Kíróníkà Kejì 11:1-23

  • Ìjọba Rèhóbóámù (1-12)

  • Àwọn ọmọ Léfì tí wọ́n jẹ́ adúróṣinṣin lọ sí Júdà (13-17)

  • Ìdílé Rèhóbóámù (18-23)

11  Nígbà tí Rèhóbóámù dé Jerúsálẹ́mù, ẹsẹ̀kẹsẹ̀ ló pe ilé Júdà àti Bẹ́ńjámínì+ jọ, ọ̀kẹ́ mẹ́sàn-án (180,000) akọgun,* láti bá Ísírẹ́lì jà, kí wọ́n lè gba ìjọba pa dà fún Rèhóbóámù.+  Ìgbà náà ni Jèhófà bá Ṣemáyà,+ èèyàn Ọlọ́run tòótọ́ sọ̀rọ̀, ó ní:  “Sọ fún Rèhóbóámù ọmọ Sólómọ́nì ọba Júdà àti gbogbo Ísírẹ́lì ní Júdà àti Bẹ́ńjámínì pé,  ‘Ohun tí Jèhófà sọ nìyí: “Ẹ kò gbọ́dọ̀ lọ bá àwọn arákùnrin yín jà. Kí kálukú yín pa dà sí ilé rẹ̀, torí èmi ló mú kí nǹkan yìí ṣẹlẹ̀.”’”+ Nítorí náà, wọ́n ṣe ohun tí Jèhófà sọ, wọ́n pa dà, wọn ò sì lọ bá Jèróbóámù jà.  Rèhóbóámù ń gbé Jerúsálẹ́mù, ó sì kọ́ àwọn ìlú olódi sí Júdà.  Ó tipa bẹ́ẹ̀ kọ́* Bẹ́tílẹ́hẹ́mù,+ Étámì, Tékóà,+  Bẹti-súrì, Sókò,+ Ádúlámù,+  Gátì,+ Máréṣà, Sífù,+  Ádóráímù,+ Lákíṣì, Ásékà,+ 10  Sórà, Áíjálónì+ àti Hébúrónì,+ àwọn ìlú olódi tó wà ní Júdà àti Bẹ́ńjámínì. 11  Yàtọ̀ síyẹn, ó mú kí àwọn ibi olódi lágbára sí i, ó sì fi àwọn aláṣẹ sínú wọn, ó ń fún wọn ní oúnjẹ àti òróró àti wáìnì, 12  ó sì fún àwọn ìlú kọ̀ọ̀kan ní apata ńlá àti aṣóró; ó mú kí wọ́n lágbára gan-an. Ó sì ń ṣàkóso lórí Júdà àti Bẹ́ńjámínì nìṣó. 13  Àwọn àlùfáà àti àwọn ọmọ Léfì tó wà ní gbogbo Ísírẹ́lì dúró tì í, wọ́n ń jáde wá láti gbogbo ìpínlẹ̀ wọn. 14  Àwọn ọmọ Léfì fi àwọn ibi ìjẹko wọn àti ohun ìní wọn sílẹ̀,+ wọ́n wá sí Júdà àti Jerúsálẹ́mù, torí pé Jèróbóámù àti àwọn ọmọ rẹ̀ ti lé wọn kúrò lẹ́nu iṣẹ́ àlùfáà fún Jèhófà.+ 15  Jèróbóámù wá yan àwọn àlùfáà tirẹ̀ fún àwọn ibi gíga+ àti fún àwọn ẹ̀mí èṣù+ tó rí bí ewúrẹ́* àti fún àwọn ère ọmọ màlúù tí ó ṣe.+ 16  Àwọn tó wá láti gbogbo ẹ̀yà Ísírẹ́lì tí wọ́n ti pinnu láti máa wá Jèhófà Ọlọ́run Ísírẹ́lì tẹ̀ lé àwọn àlùfáà àti àwọn ọmọ Léfì wá sí Jerúsálẹ́mù láti rúbọ sí Jèhófà Ọlọ́run àwọn baba ńlá wọn.+ 17  Ọdún mẹ́ta ni wọ́n fi kọ́wọ́ ti ìjọba Júdà, wọ́n sì ti Rèhóbóámù ọmọ Sólómọ́nì lẹ́yìn, wọ́n rìn ní ọ̀nà Dáfídì àti Sólómọ́nì fún ọdún mẹ́ta. 18  Nígbà náà, Rèhóbóámù fi Máhálátì ṣe aya, bàbá rẹ̀ ni Jérímótì ọmọ Dáfídì, ìyá rẹ̀ sì ni Ábíháílì ọmọ Élíábù+ ọmọ Jésè. 19  Nígbà tó yá, ó bí àwọn ọmọkùnrin fún un, àwọn ni: Jéúṣì, Ṣemaráyà àti Sáhámù. 20  Lẹ́yìn rẹ̀, ó fẹ́ Máákà ọmọ ọmọ Ábúsálómù.+ Nígbà tó yá, ó bí Ábíjà,+ Átáì, Sísà àti Ṣẹ́lómítì fún un. 21  Rèhóbóámù nífẹ̀ẹ́ Máákà ọmọ ọmọ Ábúsálómù ju gbogbo àwọn ìyàwó rẹ̀ yòókù àti àwọn wáhàrì*+ rẹ̀ lọ. Ó ní ìyàwó méjìdínlógún (18) àti ọgọ́ta (60) wáhàrì, ó sì bí ọmọkùnrin méjìdínlọ́gbọ̀n (28) àti ọgọ́ta (60) ọmọbìnrin. 22  Nítorí náà, Rèhóbóámù yan Ábíjà ọmọ Máákà ṣe olórí àti aṣáájú láàárín àwọn arákùnrin rẹ̀, torí ó fẹ́ fi jọba. 23  Àmọ́, ó dá ọgbọ́n, ó rán lára àwọn ọmọkùnrin rẹ̀ lọ* sí gbogbo agbègbè Júdà àti Bẹ́ńjámínì àti sí gbogbo àwọn ìlú olódi,+ ó fún wọn ní ọ̀pọ̀ rẹpẹtẹ ohun tí wọ́n nílò, ó sì fẹ́ ìyàwó púpọ̀ fún wọn.

Àlàyé Ìsàlẹ̀ Ìwé

Ní Héb., “àṣàyàn jagunjagun.”
Tàbí “mọ odi.”
Ní Héb., “àwọn ewúrẹ́.”
Tàbí “ìyàwó onípò kejì.” Wo Àlàyé Ọ̀rọ̀, “Wáhàrì.”
Tàbí “fọ́n lára àwọn ọmọ rẹ̀ ká.”