Sámúẹ́lì Kejì 1:1-27

  • Dáfídì gbọ́ nípa ikú Sọ́ọ̀lù (1-16)

  • Orin arò tí Dáfídì kọ nítorí Sọ́ọ̀lù àti Jónátánì (17-27)

1  Lẹ́yìn ikú Sọ́ọ̀lù, nígbà tí Dáfídì dé láti ibi tí ó ti lọ ṣẹ́gun* àwọn ọmọ Ámálékì, Dáfídì dúró sí Síkílágì+ fún ọjọ́ méjì.  Ní ọjọ́ kẹta, ọkùnrin kan wá láti ibùdó Sọ́ọ̀lù, aṣọ rẹ̀ ti ya, iyẹ̀pẹ̀ sì wà lórí rẹ̀. Nígbà tí ó wá sọ́dọ̀ Dáfídì, ó wólẹ̀, ó sì dọ̀bálẹ̀.  Dáfídì béèrè lọ́wọ́ rẹ̀ pé: “Ibo lo ti ń bọ̀?” Ó dáhùn pé: “Ibùdó Ísírẹ́lì ni mo ti sá wá.”  Dáfídì sì béèrè lọ́wọ́ rẹ̀ pé: “Báwo ni ọ̀hún ṣe rí? Jọ̀ọ́, sọ fún mi.” Ó dáhùn pé: “Àwọn èèyàn ti sá kúrò lójú ogun, ọ̀pọ̀ ló ti ṣubú tí wọ́n sì ti kú. Kódà Sọ́ọ̀lù àti Jónátánì ọmọ rẹ̀ ti kú.”+  Dáfídì bá béèrè lọ́wọ́ ọ̀dọ́kùnrin tí ó wá ròyìn fún un pé: “Báwo lo ṣe mọ̀ pé Sọ́ọ̀lù àti Jónátánì ọmọ rẹ̀ ti kú?”  Ọ̀dọ́kùnrin náà fèsì pé: “Ó ṣẹlẹ̀ pé mo wà ní orí Òkè Gíbóà,+ ni mo bá rí Sọ́ọ̀lù tó fi ara ti ọ̀kọ̀ rẹ̀, àwọn tó ń gun kẹ̀kẹ́ ogun àti àwọn agẹṣin sì ti ká a mọ́.+  Nígbà tí ó bojú wẹ̀yìn, tí ó rí mi, ó pè mí, mo sì sọ pé, ‘Èmi nìyí!’  Ó béèrè lọ́wọ́ mi pé, ‘Ta ni ọ́?’ Mo dá a lóhùn pé, ‘Ọmọ Ámálékì+ ni mí.’  Ni ó bá sọ pé, ‘Jọ̀wọ́, dúró lẹ́gbẹ̀ẹ́ mi, kí o sì pa mí, nítorí mò ń jẹ̀rora gan-an, àmọ́ mo ṣì wà láàyè.’* 10  Torí náà, mo dúró lẹ́gbẹ̀ẹ́ rẹ̀, mo sì pa á,+ nítorí mo mọ̀ pé kò lè yè é lẹ́yìn tí ó ti fara gbọgbẹ́ tí ó sì ti ṣubú. Lẹ́yìn náà, mo ṣí adé* orí rẹ̀, mo sì bọ́ ẹ̀gbà tó wà ní apá rẹ̀, mo sì kó wọn wá fún olúwa mi.” 11  Ni Dáfídì bá di ẹ̀wù ara rẹ̀ mú, ó sì fà á ya, gbogbo àwọn ọkùnrin tí ó wà pẹ̀lú rẹ̀ náà sì ṣe bẹ́ẹ̀. 12  Wọ́n pohùn réré ẹkún, wọ́n sunkún, wọ́n sì gbààwẹ̀+ títí di ìrọ̀lẹ́ nítorí Sọ́ọ̀lù àti Jónátánì ọmọ rẹ̀ àti nítorí àwọn èèyàn Jèhófà àti ilé Ísírẹ́lì+ torí pé wọ́n ti fi idà pa wọ́n. 13  Dáfídì béèrè lọ́wọ́ ọ̀dọ́kùnrin tó wá ròyìn fún un pé: “Ibo lo ti wá?” Ó sọ pé: “Ọmọ Ámálékì ni bàbá mi, àjèjì ni nílẹ̀ Ísírẹ́lì.” 14  Ìgbà náà ni Dáfídì sọ fún un pé: “Kí ló dé tí ẹ̀rù ò fi bà ọ́ láti gbé ọwọ́ rẹ sókè láti pa ẹni àmì òróró Jèhófà?”+ 15  Dáfídì bá pe ọ̀kan lára àwọn ọ̀dọ́kùnrin rẹ̀, ó sì sọ pé: “Bọ́ síwájú, kí o sì ṣá a balẹ̀.” Torí náà, ó ṣá a balẹ̀, ó sì kú.+ 16  Dáfídì sọ fún un pé: “Ẹ̀jẹ̀ rẹ wà ní orí ìwọ fúnra rẹ, nítorí ẹnu rẹ ló kó bá ọ, bí o ṣe sọ pé, ‘Èmi ni mo pa ẹni àmì òróró Jèhófà.’”+ 17  Dáfídì wá kọ orin arò* yìí nítorí Sọ́ọ̀lù àti Jónátánì ọmọ rẹ̀,+ 18  ó sì ní kí wọ́n kọ́ àwọn èèyàn Júdà ní orin arò tí wọ́n pè ní “Ọrun,” tó wà lákọsílẹ̀ nínú ìwé Jáṣárì:+ 19  “Ìwọ Ísírẹ́lì, wọ́n ti pa ẹwà lórí àwọn ibi gíga rẹ.+ Wo bí àwọn alágbára ṣe ṣubú! 20  Ẹ má sọ ọ́ ní Gátì;+Ẹ má ṣe kéde rẹ̀ ní àwọn ojú ọ̀nà Áṣíkẹ́lónì,Kí àwọn ọmọbìnrin Filísínì má bàa yọ̀,Kí àwọn ọmọbìnrin àwọn aláìdádọ̀dọ́* má bàa dunnú. 21  Ẹ̀yin òkè Gíbóà,+Kí ìrì má sẹ̀, kí òjò má sì rọ̀ sórí yín,Bẹ́ẹ̀ ni kí pápá má ṣe mú ọrẹ mímọ́+ jáde,Nítorí pé ibẹ̀ ni wọ́n ti sọ apata àwọn alágbára di aláìmọ́,A kò sì fi òróró pa apata Sọ́ọ̀lù mọ́. 22  Ọrun Jónátánì+ àti idà Sọ́ọ̀lù+Ti rẹ nínú ẹ̀jẹ̀ àwọn ọ̀tá, ó sì ti gún ọ̀rá àwọn jagunjagun,Wọn kì í tàsé. 23  Sọ́ọ̀lù àti Jónátánì,+ àwọn ẹni ọ̀wọ́n àti àyànfẹ́* nígbà ayé wọn,A kò sì pín wọn níyà nígbà ikú wọn.+ Wọ́n yára ju ẹyẹ idì lọ,+Wọ́n lágbára ju kìnnìún lọ.+ 24  Ẹ̀yin ọmọbìnrin Ísírẹ́lì, ẹ sunkún nítorí Sọ́ọ̀lù,Ẹni tí ó fi aṣọ rírẹ̀dòdò àti ohun ọ̀ṣọ́ wọ̀ yín,Ẹni tí ó fi ohun ọ̀ṣọ́ wúrà sára aṣọ yín. 25  Wo bí àwọn alágbára ṣe ṣubú lójú ogun! Wọ́n ti pa Jónátánì sílẹ̀ lórí ibi gíga!+ 26  Ẹ̀dùn ọkàn bá mi nítorí rẹ, Jónátánì arákùnrin mi;Ẹni ọ̀wọ́n lo jẹ́ sí mi.+ Ìfẹ́ tí o ní sí mi lágbára ju ti obìnrin lọ.+ 27  Wo bí àwọn alágbára ṣe ṣubúTí àwọn ohun ìjà sì ṣègbé!”

Àlàyé Ìsàlẹ̀ Ìwé

Tàbí “pa.”
Tàbí “ẹ̀mí mi kò tíì bọ́.”
Tàbí “dáyádémà.”
Tàbí “ọ̀fọ̀.”
Tàbí “aláìkọlà.”
Tàbí “ẹni àrídunnú.”