Kíróníkà Kejì 8:1-18

  • Àwọn iṣẹ́ ìkọ́lé míì tí Sólómọ́nì ṣe (1-11)

  • Ó ṣètò bí wọ́n á ṣe máa jọ́sìn ní tẹ́ńpìlì (12-16)

  • Àwọn ọkọ̀ òkun Sólómọ́nì (17, 18)

8  Ní òpin ogún (20) ọdún tí Sólómọ́nì fi kọ́ ilé Jèhófà àti ilé ara rẹ̀,*+  Sólómọ́nì tún àwọn ìlú tí Hírámù+ fún un kọ́, ó sì ní kí àwọn ọmọ Ísírẹ́lì* máa gbé ibẹ̀.  Yàtọ̀ síyẹn, Sólómọ́nì lọ sí Hamati-sóbà, ó sì gbà á.  Lẹ́yìn náà, ó kọ́ Tádímórì ní aginjù* àti gbogbo àwọn ìlú tí ó ń kó nǹkan pa mọ́ sí,+ èyí tó kọ́ sí Hámátì.+  Ó tún kọ́ Bẹti-hórónì Òkè+ àti Bẹti-hórónì Ìsàlẹ̀,+ àwọn ìlú aláàbò tó ní ògiri àti àwọn ẹnubodè pẹ̀lú ọ̀pá ìdábùú.  Bákan náà, ó kọ́ Báálátì+ pẹ̀lú gbogbo àwọn ìlú tó ń kó nǹkan pa mọ́ sí, gbogbo àwọn ìlú kẹ̀kẹ́ ẹṣin,+ àwọn ìlú àwọn agẹṣin àti ohunkóhun tó wu Sólómọ́nì láti kọ́ sí Jerúsálẹ́mù, sí Lẹ́bánónì àti sí gbogbo ilẹ̀ tó ń ṣàkóso lé lórí.  Ní ti gbogbo àwọn tó ṣẹ́ kù lára àwọn ọmọ Hétì, àwọn Ámórì, àwọn Pérísì, àwọn Hífì àti àwọn ará Jébúsì,+ tí wọn kì í ṣe ara àwọn ọmọ Ísírẹ́lì,+  àwọn àtọmọdọ́mọ wọn tó ṣẹ́ kù sí ilẹ̀ náà, ìyẹn àwọn tí àwọn ọmọ Ísírẹ́lì kò pa run,+ Sólómọ́nì ní kí wọ́n máa ṣiṣẹ́ fún òun títí di òní yìí.+  Àmọ́ Sólómọ́nì kò fi ọmọ Ísírẹ́lì kankan ṣe ẹrú fún iṣẹ́ rẹ̀,+ àwọn ló fi ṣe jagunjagun rẹ̀, olórí àwọn olùrànlọ́wọ́ ọ̀gágun rẹ̀, olórí àwọn tó ń gun kẹ̀kẹ́ ẹṣin àti ti àwọn agẹṣin rẹ̀.+ 10  Olórí àwọn alábòójútó fún Ọba Sólómọ́nì jẹ́ igba ó lé àádọ́ta (250), àwọn ló sì ń darí àwọn èèyàn náà.+ 11  Bákan náà, Sólómọ́nì mú ọmọbìnrin Fáráò+ wá láti Ìlú Dáfídì sí ilé tó kọ́ fún un,+ torí ó sọ pé: “Bó tilẹ̀ jẹ́ pé ìyàwó mi ni, kò yẹ kó máa gbé inú ilé Dáfídì ọba Ísírẹ́lì, nítorí ibi tí Àpótí Jèhófà bá ti wọ̀ ti di mímọ́.”+ 12  Lẹ́yìn náà, Sólómọ́nì rú àwọn ẹbọ sísun+ sí Jèhófà lórí pẹpẹ+ Jèhófà tí ó mọ síwájú ibi àbáwọlé.*+ 13  Ó ń ṣe ohun tí wọ́n máa ń ṣe lójoojúmọ́, ó sì ń mú ọrẹ wá gẹ́gẹ́ bí àṣẹ tí Mósè pa ní ti àwọn Sábáàtì,+ àwọn òṣùpá tuntun+ àti àwọn àjọyọ̀ tó máa ń wáyé nígbà mẹ́ta lọ́dún,+ ìyẹn Àjọyọ̀ Búrẹ́dì Aláìwú,+ Àjọyọ̀ Àwọn Ọ̀sẹ̀+ àti Àjọyọ̀ Àtíbàbà.+ 14  Síwájú sí i, ó yan àwùjọ àwọn àlùfáà+ sí àwọn iṣẹ́ ìsìn wọn gẹ́gẹ́ bí ìlànà tí Dáfídì bàbá rẹ̀ fi lélẹ̀, ó yan àwọn ọmọ Léfì sẹ́nu iṣẹ́ wọn, láti máa yin+ Ọlọ́run àti láti máa ṣe ìránṣẹ́ níwájú àwọn àlùfáà bí wọ́n ti ń ṣe lójoojúmọ́, ó tún yan àwùjọ àwọn aṣọ́bodè sí ẹnubodè kọ̀ọ̀kan,+ nítorí ohun tí Dáfídì, èèyàn Ọlọ́run tòótọ́ pa láṣẹ nìyẹn. 15  Wọn ò kúrò nínú àṣẹ tí ọba pa fún àwọn àlùfáà àti àwọn ọmọ Léfì nínú ọ̀ràn èyíkéyìí tàbí ní ti ilé ìkẹ́rùsí. 16  Nítorí náà, gbogbo iṣẹ́ Sólómọ́nì wà létòlétò,* láti ọjọ́ tí wọ́n ti fi ìpìlẹ̀ ilé Jèhófà lélẹ̀+ títí ó fi parí. Bí ilé Jèhófà ṣe parí nìyẹn.+ 17  Ìgbà náà ni Sólómọ́nì lọ sí Esioni-gébérì+ àti sí Élótì+ ní èbúté òkun tó wà ní ilẹ̀ Édómù.+ 18  Hírámù+ fi àwọn ọkọ̀ òkun àti àwọn òṣìṣẹ́ ọkọ̀ òkun tó mọṣẹ́ ránṣẹ́ sí Sólómọ́nì nípasẹ̀ àwọn ìránṣẹ́ rẹ̀. Wọ́n bá àwọn ìránṣẹ́ Sólómọ́nì lọ sí Ófírì,+ wọ́n sì kó ọgọ́rùn-ún mẹ́rin ó lé àádọ́ta (450) tálẹ́ńtì* wúrà+ láti ibẹ̀ wá fún Ọba Sólómọ́nì.+

Àlàyé Ìsàlẹ̀ Ìwé

Tàbí “ààfin.”
Ní Héb., “àwọn ọmọkùnrin Ísírẹ́lì.”
Tàbí “ó tún Tádímórì ní aginjù kọ́.”
Tàbí “gọ̀bì.”
Tàbí “lẹ́sẹẹsẹ; parí.”
Tálẹ́ńtì kan jẹ́ kìlógíráàmù 34.2. Wo Àfikún B14.