Ìwé Kejì sí Àwọn Ará Kọ́ríńtì 11:1-33
11 Ó wù mí kí ẹ máa fara dà á bó bá tiẹ̀ jọ pé mo dà bí aláìnírònú. Àmọ́, ká sòótọ́, ẹ ti ń fara dà á fún mi!
2 Mò ń jowú torí yín lọ́nà ti Ọlọ́run,* nítorí èmi fúnra mi ti fẹ́ yín sílẹ̀ de ọkọ kan, kí n lè mú yín wá fún Kristi bíi wúńdíá oníwà mímọ́.*+
3 Àmọ́ ẹ̀rù ń bà mí pé lọ́nà kan ṣáá, bí ejò ṣe fi ẹ̀tàn fa ojú Éfà mọ́ra,+ a lè sọ ìrònú yín dìbàjẹ́, tí ẹ ó sì yà kúrò nínú òtítọ́ inú àti ìwà mímọ́* tó yẹ Kristi.+
4 Torí ní báyìí, tí ẹnì kan bá wá, tó sì wàásù Jésù kan yàtọ̀ sí èyí tí a ti wàásù tàbí tí ẹ bá gba ẹ̀mí kan tó yàtọ̀ sí èyí tí ẹ ti gbà tàbí tí ẹ gba ìhìn rere kan tó yàtọ̀ sí èyí tí ẹ ti gbà,+ ẹ̀ ń gba onítọ̀hún láyè láìjanpata.
5 Mo rò pé kò sí ohun kankan tó fi hàn pé àwọn àpọ́sítélì yín adára-má-kù-síbìkan sàn jù mí lọ.+
6 Àmọ́ ká tiẹ̀ sọ pé ọ̀rọ̀ kò dá ṣáká lẹ́nu mi,+ ó dájú pé mi ò rí bẹ́ẹ̀ nínú ìmọ̀; ní tòótọ́, a jẹ́ kó ṣe kedere sí yín ní gbogbo ọ̀nà àti nínú ohun gbogbo.
7 Àbí, ṣé ẹ̀ṣẹ̀ ni mo dá ni bí mo ṣe rẹ ara mi sílẹ̀ kí a lè gbé yín ga, tí mo fi ayọ̀ kéde ìhìn rere Ọlọ́run fún yín lọ́fẹ̀ẹ́?+
8 Mo fi nǹkan du àwọn ìjọ míì* bí mo ṣe gba àwọn nǹkan* lọ́wọ́ wọn kí n lè ṣe ìránṣẹ́ fún yín.+
9 Síbẹ̀, nígbà tí mo wà lọ́dọ̀ yín, tí mo sì nílò àwọn nǹkan kan, mi ò di ẹrù sí ẹnikẹ́ni lọ́rùn, torí àwọn arákùnrin tó wá láti Makedóníà pèsè àwọn nǹkan tí mo nílò lọ́pọ̀ yanturu.+ Bẹ́ẹ̀ ni, mo kíyè sára ní gbogbo ọ̀nà kí n má bàa di ẹrù sí yín lọ́rùn, màá sì máa bá a lọ bẹ́ẹ̀.+
10 Bó ṣe dájú pé òtítọ́ Kristi wà nínú mi, mi ò ní ṣíwọ́ láti máa yangàn + ní àwọn agbègbè Ákáyà.
11 Nítorí kí ni? Ṣé torí mi ò nífẹ̀ẹ́ yín ni? Ọlọ́run mọ̀ pé mo nífẹ̀ẹ́ yín.
12 Àmọ́ ohun tí mò ń ṣe ni màá máa ṣe lọ,+ kí n lè fòpin sí àwáwí àwọn tó ń wá bí wọ́n á ṣe rí ohun* tí wọ́n á fi sọ pé àwọn jẹ́ bákan náà pẹ̀lú wa nínú àwọn nǹkan* tí wọ́n fi ń yangàn.
13 Nítorí irú àwọn èèyàn bẹ́ẹ̀ jẹ́ èké àpọ́sítélì, àwọn oníṣẹ́ ẹ̀tàn, tí wọ́n ń díbọ́n pé àpọ́sítélì Kristi ni àwọn.+
14 Kò sì yani lẹ́nu, torí Sátánì fúnra rẹ̀ máa ń díbọ́n pé áńgẹ́lì ìmọ́lẹ̀ ni òun.+
15 Nítorí náà, kì í ṣe ohun ńlá bí àwọn òjíṣẹ́ rẹ̀ náà bá ń díbọ́n pé òjíṣẹ́ òdodo ni àwọn. Àmọ́ òpin wọn máa rí bí iṣẹ́ wọn.+
16 Mo tún sọ pé: Kí ẹnikẹ́ni má rò pé mi ò nírònú. Àmọ́ ká tiẹ̀ ní ẹ rò bẹ́ẹ̀, ẹ gbà mí bí aláìnírònú, kí èmi náà lè yangàn díẹ̀.
17 Ní báyìí, mi ò sọ̀rọ̀ bí ẹni tó ń tẹ̀ lé àpẹẹrẹ Olúwa, àmọ́ mò ń sọ̀rọ̀ bí aláìnírònú tó dá ara rẹ̀ lójú tó sì ń fọ́nnu.
18 Bó ṣe jẹ́ pé ọ̀pọ̀ ló ń yangàn nípa ti ara,* èmi náà á yangàn.
19 Níbi tí ẹ “nírònú” dé, tayọ̀tayọ̀ lẹ̀ ń fara dà á fún àwọn aláìnírònú.
20 Kódà, ẹ̀ ń fara dà á fún ẹni tó bá mú yín lẹ́rú, ẹni tó bá gba ohun ìní yín, ẹni tó bá já nǹkan yín gbà, ẹni tó bá jẹ gàba lé yín lórí àti ẹni tó bá gbá yín lójú.
21 Ohun tí mò ń sọ yìí jẹ́ ìtìjú fún wa, torí ó lè dà bíi pé a jẹ́ aláìlera lójú yín.
Àmọ́ tí àwọn míì bá ń ṣàyà gbàǹgbà, mò ń sọ̀rọ̀ bí aláìnírònú, èmi náà á ṣàyà gbàǹgbà.
22 Ṣé Hébérù ni wọ́n? Hébérù lèmi náà.+ Ṣé ọmọ Ísírẹ́lì ni wọ́n? Ọmọ Ísírẹ́lì lèmi náà. Ṣé ọmọ* Ábúráhámù ni wọ́n? Ọmọ Ábúráhámù lèmi náà.+
23 Ṣé òjíṣẹ́ Kristi ni wọ́n? Mo fèsì bí ayírí, mo jẹ́ òjíṣẹ́ Kristi lọ́nà tó ta wọ́n yọ: mo ti ṣiṣẹ́ jù wọ́n lọ,+ wọ́n ti jù mí sẹ́wọ̀n lọ́pọ̀ ìgbà,+ wọ́n ti lù mí láìmọye ìgbà, ọ̀pọ̀ ìgbà sì ni ẹ̀mí mi ti fẹ́rẹ̀ẹ́ bọ́.+
24 Ìgbà márùn-ún ni àwọn Júù nà mí ní ẹgba mọ́kàndínlógójì (39),+
25 ìgbà mẹ́ta ni wọ́n ti fi ọ̀pá nà mí,+ wọ́n sọ mí lókùúta lẹ́ẹ̀kan,+ ìgbà mẹ́ta ni mo ti wọkọ̀ tó rì,+ mo sì ti lo ọ̀sán kan àti òru kan lórí agbami òkun;
26 nínú ìrìn àjò lọ́pọ̀ ìgbà, nínú ewu odò, nínú ewu dánàdánà, nínú ewu látọ̀dọ̀ àwọn èèyàn tèmi,+ nínú ewu látọ̀dọ̀ àwọn orílẹ̀-èdè,+ nínú ewu láàárín ìlú,+ nínú ewu láàárín aginjù, nínú ewu lójú òkun, nínú ewu láàárín àwọn èké arákùnrin,
27 nínú òpò* àti làálàá, nínú àìlèsùn lóru lọ́pọ̀ ìgbà,+ nínú ebi àti òùngbẹ,+ nínú àìsí oúnjẹ lọ́pọ̀ ìgbà,+ nínú òtútù àti àìrí aṣọ wọ̀.*
28 Yàtọ̀ sí àwọn nǹkan tó jẹ́ ti òde yìí, nǹkan míì tún wà tó ń rọ́ lù mí láti ọjọ́ dé ọjọ́:* àníyàn lórí gbogbo ìjọ.+
29 Ta ló jẹ́ aláìlera, témi náà ò di aláìlera? Ta ló kọsẹ̀, tí mi ò sì gbaná jẹ?
30 Tí mo bá tiẹ̀ máa yangàn, màá fi àwọn nǹkan tó fi hàn pé mo jẹ́ aláìlera yangàn.
31 Ọlọ́run àti Baba Jésù Olúwa, Ẹni tí àá máa yìn títí láé, mọ̀ pé mi ò parọ́.
32 Ní Damásíkù, gómìnà tó wà lábẹ́ Ọba Árétásì ń ṣọ́ ìlú àwọn ará Damásíkù kí ó lè gbá mi mú,
33 àmọ́ wọ́n fi apẹ̀rẹ̀* sọ̀ mí kalẹ̀ gba ojú fèrèsé* ara ògiri ìlú,+ mo sì bọ́ lọ́wọ́ rẹ̀.
Àlàyé Ìsàlẹ̀ Ìwé
^ Tàbí “mímọ́.”
^ Ní Grk., “pẹ̀lú ìtara Ọlọ́run.”
^ Tàbí “ìjẹ́mímọ́.”
^ Tàbí “ìtìlẹ́yìn.”
^ Ní Grk., “ja àwọn ìjọ míì lólè.”
^ Tàbí “àwáwí.”
^ Tàbí “ipò.”
^ Ìyẹn, lójú ti èèyàn.
^ Ní Grk., “èso.”
^ Tàbí “iṣẹ́ àṣekára.”
^ Ní Grk., “ìhòòhò.”
^ Tàbí “ìdààmú ń bá mi lójoojúmọ́.”
^ Tàbí “agbọ̀n.”
^ Tàbí “wíńdò.”