Diutarónómì 23:1-25

  • Àwọn tí kò gbọ́dọ̀ wá sínú ìjọ Ọlọ́run (1-8)

  • Kí ibùdó máa wà ní mímọ́ (9-14)

  • Ẹrú tó sá lọ (15, 16)

  • Wọn ò gbọ́dọ̀ ṣe aṣẹ́wó (17, 18)

  • Èlé àti ẹ̀jẹ́ (19-23)

  • Ohun tí ẹni tó ń kọjá lọ lè jẹ (24, 25)

23  “Ọkùnrin èyíkéyìí tí wọ́n bá tẹ̀ lọ́dàá, tí wọ́n fọ́ kórópọ̀n rẹ̀ tàbí tí wọ́n gé ẹ̀yà ìbímọ rẹ̀ kúrò kò gbọ́dọ̀ wá sínú ìjọ Jèhófà.+  “Ọmọ àlè kankan ò gbọ́dọ̀ wá sínú ìjọ Jèhófà.+ Àní títí dé ìran rẹ̀ kẹwàá, àtọmọdọ́mọ rẹ̀ kankan ò gbọ́dọ̀ wá sínú ìjọ Jèhófà.  “Ọmọ Ámónì tàbí ọmọ Móábù kankan ò gbọ́dọ̀ wá sínú ìjọ Jèhófà.+ Àní títí dé ìran wọn kẹwàá, àtọmọdọ́mọ wọn kankan ò gbọ́dọ̀ wá sínú ìjọ Jèhófà láé,  torí pé wọn ò fún yín ní oúnjẹ àti omi láti fi ràn yín lọ́wọ́ nígbà tí ẹ kúrò ní Íjíbítì,+ wọ́n sì tún gba Báláámù ọmọ Béórì láti Pétórì ti Mesopotámíà pé kó wá gégùn-ún fún* yín.+  Àmọ́ Jèhófà Ọlọ́run rẹ ò gbọ́ ti Báláámù.+ Kàkà bẹ́ẹ̀, Jèhófà Ọlọ́run rẹ yí ègún náà pa dà sí ìbùkún fún ọ,+ torí Jèhófà Ọlọ́run rẹ nífẹ̀ẹ́ rẹ.+  O ò gbọ́dọ̀ wá ire wọn tàbí ìtẹ̀síwájú wọn ní gbogbo ọjọ́ ayé rẹ.+  “O ò gbọ́dọ̀ kórìíra ọmọ Édómù, torí arákùnrin rẹ ni.+ “O ò gbọ́dọ̀ kórìíra ọmọ Íjíbítì, torí o di àjèjì ní ilẹ̀ rẹ̀.+  Ìran kẹta àwọn ọmọ tí wọ́n bá bí fún wọn lè wá sínú ìjọ Jèhófà.  “Tí o bá pàgọ́ láti gbógun ja àwọn ọ̀tá rẹ, kí o yẹra fún ohunkóhun tí kò dáa.*+ 10  Tí ọkùnrin kan bá di aláìmọ́ torí pé àtọ̀ dà lára rẹ̀ ní òru,+ kó kúrò nínú ibùdó, kó má sì pa dà síbẹ̀. 11  Tó bá di ìrọ̀lẹ́, kó fi omi wẹ̀, tí oòrùn bá sì ti wọ̀, kó pa dà sínú ibùdó.+ 12  Kí ibi ìkọ̀kọ̀* kan wà tí wàá máa lò lẹ́yìn ibùdó, ibẹ̀ sì ni kí o lọ. 13  Kí igi tó ṣeé fi gbẹ́lẹ̀ wà lára àwọn ohun èlò rẹ. Tí o bá lóṣòó ní ìta láti yàgbẹ́, kí o fi igi náà gbẹ́lẹ̀, kí o sì bo ìgbẹ́ rẹ. 14  Torí Jèhófà Ọlọ́run rẹ ń rìn kiri nínú ibùdó rẹ+ láti gbà ọ́, kó sì fi àwọn ọ̀tá rẹ lé ọ lọ́wọ́. Kí ibùdó rẹ máa wà ní mímọ́,+ kó má bàa rí ohunkóhun tí kò bójú mu láàárín rẹ, kó sì pa dà lẹ́yìn rẹ. 15  “O ò gbọ́dọ̀ fi ẹrú lé ọ̀gá rẹ̀ lọ́wọ́ tó bá sá kúrò lọ́dọ̀ ọ̀gá rẹ̀ wá sọ́dọ̀ rẹ. 16  Ó lè máa gbé láàárín rẹ níbikíbi tó bá yàn nínú ọ̀kan lára àwọn ìlú rẹ, níbikíbi tó bá wù ú. Má fìyà jẹ ẹ́.+ 17  “Ìkankan nínú àwọn ọmọbìnrin Ísírẹ́lì ò gbọ́dọ̀ di aṣẹ́wó tẹ́ńpìlì,+ bẹ́ẹ̀ ni ìkankan nínú àwọn ọmọkùnrin Ísírẹ́lì ò gbọ́dọ̀ di aṣẹ́wó tẹ́ńpìlì.+ 18  O ò gbọ́dọ̀ mú owó tí wọ́n san fún obìnrin kan nídìí iṣẹ́ aṣẹ́wó tàbí owó tí wọ́n san fún ọkùnrin kan* nídìí iṣẹ́ aṣẹ́wó* wá sínú ilé Jèhófà Ọlọ́run rẹ láti fi san ẹ̀jẹ́, torí méjèèjì jẹ́ ohun ìríra lójú Jèhófà Ọlọ́run rẹ. 19  “O ò gbọ́dọ̀ gba èlé lọ́wọ́ arákùnrin rẹ,+ ì báà jẹ́ èlé lórí owó, lórí oúnjẹ tàbí ohunkóhun tí wọ́n ń gba èlé lé lórí. 20  O lè gba èlé lọ́wọ́ àjèjì,+ àmọ́ o ò gbọ́dọ̀ gba èlé lọ́wọ́ arákùnrin rẹ,+ kí Jèhófà Ọlọ́run rẹ lè máa bù kún ọ nínú gbogbo ohun tí o bá dáwọ́ lé ní ilẹ̀ tí o fẹ́ lọ gbà.+ 21  “Tí o bá jẹ́jẹ̀ẹ́ fún Jèhófà Ọlọ́run rẹ,+ má ṣe lọ́ra láti san án.+ Torí ó dájú pé Jèhófà Ọlọ́run rẹ máa béèrè rẹ̀ lọ́wọ́ rẹ; àìjẹ́ bẹ́ẹ̀, ó máa di ẹ̀ṣẹ̀ sí ọ lọ́rùn.+ 22  Àmọ́ tí o ò bá jẹ́jẹ̀ẹ́, kò ní di ẹ̀ṣẹ̀ sí ọ lọ́rùn.+ 23  Máa mú ọ̀rọ̀ ẹnu rẹ ṣẹ,+ tí o bá sì fi ẹnu ara rẹ jẹ́jẹ̀ẹ́ pé wàá ṣe ọrẹ àtinúwá fún Jèhófà Ọlọ́run rẹ, o gbọ́dọ̀ ṣe é.+ 24  “Tí o bá lọ sínú ọgbà àjàrà ọmọnìkejì rẹ, o lè jẹ èso àjàrà débi tó bá tẹ́ ọ* lọ́rùn, àmọ́ o ò gbọ́dọ̀ kó ìkankan sínú àpò rẹ.+ 25  “Tí o bá wọ inú oko ọkà ọmọnìkejì rẹ, o lè fọwọ́ ya àwọn ṣírí ọkà tó ti gbó, àmọ́ má yọ dòjé ti ọkà ọmọnìkejì rẹ.+

Àlàyé Ìsàlẹ̀ Ìwé

Tàbí “pe ibi wá sórí.”
Tàbí “tó ń sọni di aláìmọ́.”
Ìyẹn, ilé ìyàgbẹ́.
Tàbí “owó tí ọkùnrin kan gbà.”
Ní Héb., “owó tí wọ́n san fún ajá.”
Tàbí “ọkàn rẹ.”