Ìwé Kejì sí Tímótì 4:1-22
4 Mo pàṣẹ tó rinlẹ̀ yìí fún ọ níwájú Ọlọ́run àti Kristi Jésù, ẹni tó máa ṣèdájọ́+ àwọn alààyè àti òkú,+ nípasẹ̀ ìfarahàn rẹ̀+ àti Ìjọba rẹ̀:+
2 Wàásù ọ̀rọ̀ náà;+ máa ṣe bẹ́ẹ̀ láìfi falẹ̀ ní àkókò tó rọrùn àti ní àkókò tí kò rọrùn; máa báni wí,+ máa fi ìbáwí tọ́ni sọ́nà, máa gbani níyànjú, pẹ̀lú ọ̀pọ̀ sùúrù àti ọ̀nà ìkọ́nilẹ́kọ̀ọ́ tó dáa.*+
3 Torí ìgbà kan ń bọ̀ tí wọn ò ní tẹ̀ lé ẹ̀kọ́ tó ṣàǹfààní,*+ àmọ́ wọ́n á máa ṣe ìfẹ́ inú ara wọn, wọ́n á fi àwọn olùkọ́ yí ara wọn ká, kí wọ́n lè máa sọ ohun tí wọ́n fẹ́ gbọ́.*+
4 Wọn ò ní fetí sí òtítọ́ mọ́, ìtàn èké ni wọ́n á máa fetí sí.
5 Àmọ́, kí ìwọ máa ronú bó ṣe tọ́ nínú ohun gbogbo, fara da ìnira,+ ṣe iṣẹ́ ajíhìnrere,* ṣe iṣẹ́ òjíṣẹ́ rẹ láìkù síbì kan.+
6 Torí ní báyìí, a ti ń tú mi jáde bí ọrẹ ohun mímu,+ a sì máa tó tú mi sílẹ̀.+
7 Mo ti ja ìjà rere náà,+ mo ti sá eré ìje náà dé ìparí,+ mo ti pa ìgbàgbọ́ mọ́.
8 Láti ìsinsìnyí lọ, a ti fi adé òdodo + pa mọ́ dè mí, èyí tí Olúwa, onídàájọ́ òdodo,+ máa fi san mí lẹ́san ní ọjọ́ yẹn,+ síbẹ̀ kì í ṣe fún èmi nìkan, àmọ́ fún gbogbo àwọn tó nífẹ̀ẹ́ ìfarahàn rẹ̀.
9 Sa gbogbo ipá rẹ láti wá sọ́dọ̀ mi láìpẹ́.
10 Ìdí ni pé Démà+ ti pa mí tì torí ó nífẹ̀ẹ́ ètò àwọn nǹkan yìí,* ó sì ti lọ sí Tẹsalóníkà, Kírẹ́sẹ́ńsì ti lọ sí Gálátíà, Títù sì ti lọ sí Damatíà.
11 Lúùkù nìkan ló wà lọ́dọ̀ mi. Mú Máàkù dání tí o bá ń bọ̀, torí ó ń ràn mí lọ́wọ́ lẹ́nu iṣẹ́ òjíṣẹ́.
12 Àmọ́ mo ti rán Tíkíkù+ lọ sí Éfésù.
13 Tí o bá ń bọ̀, bá mi mú aṣọ àwọ̀lékè tí mo fi sílẹ̀ ní Tíróásì lọ́dọ̀ Kápọ́sì dání àti àwọn àkájọ ìwé, ní pàtàkì àwọn ìwé awọ.*
14 Alẹkisáńdà alágbẹ̀dẹ bàbà fi ojú mi rí màbo. Jèhófà* máa fi iṣẹ́ ọwọ́ rẹ̀ san án lẹ́san.+
15 Kí ìwọ náà máa ṣọ́ra fún un, torí ó ń ta ko ọ̀rọ̀ wa gan-an.
16 Nígbà tí mo kọ́kọ́ lọ jẹ́jọ́, ẹnì kankan ò wá gbèjà mi, ṣe ni gbogbo wọn pa mí tì—kí a má ṣe kà á sí wọn lọ́rùn.
17 Àmọ́ Olúwa dúró tì mí, ó sì fún mi lágbára, ká lè lò mí láti ṣe iṣẹ́ ìwàásù láìkù síbì kan, kí gbogbo orílẹ̀-èdè lè gbọ́ ọ;+ ó sì gbà mí kúrò lẹ́nu kìnnìún.+
18 Olúwa máa gbà mí lọ́wọ́ gbogbo iṣẹ́ burúkú, ó sì máa pa mí mọ́ kí n lè wọ ìjọba rẹ̀ ní ọ̀run.+ Òun ni kí ògo jẹ́ tirẹ̀ títí láé àti láéláé. Àmín.
19 Bá mi kí Pírísíkà àti Ákúílà+ àti agbo ilé Ónẹ́sífórù.+
20 Érásítù+ dúró sí Kọ́ríńtì, àmọ́ mo fi Tírófímù+ sílẹ̀ ní Mílétù, ara rẹ̀ ò yá.
21 Sa gbogbo ipá rẹ kí o lè dé kí ìgbà òtútù tó bẹ̀rẹ̀.
Yúbúlọ́sì ní kí n kí ọ, Púdéńsì àti Línúsì àti Kíláúdíà àti gbogbo àwọn ará pẹ̀lú ní kí n kí ọ.
22 Kí Olúwa wà pẹ̀lú ẹ̀mí tí o fi hàn. Kí inú rere àìlẹ́tọ̀ọ́sí rẹ̀ wà pẹ̀lú rẹ.
Àlàyé Ìsàlẹ̀ Ìwé
^ Ní Grk., “kí o sì máa lo ọnà ìkọ́nilẹ́kọ̀ọ́.”
^ Tàbí “tó ṣeni lóore; tó wúlò.”
^ Ní Grk., “kí wọ́n lè máa rin wọ́n ní etí.”
^ Tàbí “máa wàásù ìhìn rere náà.”
^ Tàbí “àsìkò yìí.” Wo Àlàyé Ọ̀rọ̀.
^ Ìyẹn, àwọn àkájọ ìwé tí wọ́n fi awọ ṣe.