Kíróníkà Kejì 35:1-27
35 Jòsáyà ṣe Ìrékọjá+ kan fún Jèhófà ní Jerúsálẹ́mù, wọ́n sì pa ẹran Ìrékọjá náà + ní ọjọ́ kẹrìnlá oṣù kìíní.+
2 Ó yan àwọn àlùfáà sẹ́nu iṣẹ́ wọn, ó sì fún wọn ní ìṣírí pé kí wọ́n máa ṣe iṣẹ́ ìsìn wọn ní ilé Jèhófà.+
3 Lẹ́yìn náà, ó sọ fún àwọn ọmọ Léfì, àwọn olùkọ́ gbogbo Ísírẹ́lì,+ tí wọ́n jẹ́ mímọ́ sí Jèhófà pé: “Ẹ gbé Àpótí mímọ́ sínú ilé tí Sólómọ́nì ọmọ Dáfídì ọba Ísírẹ́lì kọ́;+ ẹ ò ní máa gbé e lé èjìká yín mọ́.+ Ní báyìí, ẹ ṣiṣẹ́ sin Jèhófà Ọlọ́run yín àti àwọn èèyàn rẹ̀ Ísírẹ́lì.
4 Ẹ ṣètò ara yín sí àwùjọ-àwùjọ nínú agbo ilé yín, gẹ́gẹ́ bí ohun tí Dáfídì+ ọba Ísírẹ́lì àti Sólómọ́nì ọmọ rẹ̀ kọ sílẹ̀.+
5 Ẹ dúró ní ibi mímọ́ ní àwùjọ tí wọ́n pín agbo ilé àwọn arákùnrin yín sí, ìyẹn ìyókù àwọn èèyàn náà,* kí àwùjọ kọ̀ọ̀kan wọn ní àwùjọ kan látinú ìdílé àwọn ọmọ Léfì tó máa ṣiṣẹ́ fún wọn.
6 Kí ẹ pa ẹran Ìrékọjá,+ kí ẹ ya ara yín sí mímọ́, kí ẹ sì múra sílẹ̀ de àwọn arákùnrin yín kí wọ́n lè ṣe ohun tí Jèhófà gbẹnu Mósè sọ.”
7 Jòsáyà fún àwọn èèyàn náà ní agbo ẹran, akọ ọ̀dọ́ àgùntàn àti akọ ọmọ ewúrẹ́, láti fi ṣe ẹran Ìrékọjá fún gbogbo àwọn tó wá, àpapọ̀ rẹ̀ jẹ́ ọ̀kẹ́ kan ààbọ̀ (30,000), ó tún fi ẹgbẹ̀rún mẹ́ta (3,000) màlúù kún un. Inú ohun ìní ọba ni àwọn nǹkan yìí ti wá.+
8 Àwọn ìjòyè rẹ̀ tún fún àwọn èèyàn náà àti àwọn àlùfáà pẹ̀lú àwọn ọmọ Léfì ní ọrẹ àtinúwá. Hilikáyà,+ Sekaráyà àti Jéhíélì, àwọn aṣáájú ilé Ọlọ́run tòótọ́, fún àwọn àlùfáà ní ẹgbẹ̀rún méjì ó lé ọgọ́rùn-ún mẹ́fà (2,600) ẹran Ìrékọjá àti ọgọ́rùn-ún mẹ́ta (300) màlúù.
9 Konanáyà àti àwọn arákùnrin rẹ̀ Ṣemáyà àti Nétánélì pẹ̀lú Haṣabáyà, Jéélì àti Jósábádì, àwọn olórí àwọn ọmọ Léfì, fún àwọn ọmọ Léfì ní ẹgbẹ̀rún márùn-ún (5,000) ẹran Ìrékọjá àti ọgọ́rùn-ún márùn-ún (500) màlúù.
10 Wọ́n múra iṣẹ́ ìsìn náà sílẹ̀, àwọn àlùfáà dúró sí àyè wọn, àwọn ọmọ Léfì sì dúró ní àwọn àwùjọ wọn,+ gẹ́gẹ́ bí ọba ṣe pa á láṣẹ.
11 Wọ́n pa àwọn ẹran Ìrékọjá,+ àwọn àlùfáà wọ́n ẹ̀jẹ̀ tí wọ́n gbà lára wọn,+ àwọn ọmọ Léfì sì ń bó awọ àwọn ẹran náà.+
12 Lẹ́yìn náà, wọ́n ṣètò àwọn ẹbọ sísun kí wọ́n lè pín wọn fún ìyókù àwọn èèyàn náà, àwọn tí wọ́n wà ní àwùjọ-àwùjọ nínú agbo ilé bàbá wọn, kí wọ́n lè mú wọn wá fún Jèhófà bó ṣe wà lákọsílẹ̀ nínú ìwé Mósè; wọ́n sì ṣe ohun kan náà ní ti àwọn màlúù náà.
13 Wọ́n se* ẹran Ìrékọjá lórí iná gẹ́gẹ́ bí àṣà;+ wọ́n sì se àwọn ẹran mímọ́ nínú àwọn ìkòkò àti àwọn ìkòkò irin pẹ̀lú àwọn páànù, lẹ́yìn náà, wọ́n gbé e wá kíákíá fún gbogbo ìyókù àwọn èèyàn náà.
14 Lẹ́yìn náà, wọ́n ṣètò nǹkan sílẹ̀ fún ara wọn àti fún àwọn àlùfáà, nítorí pé àwọn àlùfáà, ìyẹn àwọn ọmọ Áárónì, ń rú ẹbọ sísun àti àwọn apá tó lọ́ràá títí ilẹ̀ fi ṣú, torí náà, àwọn ọmọ Léfì ṣètò nǹkan sílẹ̀ fún ara wọn àti fún àwọn àlùfáà, àwọn ọmọ Áárónì.
15 Àwọn akọrin, ìyẹn àwọn ọmọ Ásáfù,+ wà ní àyè wọn gẹ́gẹ́ bí àṣẹ Dáfídì+ àti Ásáfù+ àti Hémánì pẹ̀lú Jédútúnì+ aríran ọba; àwọn aṣọ́bodè sì wà ní ẹnubodè kọ̀ọ̀kan.+ Kò sí ìdí fún wọn láti kúrò lẹ́nu iṣẹ́ ìsìn wọn, nítorí pé àwọn arákùnrin wọn àwọn ọmọ Léfì ti ṣètò nǹkan sílẹ̀ fún wọn.
16 Torí náà, wọ́n ṣètò gbogbo iṣẹ́ ìsìn Jèhófà ní ọjọ́ yẹn kí wọ́n lè ṣe Ìrékọjá náà,+ kí wọ́n sì rú ẹbọ sísun lórí pẹpẹ Jèhófà, gẹ́gẹ́ bí àṣẹ tí Ọba Jòsáyà pa.+
17 Àwọn ọmọ Ísírẹ́lì tó wà níbẹ̀ fi ọjọ́ méje ṣe Ìrékọjá àti Àjọyọ̀ Búrẹ́dì Aláìwú ní àkókò yẹn.+
18 Wọn ò ṣe irú Ìrékọjá bẹ́ẹ̀ rí ní Ísírẹ́lì láti ìgbà ayé wòlíì Sámúẹ́lì; bẹ́ẹ̀ ni kò sí ìkankan lára àwọn ọba Ísírẹ́lì tó ṣe irú Ìrékọjá tí Jòsáyà ṣe+ pẹ̀lú àwọn àlùfáà àti àwọn ọmọ Léfì àti gbogbo Júdà pẹ̀lú àwọn ọmọ Ísírẹ́lì tó wà níbẹ̀ àti àwọn tó ń gbé Jerúsálẹ́mù.
19 Wọ́n ṣe Ìrékọjá yìí ní ọdún kejìdínlógún ìjọba Jòsáyà.
20 Lẹ́yìn gbogbo nǹkan yìí, tí Jòsáyà ti múra tẹ́ńpìlì* náà sílẹ̀, Nékò+ ọba Íjíbítì wá jà ní Kákémíṣì lẹ́gbẹ̀ẹ́ Yúfírétì. Ni Jòsáyà bá jáde lọ dojú kọ ọ́.+
21 Torí náà, ó rán àwọn òjíṣẹ́ sí Jòsáyà, ó ní: “Kí ló kàn ọ́ nínú ọ̀ràn yìí, ìwọ ọba Júdà? Ìwọ kọ́ ni mo wá bá jà lónìí, ilé mìíràn ni mo wá bá, Ọlọ́run sì sọ fún mi pé kí n ṣe kíá. Torí náà, fún àǹfààní ara rẹ, má dojú kọ Ọlọ́run, ẹni tó wà pẹ̀lú mi, àìjẹ́ bẹ́ẹ̀, ó máa pa ọ́ run.”
22 Síbẹ̀, Jòsáyà kò pa dà lẹ́yìn rẹ̀, ńṣe ló para dà+ láti lọ bá a jà, kò sì fetí sí ọ̀rọ̀ Nékò, èyí tó wá láti ẹnu Ọlọ́run. Torí náà, ó wá jà ní Pẹ̀tẹ́lẹ̀ Mẹ́gídò.+
23 Àwọn tafàtafà ta Ọba Jòsáyà lọ́fà, ọba sì sọ fún àwọn ìránṣẹ́ rẹ̀ pé: “Ẹ gbé mi kúrò níbí, torí mo ti fara gbọgbẹ́ gan-an.”
24 Torí náà, àwọn ìránṣẹ́ rẹ̀ gbé e kúrò nínú kẹ̀kẹ́ ẹṣin, wọ́n sì fi kẹ̀kẹ́ ogun rẹ̀ kejì gbé e wá sí Jerúsálẹ́mù. Bó ṣe kú nìyẹn, wọ́n sì sin ín sí ibojì àwọn baba ńlá rẹ̀,+ gbogbo Júdà àti Jerúsálẹ́mù sì ṣọ̀fọ̀ Jòsáyà.
25 Jeremáyà+ sun rárà fún Jòsáyà, gbogbo akọrin lọ́kùnrin àti lóbìnrin+ sì ń sọ nípa Jòsáyà nínú orin arò* wọn títí di òní yìí; wọ́n pinnu pé kí wọ́n máa kọ àwọn orin náà ní Ísírẹ́lì, wọ́n sì wà lákọsílẹ̀ nínú àwọn orin arò.
26 Ní ti ìyókù ìtàn Jòsáyà àti ìfẹ́ tí kì í yẹ̀ tó fi hàn, bó ṣe ń tẹ̀ lé ohun tó wà lákọsílẹ̀ nínú Òfin Jèhófà,
27 títí kan àwọn ohun tó ṣe, láti ìbẹ̀rẹ̀ dé òpin, wọ́n wà lákọsílẹ̀ nínú Ìwé Àwọn Ọba Ísírẹ́lì àti ti Júdà.+
Àlàyé Ìsàlẹ̀ Ìwé
^ Ní Héb., “àwọn ọmọ àwọn èèyàn náà.”
^ Tàbí kó jẹ́, “yan.”
^ Ní Héb., “ilé.”
^ Tàbí “àwọn orin ọ̀fọ̀.”