Diutarónómì 16:1-22
16 “Máa rántí oṣù Ábíbù,* kí o sì máa ṣe ayẹyẹ Ìrékọjá fún Jèhófà Ọlọ́run rẹ,+ torí pé oṣù Ábíbù ni Jèhófà Ọlọ́run rẹ mú ọ kúrò ní Íjíbítì ní òru.+
2 Kí o fi ẹran Ìrékọjá rúbọ sí Jèhófà Ọlọ́run rẹ,+ látinú agbo ẹran àti ọ̀wọ́ ẹran,+ ní ibi tí Jèhófà yàn pé kí orúkọ rẹ̀ máa wà.+
3 O ò gbọ́dọ̀ jẹ ohunkóhun tó ní ìwúkàrà pẹ̀lú rẹ̀;+ ọjọ́ méje ni kí o fi jẹ búrẹ́dì aláìwú, ó jẹ́ oúnjẹ ìpọ́njú, torí pé ẹ kánjú kúrò ní ilẹ̀ Íjíbítì.+ Máa ṣe èyí ní gbogbo ìgbà tí o bá fi wà láàyè kí o lè máa rántí ọjọ́ tí o kúrò ní ilẹ̀ Íjíbítì.+
4 Kò gbọ́dọ̀ sí àpòrọ́ kíkan lọ́wọ́ rẹ ní gbogbo ilẹ̀ rẹ fún ọjọ́ méje,+ bẹ́ẹ̀ ni ìkankan nínú ẹran tí o bá fi rúbọ ní ìrọ̀lẹ́ ọjọ́ àkọ́kọ́ ò gbọ́dọ̀ ṣẹ́ kù di ọjọ́ kejì.+
5 O ò gbọ́dọ̀ fi ẹran Ìrékọjá náà rúbọ nínú èyí tó bá kàn wù ọ́ nínú àwọn ìlú tí Jèhófà Ọlọ́run rẹ máa fún ọ.
6 Ṣùgbọ́n ibi tí Jèhófà Ọlọ́run rẹ bá yàn pé kí orúkọ rẹ̀ máa wà ni kí o ti ṣe é. Kí o fi ẹran Ìrékọjá náà rúbọ ní ìrọ̀lẹ́, gbàrà tí oòrùn bá wọ̀,+ ní déédéé àkókò tí o jáde kúrò ní Íjíbítì.
7 Kí o sè é, kí o sì jẹ ẹ́+ ní ibi tí Jèhófà Ọlọ́run rẹ bá yàn,+ kí o wá pa dà sí àgọ́ rẹ tí ilẹ̀ bá mọ́.
8 Ọjọ́ mẹ́fà ni kí o fi jẹ búrẹ́dì aláìwú, àpéjọ ọlọ́wọ̀ sì máa wà fún Jèhófà Ọlọ́run rẹ ní ọjọ́ keje. O ò gbọ́dọ̀ ṣiṣẹ́ kankan.+
9 “Kí o ka ọ̀sẹ̀ méje. Ìgbà tí o bá kọ́kọ́ ki dòjé bọ ọkà tó wà ní ìdúró ni kí o ti bẹ̀rẹ̀ sí í ka ọ̀sẹ̀ méje náà.+
10 Kí o wá fi ọrẹ àtinúwá tí o mú wá ṣe Àjọyọ̀ Àwọn Ọ̀sẹ̀ fún Jèhófà Ọlọ́run rẹ,+ kí o mú un wá bí Jèhófà Ọlọ́run rẹ bá ṣe bù kún ọ tó.+
11 Kí o sì máa yọ̀ níwájú Jèhófà Ọlọ́run rẹ, ìwọ àti ọmọkùnrin rẹ, ọmọbìnrin rẹ, ẹrúkùnrin rẹ, ẹrúbìnrin rẹ, ọmọ Léfì tó wà nínú àwọn ìlú* rẹ, àjèjì, ọmọ aláìníbaba* àti opó, tí wọ́n wà láàárín rẹ, ní ibi tí Jèhófà Ọlọ́run rẹ bá yàn pé kí orúkọ rẹ̀ máa wà.+
12 Rántí pé o di ẹrú ní Íjíbítì,+ kí o máa pa àwọn ìlànà yìí mọ́, kí o sì máa tẹ̀ lé e.
13 “Ọjọ́ méje ni kí o fi ṣe Àjọyọ̀ Àtíbàbà,+ nígbà tí o bá kó ọkà rẹ jọ láti ibi ìpakà, tí o sì mú òróró àti wáìnì jáde láti ibi ìfúntí rẹ.
14 Máa yọ̀ nígbà àjọyọ̀ rẹ,+ ìwọ àti ọmọkùnrin rẹ, ọmọbìnrin rẹ, ẹrúkùnrin rẹ, ẹrúbìnrin rẹ, ọmọ Léfì, àjèjì, ọmọ aláìníbaba àti opó, tí wọ́n wà nínú àwọn ìlú rẹ.
15 Ọjọ́ méje ni kí o fi ṣe àjọyọ̀+ fún Jèhófà Ọlọ́run rẹ ní ibi tí Jèhófà bá yàn, torí Jèhófà Ọlọ́run rẹ máa bù kún gbogbo ohun tí o bá kórè àti gbogbo iṣẹ́ ọwọ́ rẹ,+ wàá sì máa láyọ̀ nígbà gbogbo.+
16 “Kí gbogbo ọkùnrin rẹ máa fara hàn níwájú Jèhófà Ọlọ́run lẹ́ẹ̀mẹta lọ́dún ní ibi tó bá yàn: ní Àjọyọ̀ Búrẹ́dì Aláìwú,+ Àjọyọ̀ Àwọn Ọ̀sẹ̀+ àti Àjọyọ̀ Àtíbàbà,+ kí ẹnì kankan nínú wọn má sì wá síwájú Jèhófà lọ́wọ́ òfo.
17 Kí kálukú yín mú ẹ̀bùn wá bí Jèhófà Ọlọ́run yín bá ṣe bù kún yín tó.+
18 “Kí o yan àwọn onídàájọ́+ àti àwọn olórí fún ẹ̀yà kọ̀ọ̀kan ní gbogbo ìlú* tí Jèhófà Ọlọ́run rẹ máa fún ọ, kí wọ́n sì máa fi òdodo ṣèdájọ́ àwọn èèyàn náà.
19 O ò gbọ́dọ̀ ṣe èrú tí o bá ń dájọ́,+ o ò gbọ́dọ̀ ṣe ojúsàájú,+ o ò sì gbọ́dọ̀ gba àbẹ̀tẹ́lẹ̀, torí àbẹ̀tẹ́lẹ̀ máa ń dí ọlọ́gbọ́n lójú,+ ó sì máa ń mú kí olódodo yí ọ̀rọ̀ po.
20 Máa ṣèdájọ́ òdodo, àní ìdájọ́ òdodo ni kí o máa ṣe,+ kí o lè máa wà láàyè, kí o sì lè gba ilẹ̀ tí Jèhófà Ọlọ́run rẹ máa fún ọ.
21 “O ò gbọ́dọ̀ gbin igi èyíkéyìí láti fi ṣe òpó òrìṣà*+ sẹ́gbẹ̀ẹ́ pẹpẹ Jèhófà Ọlọ́run rẹ tí o ṣe fún ara rẹ.
22 “O ò sì gbọ́dọ̀ ṣe ọwọ̀n òrìṣà fún ara rẹ,+ torí Jèhófà Ọlọ́run rẹ kórìíra rẹ̀.
Àlàyé Ìsàlẹ̀ Ìwé
^ Wo Àfikún B15.
^ Tàbí “aláìlóbìí.”
^ Ní Héb., “ẹnubodè.”
^ Ní Héb., “nínú gbogbo ẹnubodè rẹ.”
^ Wo Àlàyé Ọ̀rọ̀.