Ìwé Kejì sí Àwọn Ará Kọ́ríńtì 6:1-18

  • Kí a má ṣi inú rere Ọlọ́run lò (1, 2)

  • Bí iṣẹ́ òjíṣẹ́ Pọ́ọ̀lù ṣe rí (3-13)

  • Ẹ má fi àìdọ́gba so pọ̀ (14-18)

6  Bí a ṣe ń bá a ṣiṣẹ́,+ à ń rọ̀ yín pé kí ẹ má ṣe gba inú rere àìlẹ́tọ̀ọ́sí Ọlọ́run, kí ẹ sì pàdánù ohun tó wà fún.+  Nítorí ó sọ pé: “Ní àkókò ìtẹ́wọ́gbà, mo gbọ́ ọ̀rọ̀ rẹ, ní ọjọ́ ìgbàlà, mo ràn ọ́ lọ́wọ́.”+ Wò ó! Ìsinsìnyí gan-an ni àkókò ìtẹ́wọ́gbà. Wò ó! Ìsinsìnyí ni ọjọ́ ìgbàlà.  A ò ṣe ohun tó lè fa ìkọ̀sẹ̀ lọ́nàkọnà, kí iṣẹ́ òjíṣẹ́ wa má bàa ní àbùkù;+  àmọ́ ní gbogbo ọ̀nà, à ń dámọ̀ràn ara wa bí òjíṣẹ́ Ọlọ́run,+ nínú ọ̀pọ̀ ìfaradà, nínú ìpọ́njú, nínú àìní, nínú ìṣòro,+  nínú lílù, nínú ẹ̀wọ̀n,+ nínú rúkèrúdò, nínú iṣẹ́ àṣekára, nínú àìsùn, nínú àìrí oúnjẹ jẹ;+  nínú jíjẹ́ mímọ́, nínú ìmọ̀, nínú sùúrù,+ nínú inú rere,+ nínú ẹ̀mí mímọ́, nínú ìfẹ́ tí kò ní ẹ̀tàn,+  nínú ọ̀rọ̀ òtítọ́, nínú agbára Ọlọ́run;+ nípasẹ̀ àwọn ohun ìjà òdodo+ lọ́wọ́ ọ̀tún* àti lọ́wọ́ òsì,*  nínú ògo àti àbùkù, nínú ìròyìn burúkú àti ìròyìn rere. Wọ́n kà wá sí ẹlẹ́tàn, síbẹ̀ a jẹ́ olóòótọ́,  bí ẹni tí a kò mọ̀, síbẹ̀ a dá wa mọ̀, bí ẹni tó ń kú lọ,* síbẹ̀, wò ó! a wà láàyè,+ bí ẹni tí wọ́n fìyà jẹ,* síbẹ̀ a kò fà wá lé ikú lọ́wọ́,+ 10  bí ẹni tó ń kárí sọ àmọ́ à ń yọ̀ nígbà gbogbo, bí aláìní àmọ́ à ń sọ ọ̀pọ̀ di ọlọ́rọ̀, bí ẹni tí kò ní nǹkan kan, síbẹ̀ a ní ohun gbogbo.+ 11  A ti la ẹnu wa láti bá yín sọ̀rọ̀,* ẹ̀yin ará Kọ́ríńtì, a sì ti ṣí ọkàn wa sílẹ̀ pátápátá. 12  Ìfẹ́ tí a ní sí yín kò ní ààlà,*+ àmọ́ ẹ ti pààlà sí ìfẹ́ oníjẹ̀lẹ́ńkẹ́ tí ẹ ní sí wa. 13  Torí náà, mò ń bá yín sọ̀rọ̀ bí ẹni ń bá àwọn ọmọ mi sọ̀rọ̀, ẹ̀yin náà, ẹ ṣí ọkàn yín sílẹ̀ pátápátá.*+ 14  Ẹ má fi àìdọ́gba so pọ̀ pẹ̀lú* àwọn aláìgbàgbọ́.+ Nítorí àjọṣe wo ni òdodo àti ìwà tí kò bófin mu ní?+ Tàbí kí ló pa ìmọ́lẹ̀ àti òkùnkùn pọ̀?+ 15  Bákan náà, ìṣọ̀kan wo ló wà láàárín Kristi àti Bélíálì?*+ Àbí kí ló pa onígbàgbọ́* àti aláìgbàgbọ́ pọ̀?+ 16  Kí ló pa òrìṣà pọ̀ mọ́ tẹ́ńpìlì Ọlọ́run?+ Nítorí àwa jẹ́ tẹ́ńpìlì Ọlọ́run alààyè;+ bí Ọlọ́run ṣe sọ pé: “Èmi yóò máa gbé láàárín wọn,+ èmi yóò sì máa rìn láàárín wọn, èmi yóò jẹ́ Ọlọ́run wọn, wọn yóò sì di èèyàn mi.”+ 17  “‘Nítorí náà, ẹ jáde kúrò láàárín wọn, kí ẹ sì ya ara yín sọ́tọ̀,’ ni Jèhófà* wí, ‘ẹ má fọwọ́ kan ohun àìmọ́ mọ́’”;+ “‘màá sì gbà yín wọlé.’”+ 18  “‘Màá di bàbá yín,+ ẹ ó sì di ọmọkùnrin àti ọmọbìnrin mi,’+ ni Jèhófà,* Olódùmarè wí.”

Àlàyé Ìsàlẹ̀ Ìwé

Ó ṣeé ṣe kó jẹ́ fún ààbò.
Ó ṣeé ṣe kó jẹ́ fún ìjà.
Tàbí “ẹni tí wọ́n gbà pé ikú tọ́ sí.”
Tàbí “bá wí.”
Tàbí “A ti bá yín sọ òótọ́ ọ̀rọ̀.”
Tàbí “Àyè kò há mọ́ wa láti fìfẹ́ hàn sí yín.”
Tàbí “ẹ jẹ́ kí ìfẹ́ yín pọ̀ sí i.”
Tàbí “so mọ́.”
Tàbí “olóòótọ́.”
Látinú ọ̀rọ̀ Hébérù tó túmọ̀ sí “Tí Kò Dára fún Ohunkóhun.” Ó ń tọ́ka sí Sátánì.