Dáníẹ́lì 4:1-37
4 “Ọba Nebukadinésárì kéde fún gbogbo èèyàn, orílẹ̀-èdè àti ẹ̀yà tó ń gbé ní gbogbo ayé pé: Kí àlàáfíà yín pọ̀ sí i!
2 Inú mi dùn láti kéde àwọn iṣẹ́ àmì àti iṣẹ́ ìyanu tí Ọlọ́run Gíga Jù Lọ ti ṣe fún mi.
3 Ẹ wo bí àwọn iṣẹ́ àmì rẹ̀ ṣe tóbi tó àti bí àwọn iṣẹ́ ìyanu rẹ̀ ṣe lágbára tó! Ìjọba tó wà títí láé ni ìjọba rẹ̀, àkóso rẹ̀ sì wà láti ìran dé ìran.+
4 “Èmi Nebukadinésárì wà nínú ilé mi, ọkàn mi balẹ̀, nǹkan sì ń lọ dáadáa fún mi ní ààfin mi.
5 Mo lá àlá kan tó dẹ́rù bà mí. Bí mo ṣe dùbúlẹ̀ sórí ibùsùn mi, àwọn àwòrán àti ìran tí mo rí dáyà já mi.+
6 Mo wá pàṣẹ pé kí wọ́n kó gbogbo àwọn amòye Bábílónì wá síwájú mi, kí wọ́n lè sọ ìtumọ̀ àlá náà fún mi.+
7 “Ìgbà yẹn ni àwọn àlùfáà onídán, àwọn pidánpidán, àwọn ará Kálídíà* àti àwọn awòràwọ̀+ wọlé wá. Nígbà tí mo rọ́ àlá náà fún wọn, wọn ò lè sọ ìtumọ̀ rẹ̀ fún mi.+
8 Nígbẹ̀yìn-gbẹ́yín, Dáníẹ́lì wá síwájú mi, ẹni tí orúkọ rẹ̀ ń jẹ́ Bẹtiṣásárì,+ látinú orúkọ ọlọ́run mi,+ ẹni tí ẹ̀mí àwọn ọlọ́run mímọ́ + wà nínú rẹ̀, mo sì rọ́ àlá náà fún un:
9 “‘Bẹtiṣásárì, olórí àwọn àlùfáà onídán,+ ó dá mi lójú pé ẹ̀mí àwọn ọlọ́run mímọ́ wà nínú rẹ,+ kò sì sí àṣírí kankan tó le jù fún ọ.+ Torí náà, ṣàlàyé ìran tí mo rí lójú àlá mi fún mi àti ohun tó túmọ̀ sí.
10 “‘Nínú ìran tí mo rí nígbà tí mo wà lórí ibùsùn mi, mo rí igi kan+ ní àárín ayé, igi náà sì ga fíofío.+
11 Igi náà dàgbà, ó sì lágbára, orí rẹ̀ kan ọ̀run, a sì lè rí i láti gbogbo ìkángun ayé.
12 Àwọn ewé rẹ̀ rẹwà, èso rẹ̀ pọ̀ yanturu, oúnjẹ sì wà lórí rẹ̀ fún gbogbo ayé. Àwọn ẹranko orí ilẹ̀ ń wá ibòji wá sábẹ́ rẹ̀, àwọn ẹyẹ ojú ọ̀run ń gbé lórí àwọn ẹ̀ka rẹ̀, gbogbo ohun alààyè* sì ń rí oúnjẹ jẹ lára rẹ̀.
13 “‘Bí mo ṣe ń wo ìran tí mo rí nígbà tí mo wà lórí ibùsùn mi, mo rí olùṣọ́ kan, ẹni mímọ́, tó ń sọ̀ kalẹ̀ láti ọ̀run.+
14 Ó ké jáde pé: “Ẹ gé igi náà lulẹ̀,+ ẹ gé àwọn ẹ̀ka rẹ̀ kúrò, ẹ gbọn àwọn ewé rẹ̀ dà nù, kí ẹ sì tú àwọn èso rẹ̀ ká! Kí àwọn ẹranko sá kúrò lábẹ́ rẹ̀, kí àwọn ẹyẹ sì kúrò lórí àwọn ẹ̀ka rẹ̀.
15 Àmọ́ ẹ fi kùkùté igi náà sílẹ̀ pẹ̀lú gbòǹgbò rẹ̀* nínú ilẹ̀, kí ẹ sì fi ọ̀já irin àti bàbà dè é láàárín koríko pápá. Ẹ jẹ́ kí ìrì ọ̀run sẹ̀ sí i, kí ìpín rẹ̀ sì wà pẹ̀lú àwọn ẹranko láàárín ewéko ayé.+
16 Kí ọkàn rẹ̀ yí pa dà kúrò ní ti èèyàn, kí a sì fún un ní ọkàn ẹranko, kí ìgbà méje+ sì kọjá lórí rẹ̀.+
17 Àṣẹ tí àwọn olùṣọ́+ pa nìyí, àwọn ẹni mímọ́ ló sì béèrè fún un, kí àwọn èèyàn tó wà láàyè lè mọ̀ pé Ẹni Gíga Jù Lọ ni Alákòóso nínú ìjọba aráyé,+ ẹni tó bá wù ú ló ń gbé e fún, ẹni tó sì rẹlẹ̀ jù nínú àwọn èèyàn ló ń fi síbẹ̀.”
18 “‘Àlá tí èmi, Ọba Nebukadinésárì lá nìyí; ó yá, ìwọ Bẹtiṣásárì, sọ ìtumọ̀ rẹ̀ fún mi, torí gbogbo àwọn amòye yòókù nínú ìjọba mi kò lè sọ ìtumọ̀ rẹ̀ fún mi.+ Àmọ́ ìwọ lè sọ ọ́, torí pé ẹ̀mí àwọn ọlọ́run mímọ́ wà nínú rẹ.’
19 “Ní àkókò yẹn, ẹnu ya Dáníẹ́lì fúngbà díẹ̀, ẹni tí orúkọ rẹ̀ ń jẹ́ Bẹtiṣásárì,+ èrò ọkàn rẹ̀ sì bẹ̀rẹ̀ sí í dẹ́rù bà á.
“Ọba sọ pé, ‘Bẹtiṣásárì, má ṣe jẹ́ kí àlá náà àti ìtumọ̀ rẹ̀ dẹ́rù bà ọ́.’
“Bẹtiṣásárì dáhùn pé, ‘Olúwa mi, kí àlá náà ṣẹ sí àwọn tó kórìíra rẹ, kí ìtumọ̀ rẹ̀ sì ṣẹ sí àwọn ọ̀tá rẹ lára.
20 “‘Igi tí o rí, tó di ńlá, tó sì lágbára, tí orí rẹ̀ kan ọ̀run, tí gbogbo ayé sì ń rí i,+
21 tí àwọn ewé rẹ̀ rẹwà, tí èso rẹ̀ pọ̀ yanturu, tó sì jẹ́ oúnjẹ fún gbogbo ayé, tí àwọn ẹranko orí ilẹ̀ ń gbé lábẹ́ rẹ̀, tí àwọn ẹyẹ ojú ọ̀run sì ń gbé lórí àwọn ẹ̀ka rẹ̀,+
22 ọba, ìwọ ni, torí pé o ti di ẹni ńlá, o sì ti di alágbára, títóbi rẹ ti dé ọ̀run,+ àkóso rẹ sì ti dé àwọn ìkángun ayé.+
23 “‘Ọba wá rí olùṣọ́ kan, ẹni mímọ́,+ tó ń sọ̀ kalẹ̀ láti ọ̀run, ó ń sọ pé: “Ẹ gé igi náà lulẹ̀, kí ẹ sì pa á run, àmọ́ ẹ fi kùkùté igi náà sílẹ̀ pẹ̀lú gbòǹgbò rẹ̀* nínú ilẹ̀, kí ẹ sì fi ọ̀já irin àti bàbà dè é láàárín koríko pápá. Ẹ jẹ́ kí ìrì ọ̀run sẹ̀ sí i, kí ìpín rẹ̀ sì wà pẹ̀lú àwọn ẹranko títí ìgbà méje fi máa kọjá lórí rẹ̀.”+
24 Ìtumọ̀ rẹ̀ nìyí, ọba; àṣẹ tí Ẹni Gíga Jù Lọ pa, tó gbọ́dọ̀ ṣẹlẹ̀ sí olúwa mi ọba ni.
25 Wọ́n máa lé ọ kúrò láàárín àwọn èèyàn, ọ̀dọ̀ àwọn ẹranko ni wàá máa gbé, a sì máa fún ọ ní ewéko jẹ bí akọ màlúù; ìrì ọ̀run máa sẹ̀ sí ọ lára,+ ìgbà méje + sì máa kọjá lórí rẹ,+ títí o fi máa mọ̀ pé Ẹni Gíga Jù Lọ ni Alákòóso nínú ìjọba aráyé, ẹni tó bá sì wù ú ló ń gbé e fún.+
26 “‘Àmọ́ torí wọ́n sọ pé kí wọ́n fi kùkùté igi náà sílẹ̀ pẹ̀lú gbòǹgbò rẹ̀,*+ ìjọba rẹ máa pa dà di tìrẹ lẹ́yìn tí o bá mọ̀ pé ọ̀run ló ń ṣàkóso.
27 Torí náà, ọba, kí ìmọ̀ràn mi rí ìtẹ́wọ́gbà rẹ. Yí pa dà kúrò nínú ẹ̀ṣẹ̀ rẹ nípa ṣíṣe ohun tó tọ́, kí o sì yí pa dà kúrò nínú ìwà burúkú rẹ nípa fífi àánú hàn sí àwọn aláìní. Ó ṣeé ṣe kí nǹkan túbọ̀ lọ dáadáa fún ọ.’”+
28 Gbogbo nǹkan yìí ṣẹlẹ̀ sí Ọba Nebukadinésárì.
29 Lẹ́yìn oṣù méjìlá (12), ó ń rìn lórí òrùlé ààfin ọba Bábílónì.
30 Ọba ń sọ pé: “Ṣebí Bábílónì Ńlá nìyí, tí mo fi agbára mi àti okun mi kọ́ fún ilé ọba àti fún ògo ọlá ńlá mi?”
31 Ọba ò tíì sọ̀rọ̀ yìí tán lẹ́nu tí ohùn kan fi dún láti ọ̀run pé: “À ń sọ fún ìwọ Ọba Nebukadinésárì pé, ‘Ìjọba náà ti kúrò lọ́wọ́ rẹ,+
32 wọ́n sì máa lé ọ kúrò láàárín àwọn èèyàn. Ọ̀dọ̀ àwọn ẹranko ni wàá máa gbé, a máa fún ọ ní ewéko jẹ bí akọ màlúù, ìgbà méje sì máa kọjá lórí rẹ, títí o fi máa mọ̀ pé Ẹni Gíga Jù Lọ ni Alákòóso nínú ìjọba aráyé, ẹni tó bá sì wù ú ló ń gbé e fún.’”+
33 Ní ìṣẹ́jú yẹn, ọ̀rọ̀ náà ṣẹ sí Nebukadinésárì lára. Wọ́n lé e kúrò láàárín àwọn èèyàn, ó sì bẹ̀rẹ̀ sí í jẹ ewéko bí akọ màlúù, ìrì ọ̀run sẹ̀ sí i lára, títí irun rẹ̀ fi gùn bí ìyẹ́ idì, tí èékánná rẹ̀ sì dà bí èékánná ẹyẹ.+
34 “Ní òpin àkókò yẹn,+ èmi Nebukadinésárì gbójú sókè ọ̀run, òye mi sì pa dà sínú mi; mo yin Ẹni Gíga Jù Lọ, mo sì fi ìyìn àti ògo fún Ẹni tó wà láàyè títí láé, torí àkóso tó wà títí láé ni àkóso rẹ̀, ìjọba rẹ̀ sì wà láti ìran dé ìran.+
35 Kò ka gbogbo àwọn tó ń gbé ayé sí nǹkan kan, ohun tó bá sì wù ú ló ń ṣe láàárín àwọn ọmọ ogun ọ̀run àti àwọn tó ń gbé ayé. Kò sí ẹni tó lè dá a dúró*+ tàbí kó sọ fún un pé, ‘Kí lo ṣe yìí?’+
36 “Ìgbà yẹn ni òye mi pa dà sínú mi, ògo ìjọba mi, ọlá ńlá mi àti iyì mi sì pa dà sára mi.+ Àwọn ìjòyè mi àtàwọn èèyàn pàtàkì wá mi kàn, a sì dá mi pa dà sórí ìjọba mi, mo sì túbọ̀ di ẹni ńlá ju ti tẹ́lẹ̀ lọ.
37 “Ní báyìí, èmi Nebukadinésárì ń yin Ọba ọ̀run,+ mò ń gbé e ga, mo sì ń fi ògo fún un, torí òtítọ́ ni gbogbo iṣẹ́ rẹ̀, ọ̀nà rẹ̀ tọ́,+ ó sì lè rẹ àwọn tó ń gbéra ga wálẹ̀.”+
Àlàyé Ìsàlẹ̀ Ìwé
^ Ìyẹn, àwọn kan tó gbówọ́ nínú wíwoṣẹ́ àti wíwo ìràwọ̀.
^ Ní Árámáíkì, “gbogbo ẹran ara.”
^ Tàbí “ẹ fi gbòǹgbò ìdí rẹ̀ sílẹ̀.”
^ Tàbí “ẹ fi gbòǹgbò ìdí rẹ̀ sílẹ̀.”
^ Tàbí “fi gbòǹgbò ìdí igi náà sílẹ̀.”
^ Tàbí “yẹ̀ ẹ́ lọ́wọ́ wò.”