Ìwé Kejì sí Àwọn Ará Kọ́ríńtì 3:1-18

  • Lẹ́tà ìdámọ̀ràn (1-3)

  • Àwọn òjíṣẹ́ májẹ̀mú tuntun (4-6)

  • Ògo májẹ̀mú tuntun ta yọ (7-18)

3  Ṣé ká tún bẹ̀rẹ̀ sí í dámọ̀ràn ara wa ni? Àbí, ṣé a tún nílò lẹ́tà ìdámọ̀ràn sí yín tàbí látọ̀dọ̀ yín bíi ti àwọn kan ni?  Ẹ̀yin fúnra yín ni lẹ́tà wa,+ tí a kọ sára ọkàn wa, tí gbogbo aráyé mọ̀, tí wọ́n sì ń kà.  Nítorí ó ṣe kedere pé ẹ jẹ́ lẹ́tà Kristi tí àwa gẹ́gẹ́ bí òjíṣẹ́ kọ,+ kì í ṣe yíǹkì la fi kọ ọ́, ẹ̀mí Ọlọ́run alààyè ni, kì í sì í ṣe ara wàláà òkúta la kọ ọ́ sí,+ ara wàláà ti ẹran ara ni, ìyẹn sára ọkàn.+  A ní irú ìgbọ́kànlé yìí nínú Ọlọ́run nípasẹ̀ Kristi.  Kì í ṣe pé àwa fúnra wa kúnjú ìwọ̀n láti ṣe ohunkóhun, Ọlọ́run ló ń mú ká kúnjú ìwọ̀n,+  ẹni tó mú ká kúnjú ìwọ̀n lóòótọ́ láti jẹ́ òjíṣẹ́ májẹ̀mú tuntun kan,+ kì í ṣe ti àkọsílẹ̀ òfin,+ àmọ́ ó jẹ́ ti ẹ̀mí; torí àkọsílẹ̀ òfin ń dáni lẹ́bi ikú,+ àmọ́ ẹ̀mí ń sọni di ààyè.+  Ní báyìí, tí àkójọ òfin tó ń mú ikú wá, tí a fi àwọn lẹ́tà fín sára àwọn òkúta+ bá wá pẹ̀lú ògo tó pọ̀ débi pé àwọn ọmọ Ísírẹ́lì ò lè wo ojú Mósè nítorí ògo ojú rẹ̀,+ ògo tó jẹ́ pé ó máa dópin,  ṣé iṣẹ́ tí ẹ̀mí ń ṣe+ kò ní ní ògo tó pọ̀ ju bẹ́ẹ̀ lọ ni?+  Nítorí tí àkójọ òfin tó ń mú ìdálẹ́bi+ wá bá ní ògo,+ ǹjẹ́ iṣẹ́ tó ń mú ká pe àwọn èèyàn ní olódodo kò ní ní ògo tó jù bẹ́ẹ̀ lọ?+ 10  Kódà, èyí tí a ti ṣe lógo tẹ́lẹ̀ ti pàdánù ògo rẹ̀ nítorí ògo tó ju tirẹ̀ lọ.+ 11  Nítorí tí a bá mú èyí tó máa dópin wá pẹ̀lú ògo,+ ǹjẹ́ ògo èyí tí á máa wà nìṣó kò ní pọ̀ ju bẹ́ẹ̀ lọ?+ 12  Torí pé a ní irú ìrètí yìí,+ a lẹ́nu ọ̀rọ̀, 13  a kò sì ṣe bíi ti Mósè nígbà tó ń fi nǹkan bo ojú rẹ̀,+ kí àwọn ọmọ Ísírẹ́lì má bàa tẹjú mọ́ òpin ohun tó máa pa rẹ́. 14  Àmọ́ èrò inú wọn ò ṣiṣẹ́ dáadáa mọ́.+ Nítorí títí di òní yìí, a kò ká ìbòjú yẹn kúrò tí a bá ń ka májẹ̀mú láéláé,+ torí ipasẹ̀ Kristi nìkan la fi ń mú un kúrò.+ 15  Kódà, títí di òní, nígbàkigbà tí wọ́n bá ń ka ìwé Mósè,+ ìbòjú máa ń bo ọkàn wọn.+ 16  Àmọ́ nígbà tẹ́nì kan bá yíjú sí Jèhófà,* ìbòjú náà á ká kúrò.+ 17  Jèhófà* ni Ẹ̀mí náà,+ ibi tí ẹ̀mí Jèhófà* bá sì wà, òmìnira á wà níbẹ̀.+ 18  Bí a ṣe ń fi ojú tí a kò fi nǹkan bò gbé ògo Jèhófà* yọ bíi dígí, gbogbo wa ni à ń pa lára dà sí àwòrán kan náà láti ògo dé ògo, bí Jèhófà* tó jẹ́ Ẹ̀mí náà* ti ṣe gẹ́lẹ́.+

Àlàyé Ìsàlẹ̀ Ìwé

Tàbí kó jẹ́, “gẹ́gẹ́ bí ẹ̀mí Jèhófà.”