Sámúẹ́lì Kejì 21:1-22

  • Àwọn ará Gíbíónì gbẹ̀san lára ilé Sọ́ọ̀lù (1-14)

  • Àwọn ogun tó wáyé láàárín àwọn ọmọ Ísírẹ́lì àti àwọn Filísínì (15-22)

21  Ìyàn+ kan mú nígbà ayé Dáfídì, ọdún mẹ́ta tẹ̀ léra ló sì fi mú. Nítorí náà Dáfídì wádìí lọ́dọ̀ Jèhófà, Jèhófà sì sọ pé: “Ẹ̀bi ẹ̀jẹ̀ wà lórí Sọ́ọ̀lù àti lórí ilé rẹ̀, nítorí ó pa àwọn ará Gíbíónì.”+  Torí náà, ọba pe àwọn ará Gíbíónì,+ ó sì bá wọn sọ̀rọ̀. (Àwọn ará Gíbíónì kì í ṣe ara àwọn ọmọ Ísírẹ́lì, wọ́n jẹ́ àwọn Ámórì+ tó ṣẹ́ kù, àwọn ọmọ Ísírẹ́lì sì ti búra pé àwọn máa dá wọn sí,+ àmọ́ Sọ́ọ̀lù wá ọ̀nà títí ó fi pa wọ́n nítorí ìtara tó ní fún àwọn èèyàn Ísírẹ́lì àti Júdà lọ́nà òdì.)  Dáfídì sọ fún àwọn ará Gíbíónì pé: “Kí ni kí n ṣe fún yín, ètùtù wo sì ni kí n ṣe, kí ẹ lè súre fún àwọn èèyàn* Jèhófà?”  Àwọn ará Gíbíónì sọ fún un pé: “Ọ̀rọ̀ tó wà láàárín àwa àti Sọ́ọ̀lù pẹ̀lú agbo ilé rẹ̀ kì í ṣe ọ̀rọ̀ fàdákà tàbí wúrà;+ bẹ́ẹ̀ ni a kò lè pa ẹnikẹ́ni ní Ísírẹ́lì.” Ni ó bá sọ pé: “Ohunkóhun tí ẹ bá sọ ni màá ṣe fún yín.”  Wọ́n sọ fún ọba pé: “Ọkùnrin tí ó pa wá run, tí ó sì gbìmọ̀ láti pa wá rẹ́ kí a má bàa ṣẹ́ kù síbikíbi ní ilẹ̀ Ísírẹ́lì,+  òun gan-an ni kí o fún wa ní méje lára àwọn ọmọkùnrin rẹ̀. A ó sì gbé òkú wọn kọ́*+ níwájú Jèhófà ní Gíbíà+ ti Sọ́ọ̀lù, ẹni tí Jèhófà yàn.”+ Ni Ọba bá sọ pé: “Màá fi wọ́n lé yín lọ́wọ́.”  Àmọ́ ṣá, ọba ṣàánú Méfíbóṣétì+ ọmọ Jónátánì ọmọ Sọ́ọ̀lù nítorí ìbúra tó wáyé níwájú Jèhófà láàárín Dáfídì àti Jónátánì+ ọmọ Sọ́ọ̀lù.  Nítorí náà, ọba mú àwọn ọmọkùnrin méjèèjì tí Rísípà+ ọmọ Áyà bí fún Sọ́ọ̀lù, ìyẹn, Árímónì àti Méfíbóṣétì, ó tún mú àwọn ọmọkùnrin márààrún tí Míkálì*+ ọmọ Sọ́ọ̀lù bí fún Ádíríélì+ ọmọ Básíláì ará Méhólà.  Ó fi wọ́n lé àwọn ará Gíbíónì lọ́wọ́, wọ́n sì gbé òkú wọn kọ́ sórí òkè níwájú Jèhófà.+ Àwọn méjèèje ló kú pa pọ̀, ọjọ́ àkọ́kọ́ ìkórè ni wọ́n pa wọ́n, ní ìbẹ̀rẹ̀ ìkórè ọkà bálì. 10  Lẹ́yìn náà, Rísípà+ ọmọ Áyà mú aṣọ ọ̀fọ̀,* ó sì tẹ́ ẹ sórí àpáta, ó wà níbẹ̀ láti ìbẹ̀rẹ̀ ìkórè títí òjò fi rọ̀ láti ọ̀run sórí àwọn òkú náà; kò jẹ́ kí àwọn ẹyẹ ojú ọ̀run bà lé wọn ní ọ̀sán tàbí kí àwọn ẹran inú igbó sún mọ́ wọn ní òru. 11  Wọ́n sọ fún Dáfídì nípa ohun tí Rísípà ọmọ Áyà ṣe, ìyẹn wáhàrì* Sọ́ọ̀lù. 12  Torí náà, Dáfídì lọ kó egungun Sọ́ọ̀lù àti egungun Jónátánì ọmọ rẹ̀ kúrò lọ́dọ̀ àwọn aṣáájú* Jabeṣi-gílíádì+ tí wọ́n jí egungun náà kó ní ojúde ìlú Bẹti-ṣánì, níbi tí àwọn Filísínì gbé wọn kọ́ sí ní ọjọ́ tí àwọn Filísínì pa Sọ́ọ̀lù ní Gíbóà.+ 13  Ó kó egungun Sọ́ọ̀lù àti egungun Jónátánì ọmọ rẹ̀ wá láti ibẹ̀, wọ́n tún kó egungun àwọn ọkùnrin tí a ti pa* jọ.+ 14  Lẹ́yìn náà, wọ́n sin egungun Sọ́ọ̀lù àti ti Jónátánì ọmọ rẹ̀ sí ilẹ̀ Bẹ́ńjámínì ní Sẹ́là+ ní ibi tí wọ́n sin Kíṣì+ bàbá rẹ̀ sí. Lẹ́yìn tí wọ́n ṣe gbogbo ohun tí ọba pa láṣẹ, Ọlọ́run gbọ́ ẹ̀bẹ̀ wọn lórí ilẹ̀ náà.+ 15  Lẹ́ẹ̀kan sí i, ogun wáyé láàárín àwọn Filísínì àti Ísírẹ́lì.+ Nítorí náà, Dáfídì àti àwọn ìránṣẹ́ rẹ̀ lọ bá àwọn Filísínì jà, àmọ́ àárẹ̀ mú Dáfídì. 16  Ọ̀kan lára àwọn àtọmọdọ́mọ Réfáímù,+ tó ń jẹ́ Iṣibi-bénóbù, tí ìwọ̀n ọ̀kọ̀ rẹ̀ jẹ́ ọgọ́rùn-ún mẹ́ta (300) ṣékélì*+ bàbà, mú idà tuntun lọ́wọ́, ó fẹ́ ṣá Dáfídì balẹ̀. 17  Ní kíá, Ábíṣáì+ ọmọ Seruáyà wá ràn án lọ́wọ́,+ ó ṣá Filísínì náà balẹ̀, ó sì pa á. Nígbà náà, àwọn ọkùnrin Dáfídì búra fún un pé: “O ò gbọ́dọ̀ bá wa lọ sójú ogun mọ́!+ Má ṣe jẹ́ kí iná Ísírẹ́lì kú!”+ 18  Lẹ́yìn èyí, wọ́n tún bá àwọn Filísínì+ jà ní Góbù. Ìgbà yẹn ni Síbékáì+ ọmọ Húṣà pa Sáfì tó jẹ́ ọ̀kan lára àwọn àtọmọdọ́mọ Réfáímù.+ 19  Wọ́n tún bá àwọn Filísínì jà+ ní Góbù, Élíhánánì ọmọ Jaare-órégímù ará Bẹ́tílẹ́hẹ́mù sì pa Gòláyátì ará Gátì, ẹni tí igi ọ̀kọ̀ rẹ̀ dà bí ọ̀pá àwọn ahunṣọ.*+ 20  Ogun tún wáyé ní Gátì, níbi tí ọkùnrin kan wà tí ó tóbi fàkìàfakia, ó ní ìka mẹ́fà-mẹ́fà ní ọwọ́ àti ní ẹsẹ̀, gbogbo wọn jẹ́ mẹ́rìnlélógún (24); òun náà sì wà lára àwọn àtọmọdọ́mọ Réfáímù.+ 21  Ó ń pẹ̀gàn Ísírẹ́lì.+ Torí náà, Jónátánì ọmọ Ṣíméì,+ ẹ̀gbọ́n Dáfídì, pa á. 22  Àwọn mẹ́rẹ̀ẹ̀rin yìí jẹ́ àtọmọdọ́mọ Réfáímù ní Gátì, Dáfídì àti àwọn ìránṣẹ́ rẹ̀ ló sì pa wọ́n.+

Àlàyé Ìsàlẹ̀ Ìwé

Ní Héb., “ogún.”
Ní Héb., “gbé wọn síta,” ìyẹn ni pé wọ́n á dá apá àti ẹsẹ̀ wọn.
Tàbí kó jẹ́, “Mérábù.”
Ní Héb., “aṣọ àpò ìdọ̀họ.”
Tàbí “ìyàwó onípò kejì.” Wo Àlàyé Ọ̀rọ̀, “Wáhàrì.”
Tàbí kó jẹ́, “onílẹ̀.”
Ní Héb., “gbé síta.”
Nǹkan bíi kìlógíráàmù 3.42. Wo Àfikún B14.
Tàbí “olófì.”