṣe ọba lórí Ísírẹ́lì.”’”+
13 Ní kíá, kálukú mú aṣọ rẹ̀, wọ́n sì tẹ́ ẹ sórí àtẹ̀gùn kó lè gun orí rẹ̀,+ wọ́n fun ìwo, wọ́n sì sọ pé: “Jéhù ti di ọba!”+
14 Lẹ́yìn náà, Jéhù+ ọmọ Jèhóṣáfátì ọmọ Nímúṣì dìtẹ̀ sí Jèhórámù.
Ní àkókò yẹn, Jèhórámù àti gbogbo Ísírẹ́lì wà ní Ramoti-gílíádì,+ wọn ò sì dẹra nù nítorí Hásáẹ́lì+ ọba Síríà.
15 Nígbà tó yá, ọba Jèhórámù pa dà sí Jésírẹ́lì+ kó lè tọ́jú ọgbẹ́ tí àwọn ará Síríà dá sí i lára nígbà tó bá Hásáẹ́lì ọba Síríà+ jà.
Ni Jéhù bá sọ pé: “Bí ẹ* bá gbà pẹ̀lú mi, ẹ má ṣe jẹ́ kí ẹnikẹ́ni sá kúrò ní ìlú láti lọ ròyìn ní Jésírẹ́lì.”
16 Lẹ́yìn náà, Jéhù gun kẹ̀kẹ́ ẹṣin rẹ̀, ó sì lọ sí Jésírẹ́lì, torí ibẹ̀ ni Jèhórámù dùbúlẹ̀ sí pẹ̀lú ọgbẹ́ lára, Ahasáyà ọba Júdà sì wá wo Jèhórámù níbẹ̀.
17 Bí olùṣọ́ ṣe dúró sórí ilé gogoro tó wà ní Jésírẹ́lì, ó rí ọ̀gọ̀ọ̀rọ̀ àwọn ọkùnrin Jéhù tí wọ́n ń bọ̀. Ní kíá, ó sọ pé: “Mo rí ọ̀pọ̀ èèyàn tó ń bọ̀.” Jèhórámù bá sọ pé: “Mú agẹṣinjagun kan, kí o rán an lọ pàdé wọn, kó sì béèrè pé, ‘Ṣé àlàáfíà lẹ bá wá?’”
18 Torí náà, agẹṣin kan lọ pàdé rẹ̀, ó sì sọ pé: “Ọba ní kí n bi yín pé, ‘Ṣé àlàáfíà lẹ bá wá?’” Ṣùgbọ́n Jéhù sọ pé: “Ọ̀rọ̀ ‘àlàáfíà’ wo lò ń sọ? Bọ́ sẹ́yìn mi!”
Olùṣọ́ wá ròyìn pé: “Òjíṣẹ́ náà dé ọ̀dọ̀ wọn, ṣùgbọ́n kò tíì pa dà.”
19 Nítorí náà, ó rán agẹṣin kejì jáde, nígbà tó dé ọ̀dọ̀ wọn, ó sọ pé: “Ọba ní kí n bi yín pé, ‘Ṣé àlàáfíà lẹ bá wá?’” Àmọ́ Jéhù sọ pé: “Ọ̀rọ̀ ‘àlàáfíà’ wo lò ń sọ? Bọ́ sẹ́yìn mi!”
20 Lẹ́yìn náà, olùṣọ́ ròyìn pé: “Ó dé ọ̀dọ̀ wọn, ṣùgbọ́n kò tíì pa dà, bó ṣe ń gun kẹ̀kẹ́ ẹṣin rẹ̀ sì dà bíi ti Jéhù ọmọ ọmọ* Nímúṣì, nítorí eré àsápajúdé ló máa ń sá.”
21 Jèhórámù sọ pé: “Di kẹ̀kẹ́ ẹṣin!” Nítorí náà, wọ́n di kẹ̀kẹ́ ogun rẹ̀, Jèhórámù ọba Ísírẹ́lì àti Ahasáyà+ ọba Júdà sì jáde lọ, kálukú nínú kẹ̀kẹ́ ogun rẹ̀ láti pàdé Jéhù. Wọ́n bá a pàdé ní ilẹ̀ Nábótì+ ará Jésírẹ́lì.
22 Bí Jèhórámù ṣe rí Jéhù, ó sọ pé: “Ṣé àlàáfíà lo bá wá, Jéhù?” Àmọ́, ó sọ pé: “Àlàáfíà báwo, nígbà tó jẹ́ pé Jésíbẹ́lì+ ìyá rẹ kò jáwọ́ nínú ìṣekúṣe àti ọ̀pọ̀ iṣẹ́ àjẹ́ rẹ̀?”+
23 Lójú ẹsẹ̀, Jèhórámù yíjú kẹ̀kẹ́ ẹṣin rẹ̀ pa dà kó lè sá lọ, ó sì sọ fún Ahasáyà pé: “Wọ́n ti tàn wá, Ahasáyà!”
24 Jéhù mú ọfà,* ó sì ta á lu Jèhórámù ní àárín méjì ẹ̀yìn rẹ̀, ọfà náà jáde ní ọkàn rẹ̀, ó sì ṣubú sínú kẹ̀kẹ́ ogun rẹ̀.
25 Jéhù wá sọ fún Bídíkárì tó jẹ́ olùrànlọ́wọ́ rẹ̀ lójú ogun pé: “Gbé e, kí o sì jù ú sínú ilẹ̀ Nábótì ará Jésírẹ́lì.+ Rántí pé èmi pẹ̀lú rẹ jọ ń gun ẹṣin* tẹ̀ lé Áhábù bàbá rẹ̀ nígbà tí Jèhófà fúnra rẹ̀ kéde ìdájọ́ lé e lórí pé:+
26 ‘“Bí mo ṣe rí ẹ̀jẹ̀ Nábótì+ àti ẹ̀jẹ̀ àwọn ọmọ rẹ̀ lánàá,” ni Jèhófà wí, “màá san án pa dà+ fún ọ ní ilẹ̀ yìí kan náà,” ni Jèhófà wí.’ Torí náà, gbé e, kí o sì jù ú sórí ilẹ̀ náà gẹ́gẹ́ bí ọ̀rọ̀ tí Jèhófà sọ.”+
27 Nígbà tí Ahasáyà+ ọba Júdà rí ohun tó ń ṣẹlẹ̀, ó sá gba ọ̀nà ilé ọgbà. (Lẹ́yìn náà, Jéhù lépa rẹ̀, ó sì sọ pé: “Ẹ pa òun náà!” Torí náà, wọ́n ṣe é léṣe nínú kẹ̀kẹ́ ẹṣin rẹ̀ bó ṣe ń lọ sí Gúrì tó wà lẹ́gbẹ̀ẹ́ Íbíléámù.+ Àmọ́ kò dúró títí ó fi sá dé Mẹ́gídò, ó sì kú síbẹ̀.
28 Lẹ́yìn ìyẹn, àwọn ìránṣẹ́ rẹ̀ fi kẹ̀kẹ́ ẹṣin gbé e lọ sí Jerúsálẹ́mù, wọ́n sì sin ín sí sàréè rẹ̀ pẹ̀lú àwọn baba ńlá rẹ̀ ní Ìlú Dáfídì.+
29 Ọdún kọkànlá Jèhórámù ọmọ Áhábù ni Ahasáyà + di ọba lórí Júdà.)
30 Nígbà tí Jéhù dé Jésírẹ́lì,+ Jésíbẹ́lì+ gbọ́ pé ó ti dé. Torí náà, ó lé tìróò* sójú, ó ṣe irun rẹ̀ lóge, ó sì bojú wolẹ̀ látojú fèrèsé.*
31 Bí Jéhù ṣe ń gba ẹnubodè wọlé, Jésíbẹ́lì sọ pé: “Ǹjẹ́ ó dáa fún Símírì, ẹni tó pa olúwa rẹ̀?”+
32 Bí Jéhù ṣe gbójú sókè wo fèrèsé náà, ó sọ pé: “Ta ló wà lẹ́yìn mi nínú yín? Ta ni?”+ Lẹ́sẹ̀kẹsẹ̀, àwọn méjì sí mẹ́ta tó jẹ́ òṣìṣẹ́ ààfin yọjú wò ó látòkè.
33 Ó sọ pé: “Ẹ jù ú sísàlẹ̀!” Torí náà, wọ́n jù ú sísàlẹ̀, lára ẹ̀jẹ̀ rẹ̀ sì ta sára ògiri àti sára àwọn ẹṣin, àwọn ẹṣin Jéhù sì tẹ̀ ẹ́ mọ́lẹ̀.
34 Lẹ́yìn náà, ó wọlé, ó jẹ, ó sì mu. Ó wá sọ pé: “Ẹ jọ̀ọ́, ẹ palẹ̀ obìnrin ẹni ègún yìí mọ́, kí ẹ sì sin ín. Ó ṣe tán, ọmọ ọba ni.”+
35 Àmọ́ nígbà tí wọ́n fẹ́ lọ sin ín, agbárí rẹ̀ àti ẹsẹ̀ rẹ̀ pẹ̀lú àwọn àtẹ́lẹwọ́ rẹ̀ nìkan ló ṣẹ́ kù tí wọ́n rí.+
36 Nígbà tí wọ́n pa dà tí wọ́n sì sọ fún un, ó sọ pé: “Ọ̀rọ̀ Jèhófà ló ṣẹ,+ èyí tó gbẹnu Èlíjà ará Tíṣíbè ìránṣẹ́ rẹ̀ sọ pé, ‘Orí ilẹ̀ tó wà ní Jésírẹ́lì ni àwọn ajá ti máa jẹ ẹran ara Jésíbẹ́lì.+
37 Òkú Jésíbẹ́lì yóò sì di ajílẹ̀ lórí ilẹ̀ tó wà ní Jésírẹ́lì, tí ẹnikẹ́ni ò fi ní lè sọ pé: “Jésíbẹ́lì nìyí.”’”
Àlàyé Ìsàlẹ̀ Ìwé
^ Ìyẹn, ohun tí a fi amọ̀ ṣe tó dà bí ìgò ńlá.
^ Ní Héb., “ẹnikẹ́ni tó ń tọ̀ sára ògiri.” Ọ̀rọ̀ Hébérù tí wọ́n fi ń pẹ̀gàn àwọn ọkùnrin.
^ Tàbí “ọkàn yín.”
^ Ní Héb., “ọmọ.”
^ Ní Héb., “ọrun.”
^ Ní Héb., “àwọn kẹ̀kẹ́ ẹṣin tí ọ̀wọ́ ẹṣin ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀ ń fà.”
^ Tàbí “tọ́ lẹ́ẹ̀dì.”
^ Tàbí “wíńdò.”