Ìwé Kejì Pétérù 1:1-21
1 Símónì Pétérù, ẹrú àti àpọ́sítélì Jésù Kristi, sí ẹ̀yin tí ẹ ti ní irú ìgbàgbọ́ tó ṣeyebíye tí àwa náà ní,* nípasẹ̀ òdodo Ọlọ́run wa àti Jésù Kristi Olùgbàlà:
2 Kí ìmọ̀ tó péye + nípa Ọlọ́run àti Jésù Olúwa wa mú kí inú rere àìlẹ́tọ̀ọ́sí àti àlàáfíà pọ̀ sí i fún yín,
3 torí agbára rẹ̀ tó wá láti ọ̀run ti jẹ́ ká ní gbogbo ohun tó mú ká lè ní ìyè àti ìfọkànsìn Ọlọ́run* látinú ìmọ̀ tó péye nípa Ẹni tó fi ògo àti ìwà mímọ́ rẹ̀ pè wá.+
4 Àwọn nǹkan yìí ló fi jẹ́ ká ní àwọn ìlérí tó ṣeyebíye, tó sì jẹ́ àgbàyanu gan-an,*+ kí ẹ lè tipasẹ̀ wọn nípìn-ín nínú àwọn ohun ti ọ̀run,+ nígbà tí ẹ ti bọ́ lọ́wọ́ ìwà ìbàjẹ́ ayé tí ìfẹ́kúfẹ̀ẹ́* máa ń fà.
5 Nítorí èyí, ẹ sa gbogbo ipá yín+ láti fi ìwà mímọ́ kún ìgbàgbọ́ yín,+ ìmọ̀ kún ìwà mímọ́ yín,+
6 ìkóra-ẹni-níjàánu kún ìmọ̀ yín, ìfaradà kún ìkóra-ẹni-níjàánu yín,+ ìfọkànsin Ọlọ́run+ kún ìfaradà yín,
7 ìfẹ́ ará kún ìfọkànsin Ọlọ́run yín, ìfẹ́ kún ìfẹ́ ará yín.+
8 Torí bí àwọn nǹkan yìí bá wà nínú yín, tí ẹ sì ní wọn lọ́pọ̀lọpọ̀, wọn ò ní jẹ́ kí ẹ di aláìṣiṣẹ́ tàbí aláìléso+ ní ti ìmọ̀ tó péye nípa Olúwa wa Jésù Kristi.
9 Ẹnikẹ́ni tí kò bá ní àwọn nǹkan yìí jẹ́ afọ́jú, ó ti di ojú rẹ̀ sí ìmọ́lẹ̀,*+ ó sì ti gbàgbé pé a wẹ òun mọ́ kúrò nínú àwọn ẹ̀ṣẹ̀+ tó ti dá tipẹ́tipẹ́.
10 Torí náà, ẹ̀yin ará, ẹ túbọ̀ ṣe gbogbo ohun tí ẹ lè ṣe, kí pípè+ àti yíyàn yín lè dá yín lójú, torí tí ẹ bá ń ṣe àwọn nǹkan yìí, ẹ ò ní kùnà láé.+
11 Ní tòótọ́, èyí á mú kí ẹ wọlé fàlàlà* sínú Ìjọba ayérayé+ ti Olúwa àti Olùgbàlà wa Jésù Kristi.+
12 Ìdí nìyí tó fi wù mí kí n máa rán yín létí àwọn nǹkan yìí nígbà gbogbo, bí ẹ tiẹ̀ mọ̀ wọ́n, tí ẹ sì fẹsẹ̀ múlẹ̀ ṣinṣin nínú òtítọ́ tó wà nínú yín.
13 Àmọ́ mo rí i pé ó dáa, tí mo bá ṣì wà nínú àgọ́* yìí,+ láti máa rán yín létí kí n lè ta yín jí,+
14 bí mo ṣe mọ̀ pé màá tó bọ́ àgọ́ mi kúrò, bí Olúwa wa Jésù Kristi ṣe jẹ́ kí n mọ̀ kedere.+
15 Màá ṣe gbogbo ohun tí mo lè ṣe nígbà gbogbo, kó lè jẹ́ pé lẹ́yìn tí mo bá lọ, ẹ̀yin fúnra yín á lè rántí* àwọn nǹkan yìí.
16 Ó dájú pé kì í ṣe àwọn ìtàn èké tí a dọ́gbọ́n hùmọ̀ la tẹ̀ lé nígbà tí a jẹ́ kí ẹ mọ agbára Olúwa wa Jésù Kristi àti ìgbà tó máa wà níhìn-ín, àmọ́ a fi ojú ara wa rí ọlá ńlá rẹ̀.+
17 Torí ó gba ọlá àti ògo láti ọ̀dọ̀ Ọlọ́run tó jẹ́ Baba, nígbà tí ògo ọlá ńlá sọ irú ọ̀rọ̀ yìí fún un* pé: “Èyí ni Ọmọ mi, àyànfẹ́ mi, ẹni tí èmi fúnra mi tẹ́wọ́ gbà.”+
18 Àní, ọ̀rọ̀ yìí la gbọ́ láti ọ̀run nígbà tí a wà pẹ̀lú rẹ̀ ní òkè mímọ́.
19 Torí náà, a ní ọ̀rọ̀ àsọtẹ́lẹ̀ tí a mú kó túbọ̀ dá wa lójú, ẹ sì ń ṣe dáadáa bí ẹ ṣe ń fiyè sí i bíi fìtílà+ tó ń tàn níbi tó ṣókùnkùn (títí ilẹ̀ fi máa mọ́, tí ìràwọ̀ ojúmọ́+ sì máa yọ) nínú ọkàn yín.
20 Nítorí ẹ kọ́kọ́ mọ̀ pé, kò sí àsọtẹ́lẹ̀ kankan nínú Ìwé Mímọ́ tó wá látinú èrò* ara ẹni èyíkéyìí.
21 Torí a ò fìgbà kankan rí mú àsọtẹ́lẹ̀ wá nípasẹ̀ ìfẹ́ èèyàn,+ àmọ́ àwọn èèyàn sọ̀rọ̀ látọ̀dọ̀ Ọlọ́run bí ẹ̀mí mímọ́ ṣe darí wọn.*+
Àlàyé Ìsàlẹ̀ Ìwé
^ Tàbí “ìgbàgbọ́ tí àǹfààní rẹ̀ dọ́gba pẹ̀lú tiwa.”
^ Tàbí “ti fún wa ní gbogbo ohun tó mú ká lè ní ìyè àti ìfọkànsìn Ọlọ́run lọ́fẹ̀ẹ́.”
^ Tàbí “fi fún wa ní àwọn ìlérí tó ṣeyebíye, tó sì jẹ́ àgbàyanu lọ́fẹ̀ẹ́.”
^ Tàbí “ìfẹ́ ọkàn.”
^ Tàbí kó jẹ́, “ó ti fọ́jú, kò ríran jìnnà.”
^ Tàbí “ní ọ̀pọ̀ rẹpẹtẹ àǹfààní láti wọlé.”
^ Ìyẹn, ara tó ní lórí ilẹ̀ ayé.
^ Tàbí “sọ̀rọ̀ nípa.”
^ Ní Grk., “jẹ́ kó gbọ́ irú ohùn yìí.”
^ Tàbí “ìtúmọ̀.”
^ Ní Grk., “sún wọn; mú kí wọ́n gba ìmísí.”