Diutarónómì 2:1-37

  • Wọ́n fi ọdún 38 rìn kiri ní aginjù (1-23)

  • Wọ́n ṣẹ́gun Síhónì ọba Hẹ́ṣíbónì (24-37)

2  “Lẹ́yìn náà, a ṣẹ́rí pa dà, a sì gba ọ̀nà Òkun Pupa lọ sí aginjù, bí Jèhófà ṣe sọ fún mi gẹ́lẹ́,+ ọ̀pọ̀ ọjọ́ la sì fi rìn yí ká Òkè Séírì.  Níkẹyìn, Jèhófà sọ fún mi pé,  ‘Èyí tí ẹ rìn yí ká òkè yìí tó. Ó yá, ẹ yí sí apá àríwá.  Kí o sì pàṣẹ fún àwọn èèyàn náà pé: “Ààlà ilẹ̀ àwọn arákùnrin yín, àwọn àtọmọdọ́mọ Ísọ̀,+ tí wọ́n ń gbé ní Séírì,+ lẹ máa gbà kọjá, ẹ̀rù yín á sì máa bà wọ́n,+ torí náà, ẹ ṣọ́ra gidigidi.  Ẹ má ṣe bá wọn fa wàhálà kankan,* torí mi ò ní fún yín ní ìkankan lára ilẹ̀ wọn, bí ò tiẹ̀ ju ìwọ̀n àtẹ́lẹsẹ̀ kan lọ, torí mo ti fún Ísọ̀ ní Òkè Séírì kó lè di tirẹ̀.+  Kí ẹ san owó oúnjẹ tí ẹ bá jẹ fún wọn, kí ẹ sì san owó omi tí ẹ bá mu.+  Torí Jèhófà Ọlọ́run rẹ ti bù kún ọ nínú gbogbo ohun tí o ṣe. Ó mọ gbogbo bí o ṣe ń rìn nínú aginjù tó tóbi yìí dáadáa. Jèhófà Ọlọ́run rẹ ti wà pẹ̀lú rẹ jálẹ̀ ogójì (40) ọdún yìí, o ò sì ṣaláìní ohunkóhun.”’+  Torí náà, a gba ọ̀dọ̀ àwọn arákùnrin wa kọjá, àwọn àtọmọdọ́mọ Ísọ̀,+ tí wọ́n ń gbé ní Séírì, a ò gba ọ̀nà Árábà, Élátì àti Esioni-gébérì.+ “A wá yí gba ọ̀nà aginjù Móábù.+  Jèhófà wá sọ fún mi pé, ‘Má ṣe bá Móábù fa wàhálà kankan, má sì bá wọn jagun, torí mi ò ní fún ọ ní ìkankan lára ilẹ̀ rẹ̀ pé kó di tìrẹ, torí mo ti fún àwọn àtọmọdọ́mọ Lọ́ọ̀tì ní Árì kó lè di tiwọn.+ 10  (Àwọn Émímù+ ló ń gbé ibẹ̀ tẹ́lẹ̀, èèyàn ńlá ni wọ́n, wọ́n pọ̀ gan-an, wọ́n sì ga bí àwọn Ánákímù. 11  Àwọn Réfáímù+ náà rí bí àwọn Ánákímù,+ àwọn ọmọ Móábù sì máa ń pè wọ́n ní Émímù. 12  Séírì ni àwọn Hórì+ ń gbé tẹ́lẹ̀, àmọ́ àwọn àtọmọdọ́mọ Ísọ̀ lé wọn kúrò, wọ́n pa wọ́n run, wọ́n sì wá ń gbé ilẹ̀ wọn,+ ohun tí Ísírẹ́lì máa ṣe sí ilẹ̀ tó jẹ́ tiwọn nìyẹn, èyí tó dájú pé Jèhófà máa fún wọn.) 13  Ó yá, lọ sọdá Àfonífojì Séréédì.’ Bí a ṣe lọ sọdá Àfonífojì Séréédì+ nìyẹn. 14  Ọdún méjìdínlógójì (38) la fi rìn láti Kadeṣi-bánéà títí a fi sọdá Àfonífojì Séréédì, títí gbogbo ìran àwọn ọkùnrin ogun fi pa run láàárín àpéjọ, bí Jèhófà ṣe búra fún wọn gẹ́lẹ́.+ 15  Jèhófà fi ọwọ́ rẹ̀ jẹ wọ́n níyà kó lè pa wọ́n run láàárín àpéjọ náà títí wọ́n fi ṣègbé.+ 16  “Gbàrà tí gbogbo àwọn ọkùnrin ogun ti kú tán láàárín àwọn èèyàn náà,+ 17  Jèhófà tún sọ fún mi pé, 18  ‘Lónìí, kí ẹ gba ilẹ̀ Móábù kọjá, ìyẹn Árì. 19  Tí o bá ti sún mọ́ ọ̀dọ̀ àwọn ọmọ Ámónì, má yọ wọ́n lẹ́nu, má sì múnú bí wọn, torí mi ò ní fún ọ ní ìkankan lára ilẹ̀ àwọn ọmọ Ámónì kó lè di tìrẹ, nítorí mo ti fún àwọn àtọmọdọ́mọ Lọ́ọ̀tì kó lè di tiwọn.+ 20  Ilẹ̀ àwọn Réfáímù+ ni wọ́n máa ń ka ibí yìí náà sí tẹ́lẹ̀. (Ibẹ̀ ni àwọn Réfáímù ń gbé tẹ́lẹ̀, àwọn ọmọ Ámónì sì máa ń pè wọ́n ní Sámúsúmímù. 21  Èèyàn ńlá ni wọ́n, wọ́n pọ̀ gan-an, wọ́n sì ga bí àwọn Ánákímù;+ àmọ́ Jèhófà pa wọ́n run níwájú àwọn ọmọ Ámónì, wọ́n lé wọn jáde, wọ́n sì ń gbé ilẹ̀ wọn. 22  Ohun tó ṣe fún àwọn àtọmọdọ́mọ Ísọ̀ tí wọ́n ń gbé ní Séírì+ báyìí nìyẹn, nígbà tó pa àwọn Hórì+ run níwájú wọn, kí wọ́n lè lé wọn kúrò, kí wọ́n sì máa gbé ilẹ̀ wọn títí di òní yìí. 23  Ní ti àwọn Áfímù, ibi tí wọ́n ń gbé nasẹ̀ dé Gásà,+ títí àwọn Káfítórímù tí wọ́n wá láti Káfítórì*+ fi pa wọ́n run, tí wọ́n sì ń gbé ilẹ̀ wọn.) 24  “‘Ẹ dìde, kí ẹ sì rí i pé ẹ sọdá Àfonífojì Áánónì.+ Wò ó, mo ti fi Síhónì+ ọba Hẹ́ṣíbónì, tó jẹ́ Ámórì lé yín lọ́wọ́. Torí náà, ẹ bẹ̀rẹ̀ sí í gba ilẹ̀ rẹ̀, kí ẹ sì bá a jagun. 25  Lónìí yìí, màá mú kí ẹ̀rù yín máa ba gbogbo èèyàn tó wà lábẹ́ ọ̀run tí wọ́n bá gbọ́ ìròyìn nípa yín. Ọkàn wọn kò ní balẹ̀, jìnnìjìnnì á sì bò wọ́n* torí yín.’+ 26  “Mo wá ní kí àwọn ìránṣẹ́ láti aginjù Kédémótì+ lọ jíṣẹ́ àlàáfíà+ yìí fún Síhónì ọba Hẹ́ṣíbónì pé, 27  ‘Jẹ́ kí n gba ilẹ̀ rẹ kọjá. Mi ò ní kọjá ojú ọ̀nà, mi ò sì ní yà sí ọ̀tún tàbí òsì.+ 28  Oúnjẹ àti omi tí o bá tà fún mi nìkan ni màá jẹ tí màá sì mu. Ṣáà jẹ́ kí n fi ẹsẹ̀ mi rìn kọjá, 29  títí màá fi sọdá Jọ́dánì sí ilẹ̀ tí Jèhófà Ọlọ́run wa fẹ́ fún wa. Ohun tí àwọn àtọmọdọ́mọ Ísọ̀ tí wọ́n ń gbé ní Séírì àtàwọn ọmọ Móábù tí wọ́n ń gbé ní Árì ṣe fún mi nìyẹn.’ 30  Àmọ́ Síhónì ọba Hẹ́ṣíbónì kò jẹ́ ká kọjá, torí Jèhófà Ọlọ́run rẹ gbà á láyè pé kó ṣorí kunkun,+ kí ọkàn rẹ̀ sì le, kó lè fi í lé ọ lọ́wọ́ bó ṣe rí báyìí.  + 31  “Jèhófà wá sọ fún mi pé, ‘Wò ó, mo ti ń fi Síhónì àti ilẹ̀ rẹ̀ lé ọ lọ́wọ́. Bẹ̀rẹ̀ sí í gba ilẹ̀ rẹ̀.’+ 32  Nígbà tí Síhónì àti gbogbo èèyàn rẹ̀ jáde wá gbógun jà wá ní Jáhásì,+ 33  Jèhófà Ọlọ́run wa fi í lé wa lọ́wọ́, a sì ṣẹ́gun òun àtàwọn ọmọ rẹ̀ pẹ̀lú gbogbo èèyàn rẹ̀. 34  A gba gbogbo ìlú rẹ̀ nígbà yẹn, a sì pa gbogbo ìlú náà run, títí kan àwọn ọkùnrin, àwọn obìnrin àtàwọn ọmọdé. A ò dá ẹnikẹ́ni sí.+ 35  Àwọn ẹran ọ̀sìn nìkan la kó bọ̀ láti ogun pẹ̀lú àwọn ẹrù tí a kó láti àwọn ìlú tí a ṣẹ́gun. 36  Láti Áróérì,+ èyí tó wà ní etí Àfonífojì Áánónì, (títí kan ìlú tó wà ní àfonífojì náà), títí dé Gílíádì, kò sí ìlú tí apá wa ò ká. Gbogbo wọn ni Jèhófà Ọlọ́run wa fi lé wa lọ́wọ́.+ 37  Àmọ́, ẹ ò sún mọ́ ilẹ̀ àwọn ọmọ Ámónì,+ gbogbo etí Àfonífojì Jábókù+ àtàwọn ìlú tó wà ní agbègbè olókè àti gbogbo ibi tí Jèhófà Ọlọ́run wa kà léèwọ̀.

Àlàyé Ìsàlẹ̀ Ìwé

Tàbí “Ẹ má ṣe múnú bí wọn.”
Ìyẹn, Kírétè.
Tàbí “wọ́n á ní ìrora bíi ti ẹni tó ń rọbí.”