Ìwé Kejì sí Àwọn Ará Kọ́ríńtì 1:1-24
1 Pọ́ọ̀lù, àpọ́sítélì Kristi Jésù nípasẹ̀ ìfẹ́ Ọlọ́run àti Tímótì+ arákùnrin wa, sí ìjọ Ọlọ́run tó wà ní Kọ́ríńtì, títí kan gbogbo ẹni mímọ́ tó wà ní gbogbo Ákáyà:+
2 Kí ẹ ní inú rere àìlẹ́tọ̀ọ́sí àti àlàáfíà látọ̀dọ̀ Ọlọ́run, Baba wa àti Jésù Kristi Olúwa.
3 Ìyìn ni fún Ọlọ́run àti Baba Olúwa wa Jésù Kristi,+ Baba àánú oníjẹ̀lẹ́ńkẹ́+ àti Ọlọ́run ìtùnú gbogbo,+
4 ẹni tó ń tù wá nínú* nínú gbogbo àdánwò* wa,+ kí a lè fi ìtùnú tí a gbà lọ́dọ̀ rẹ̀+ tu àwọn míì nínú+ lábẹ́ àdánwò* èyíkéyìí tí wọ́n bá wà.
5 Torí pé bí ìyà tí à ń jẹ nítorí Kristi ṣe pọ̀,+ bẹ́ẹ̀ náà ni ìtùnú tí à ń rí gbà nípasẹ̀ Kristi ṣe pọ̀.
6 Nígbà náà, tí a bá dojú kọ àdánwò,* torí ìtùnú àti ìgbàlà yín ni; tí a bá sì ń tù wá nínú, torí kí ẹ lè rí ìtùnú ni, èyí tó máa jẹ́ kí ẹ lè fara da ìyà kan náà tí à ń jẹ.
7 Ìrètí wa lórí yín dájú, nítorí a mọ̀ pé bí ẹ ṣe ń jìyà bíi tiwa, bẹ́ẹ̀ ni ẹ máa rí ìtùnú bíi tiwa.+
8 Ẹ̀yin ará, a fẹ́ kí ẹ mọ̀ nípa ìpọ́njú tó bá wa ní ìpínlẹ̀ Éṣíà.+ A wà nínú ìdààmú tó lé kenkà, kódà ó kọjá agbára wa, a ò tiẹ̀ mọ̀ pé ẹ̀mí wa ò ní bọ́.+
9 Ká sòótọ́, ṣe ló ń ṣe wá bíi pé a ti gba ìdájọ́ ikú. Èyí jẹ́ kí a má bàa gbẹ́kẹ̀ lé ara wa, àmọ́ ká lè gbẹ́kẹ̀ lé Ọlọ́run+ tó ń gbé òkú dìde.
10 Ó gbà wá sílẹ̀ látinú irú ewu ikú tó lágbára bẹ́ẹ̀, ó sì máa gbà wá sílẹ̀, òun la gbẹ́kẹ̀ lé pé á máa gbà wá sílẹ̀ nìṣó.+
11 Ẹ̀yin náà lè máa fi ìrawọ́ ẹ̀bẹ̀ yín ràn wá lọ́wọ́,+ kí ọ̀pọ̀lọpọ̀ lè máa dúpẹ́ nítorí wa pé a rí inú rere gbà, èyí tó jẹ́ ìdáhùn àdúrà ọ̀pọ̀ èèyàn.*+
12 Nítorí ohun tí a fi ń yangàn nìyí, ẹ̀rí ọkàn wa ń jẹ́rìí pé a ti fi ìjẹ́mímọ́ àti òótọ́ inú lọ́nà ti Ọlọ́run hùwà nínú ayé, pàápàá sí yín, kì í ṣe pẹ̀lú ọgbọ́n ti ara,+ àmọ́ pẹ̀lú inú rere àìlẹ́tọ̀ọ́sí Ọlọ́run.
13 Lóòótọ́, àwọn nǹkan tí ẹ lè kà kí ẹ sì* lóye nìkan là ń kọ ránṣẹ́ sí yín, mo sì retí pé ẹ̀ẹ́ túbọ̀ lóye àwọn nǹkan yìí ní ẹ̀kúnrẹ́rẹ́,*
14 bí ẹ̀yin náà ṣe mọ̀ dé àyè kan pé a wà lára ohun tí ẹ lè fi yangàn, bí ẹ̀yin pẹ̀lú ṣe máa jẹ́ fún wa ní ọjọ́ Olúwa wa Jésù.
15 Torí náà, pẹ̀lú ìdánilójú yìí, mo fẹ́ kọ́kọ́ wá sọ́dọ̀ yín tẹ́lẹ̀, kí ẹ lè ní ìdí láti dunnú lẹ́ẹ̀kan sí i;*
16 torí mo fẹ́ bẹ̀ yín wò tí mo bá ń lọ sí Makedóníà, kí n sì tún pa dà sọ́dọ̀ yín tí mo bá ń bọ̀ láti Makedóníà, lẹ́yìn náà kí ẹ sìn mí dé ọ̀nà Jùdíà.+
17 Tóò, nígbà tí mo ní irú nǹkan yìí lọ́kàn, mi ò fojú kékeré wo ọ̀rọ̀ náà, àbí mo ṣe bẹ́ẹ̀? Àbí ẹran ara ló mú kí n fẹ́ ṣe bẹ́ẹ̀, tí mo wá ń sọ pé “Bẹ́ẹ̀ ni, bẹ́ẹ̀ ni” àmọ́ tí mo tún ń sọ pé “Bẹ́ẹ̀ kọ́, bẹ́ẹ̀ kọ́”?
18 Àmọ́ Ọlọ́run ṣeé gbẹ́kẹ̀ lé pé ohun tí a sọ fún yín kì í ṣe “bẹ́ẹ̀ ni” kó tún wá jẹ́ “bẹ́ẹ̀ kọ́.”
19 Nítorí Ọmọ Ọlọ́run, Jésù Kristi, tí a wàásù rẹ̀ láàárín yín, ìyẹn nípasẹ̀ èmi àti Sílífánù* pẹ̀lú Tímótì,+ kò di “bẹ́ẹ̀ ni” kó tún wá jẹ́ “bẹ́ẹ̀ kọ́,” àmọ́ “bẹ́ẹ̀ ni” ti di “bẹ́ẹ̀ ni” nínú ọ̀rọ̀ tirẹ̀.
20 Nítorí bó ṣe wù kí àwọn ìlérí Ọlọ́run pọ̀ tó, wọ́n ti di “bẹ́ẹ̀ ni” nípasẹ̀ rẹ̀.+ Torí náà, ipasẹ̀ rẹ̀ pẹ̀lú ni à ń ṣe “Àmín” sí Ọlọ́run,+ èyí tó ń fi ògo fún un nípasẹ̀ wa.
21 Àmọ́ Ọlọ́run ni ẹni tó ń mú kó dájú pé àwa àti ẹ̀yin jẹ́ ti Kristi, òun ló sì yàn wá.+
22 Ó tún fi èdìdì rẹ̀ sórí wa,+ ó sì ti fún wa ní àmì ìdánilójú ohun tó ń bọ̀,* ìyẹn ẹ̀mí+ tó wà nínú ọkàn wa.
23 Mo fi Ọlọ́run ṣe ẹlẹ́rìí ara* mi pé torí kí n má bàa tún kó ẹ̀dùn ọkàn bá yín ni mi ò ṣe tíì wá sí Kọ́ríńtì.
24 Kì í ṣe pé a jẹ́ ọ̀gá lórí ìgbàgbọ́ yín,+ àmọ́ a jọ ń ṣiṣẹ́ kí ẹ lè máa láyọ̀, torí ìgbàgbọ́ yín ló mú kí ẹ dúró.
Àlàyé Ìsàlẹ̀ Ìwé
^ Tàbí “ìpọ́njú.”
^ Tàbí “ìpọ́njú.”
^ Tàbí “tó ń fún wa níṣìírí.”
^ Tàbí “ìpọ́njú.”
^ Tàbí “nítorí ọ̀pọ̀ àwọn tó tẹ́wọ́ àdúrà.”
^ Tàbí kó jẹ́, “tí ẹ ti mọ̀ dáadáa, tí ẹ sì.”
^ Ní Grk., “títí dé òpin.”
^ Tàbí kó jẹ́, “kí ẹ lè jàǹfààní lẹ́ẹ̀mejì.”
^ Wọ́n tún ń pè é ní Sílà.
^ Tàbí “àsansílẹ̀; ìdánilójú (ẹ̀jẹ́) ohun tó ń bọ̀.”
^ Tàbí “ọkàn.”