Ìwé Kejì Pétérù 3:1-18
3 Ẹ̀yin ará mi ọ̀wọ́n, lẹ́tà kejì tí màá kọ sí yín nìyí, bíi ti àkọ́kọ́, mò ń rán yín létí kí n lè ta yín jí láti ronú jinlẹ̀,+
2 kí ẹ máa rántí àwọn ọ̀rọ̀ tí àwọn wòlíì mímọ́ ti sọ ṣáájú* àti àṣẹ Olúwa àti Olùgbàlà nípasẹ̀ àwọn àpọ́sítélì yín.
3 Lákọ̀ọ́kọ́, kí ẹ mọ̀ pé ní àwọn ọjọ́ ìkẹyìn àwọn tó ń fini ṣẹlẹ́yà máa wá, wọ́n á máa fini ṣẹlẹ́yà, wọ́n á máa ṣe ìfẹ́kúfẹ̀ẹ́ ara wọn,+
4 wọ́n á máa sọ pé: “Ṣebí ó ṣèlérí pé òun máa wà níhìn-ín, òun wá dà?+ Ó ṣe tán, bí nǹkan ṣe rí gẹ́lẹ́ láti ọjọ́ tí àwọn baba ńlá wa ti sùn nínú ikú, bẹ́ẹ̀ náà ló rí láti ìbẹ̀rẹ̀ ìṣẹ̀dá.”+
5 Torí wọ́n mọ̀ọ́mọ̀ gbójú fo òótọ́ ọ̀rọ̀ yìí, pé nígbà àtijọ́ ọ̀rọ̀ Ọlọ́run mú kí ọ̀run àti ayé dúró digbí látinú omi, kí ó sì wà láàárín omi;+
6 ìyẹn la sì fi pa ayé ìgbà yẹn run nígbà tí ìkún omi bò ó mọ́lẹ̀.+
7 Ọ̀rọ̀ yẹn kan náà la fi tọ́jú àwọn ọ̀run àti ayé tó wà báyìí pa mọ́ de iná, a sì ń fi wọ́n pa mọ́ de ọjọ́ ìdájọ́ àti ti ìparun àwọn èèyàn tí kò ṣe ìfẹ́ Ọlọ́run.+
8 Síbẹ̀, ẹ̀yin ará mi ọ̀wọ́n, ẹ má gbàgbé pé lójú Jèhófà* ọjọ́ kan dà bí ẹgbẹ̀rún ọdún àti pé ẹgbẹ̀rún ọdún dà bí ọjọ́ kan.+
9 Jèhófà* kò fi ìlérí rẹ̀ falẹ̀,+ bí àwọn èèyàn kan ṣe rò pé ó ń fi falẹ̀, àmọ́ ó ń mú sùúrù fún yín torí kò fẹ́ kí ẹnikẹ́ni pa run ṣùgbọ́n ó fẹ́ kí gbogbo èèyàn ronú pìwà dà.+
10 Àmọ́ ọjọ́ Jèhófà*+ máa dé bí olè,+ nígbà yẹn àwọn ọ̀run máa kọjá lọ+ pẹ̀lú ariwo tó rinlẹ̀,* àmọ́ àwọn ohun ìpìlẹ̀ tó gbóná janjan máa yọ́, a sì máa tú ayé àti àwọn iṣẹ́ tó wà nínú rẹ̀ síta.+
11 Bí gbogbo nǹkan yìí ṣe máa yọ́ báyìí, ẹ ronú nípa irú ẹni tó yẹ kí ẹ jẹ́ nínú ìwà mímọ́ àti àwọn iṣẹ́ ìfọkànsin Ọlọ́run,
12 bí ẹ ti ń dúró de ìgbà tí ọjọ́ Jèhófà*+ máa wà níhìn-ín, tí ẹ sì ń fi í sọ́kàn dáadáa,* nípasẹ̀ èyí tí àwọn ọ̀run máa pa run + nínú iná, tí àwọn ohun ìpìlẹ̀ máa yọ́ nítorí ooru tó gbóná janjan!
13 Àmọ́ à ń retí ọ̀run tuntun àti ayé tuntun tó ṣèlérí,+ níbi tí òdodo á máa gbé.+
14 Nítorí náà, ẹ̀yin ará mi ọ̀wọ́n, bí ẹ ṣe ń retí àwọn nǹkan yìí, ẹ sa gbogbo ipá yín kó lè bá yín nígbẹ̀yìn-gbẹ́yín láìní èérí àti àbààwọ́n àti ní àlàáfíà.+
15 Bákan náà, ẹ ka sùúrù Olúwa wa sí ìgbàlà, bí Pọ́ọ̀lù arákùnrin wa ọ̀wọ́n náà ṣe lo ọgbọ́n tí Ọlọ́run fún un láti kọ̀wé sí yín,+
16 ó sọ̀rọ̀ nípa àwọn nǹkan yìí bó ti ṣe nínú gbogbo lẹ́tà rẹ̀. Àmọ́ àwọn nǹkan kan nínú wọn ṣòroó lóye, àwọn nǹkan yìí sì ni àwọn aláìmọ̀kan* àti àwọn tí kò dúró ṣinṣin ń lọ́ po sí ìparun ara wọn, bí wọ́n ti ń ṣe sí àwọn ibi yòókù nínú Ìwé Mímọ́.
17 Torí náà, ẹ̀yin ará mi ọ̀wọ́n, bí ẹ ṣe mọ àwọn nǹkan yìí tẹ́lẹ̀, ẹ máa ṣọ́ra yín kí àṣìṣe àwọn arúfin má bàa ṣì yín lọ́nà pẹ̀lú wọn, tí ẹ ò sì ní dúró ṣinṣin* mọ́.+
18 Àmọ́ ẹ túbọ̀ máa dàgbà nínú inú rere àìlẹ́tọ̀ọ́sí àti ìmọ̀ nípa Olúwa àti Olùgbàlà wa Jésù Kristi. Òun ni kí ògo jẹ́ tirẹ̀ báyìí àti títí láé. Àmín.
Àlàyé Ìsàlẹ̀ Ìwé
^ Tàbí “ti sọ tẹ́lẹ̀.”
^ Wo Àfikún A5.
^ Wo Àfikún A5.
^ Tàbí “ariwo tó ń yára kọjá lọ.”
^ Wo Àfikún A5.
^ Wo Àfikún A5.
^ Tàbí “tó sì ń wù yín gidigidi.” Ní Grk., “tí ẹ sì ń fẹ́ kó yára kánkán.”
^ Tàbí “aláìlẹ́kọ̀ọ́.”
^ Tàbí “fẹsẹ̀ múlẹ̀.”