Diutarónómì 26:1-19
26 “Tí o bá wá dé ilẹ̀ tí Jèhófà Ọlọ́run rẹ fẹ́ fún ọ pé kí o jogún, tí o ti gbà á, tí o sì ti ń gbé ibẹ̀,
2 kí o mú lára gbogbo ohun* tó bá kọ́kọ́ so ní ilẹ̀ náà, èyí tí o bá kó jọ ní ilẹ̀ rẹ tí Jèhófà Ọlọ́run rẹ fẹ́ fún ọ, kí o kó o sínú apẹ̀rẹ̀, kí o sì lọ sí ibi tí Jèhófà Ọlọ́run rẹ bá yàn pé kí orúkọ rẹ̀ máa wà.+
3 Kí o lọ bá ẹni tó bá jẹ́ àlùfáà nígbà yẹn, kí o sì sọ fún un pé, ‘Mò ń sọ fún Jèhófà Ọlọ́run rẹ lónìí pé mo ti dé ilẹ̀ tí Jèhófà búra fún àwọn baba ńlá wa pé òun máa fún wa.’+
4 “Kí àlùfáà náà wá gba apẹ̀rẹ̀ náà lọ́wọ́ rẹ, kó sì gbé e síwájú pẹpẹ Jèhófà Ọlọ́run rẹ.
5 Kí o kéde níwájú Jèhófà Ọlọ́run rẹ pé, ‘Ará Arémíà tó ń lọ káàkiri* ni bàbá mi,+ ó lọ sí Íjíbítì,+ ó sì di àjèjì tó ń gbé níbẹ̀, òun àti àwọn díẹ̀ tí wọ́n jẹ́ ará ilé rẹ̀.+ Àmọ́ ibẹ̀ ló ti di orílẹ̀-èdè ńlá, tó lágbára, tó sì pọ̀ rẹpẹtẹ.+
6 Àwọn ọmọ Íjíbítì fìyà jẹ wá, wọ́n pọ́n wa lójú, wọ́n sọ wá di ẹrú tí wọ́n ń lò nílòkulò.+
7 A wá bẹ̀rẹ̀ sí í ké pe Jèhófà, Ọlọ́run àwọn baba ńlá wa, Jèhófà sì gbọ́ ohùn wa, ó rí bí wọ́n ṣe ń fìyà jẹ wá, bá a ṣe ń dààmú àti bí wọ́n ṣe ń pọ́n wa lójú.+
8 Níkẹyìn, Jèhófà fi ọwọ́ agbára mú wa kúrò ní Íjíbítì, pẹ̀lú apá tó nà jáde,+ àwọn nǹkan tó ń bani lẹ́rù, àwọn àmì àtàwọn iṣẹ́ ìyanu.+
9 Ó mú wa wá sí ibí yìí, ó sì fún wa ní ilẹ̀ yìí, ilẹ̀ tí wàrà àti oyin ti ń ṣàn.+
10 Ní báyìí, mo ti mú àkọ́so èso ilẹ̀ tí Jèhófà fún mi wá.’+
“Kí o kó o síwájú Jèhófà Ọlọ́run rẹ, kí o sì tẹrí ba níwájú Jèhófà Ọlọ́run rẹ.
11 Kí o wá máa yọ̀ torí gbogbo nǹkan rere tí Jèhófà Ọlọ́run rẹ fún ìwọ àti agbo ilé rẹ, ìwọ àti ọmọ Léfì àti àjèjì tó bá wà láàárín rẹ.+
12 “Tí o bá ti kó gbogbo ìdá mẹ́wàá+ èso ilẹ̀ rẹ jọ tán ní ọdún kẹta, ọdún ìdá mẹ́wàá, kí o fún ọmọ Léfì, àjèjì, ọmọ aláìníbaba* àti opó, kí wọ́n sì jẹ ẹ́ yó nínú àwọn ìlú* rẹ.+
13 Kí o wá sọ níwájú Jèhófà Ọlọ́run rẹ pé, ‘Mo ti kó ìpín mímọ́ kúrò nínú ilé mi, mo sì ti fún ọmọ Léfì, àjèjì, ọmọ aláìníbaba àti opó,+ bí o ṣe pa á láṣẹ fún mi gẹ́lẹ́. Mi ò tẹ àwọn àṣẹ rẹ lójú, mi ò sì pa wọ́n tì.
14 Mi ò jẹ nínú rẹ̀ nígbà tí mò ń ṣọ̀fọ̀, mi ò sì mú ìkankan kúrò nínú rẹ̀ nígbà tí mo jẹ́ aláìmọ́, bẹ́ẹ̀ ni mi ò lò lára rẹ̀ torí òkú. Mo fetí sí ohùn Jèhófà Ọlọ́run mi, mo sì ti ṣe gbogbo ohun tí o pa láṣẹ fún mi.
15 Wá bojú wolẹ̀ láti ọ̀run, ibi mímọ́ rẹ tí ò ń gbé, kí o sì bù kún àwọn èèyàn rẹ Ísírẹ́lì àti ilẹ̀ tí o fún wa,+ bí o ṣe búra fún àwọn baba ńlá wa,+ ilẹ̀ tí wàrà àti oyin ti ń ṣàn.’+
16 “Jèhófà Ọlọ́run rẹ ń pa á láṣẹ fún ọ lónìí pé kí o máa pa àwọn ìlànà àtàwọn ìdájọ́ yìí mọ́. Kí o máa tẹ̀ lé wọn, kí o sì máa fi gbogbo ọkàn rẹ+ àti gbogbo ara* rẹ pa á mọ́.
17 Lónìí, o ti gbọ́ tí Jèhófà kéde pé òun máa di Ọlọ́run rẹ, tí o bá ń rìn ní àwọn ọ̀nà rẹ̀, tí ò ń pa ìlànà rẹ̀ mọ́+ àti àwọn àṣẹ rẹ̀+ pẹ̀lú àwọn ìdájọ́ rẹ̀,+ tí o sì ń fetí sí ohùn rẹ̀.
18 Jèhófà sì ti gbọ́ ohun tí o kéde lónìí pé o máa di èèyàn rẹ̀, ohun ìní rẹ̀ pàtàkì,*+ bó ṣe ṣèlérí fún ọ gẹ́lẹ́ àti pé o máa pa gbogbo àṣẹ rẹ̀ mọ́,
19 pé òun máa gbé ọ ga ju gbogbo orílẹ̀-èdè yòókù tó dá,+ pé òun á mú kí àwọn èèyàn máa yìn ọ́, òun sì máa mú kí o ní òkìkí àti ògo, bó ṣe ṣèlérí fún ọ gẹ́lẹ́, tí o bá fi hàn pé o jẹ́ èèyàn mímọ́ lójú Jèhófà Ọlọ́run rẹ.”+
Àlàyé Ìsàlẹ̀ Ìwé
^ Ní Héb., “èso.”
^ Tàbí kó jẹ́, “tó ń kú lọ.”
^ Ní Héb., “ẹnubodè.”
^ Tàbí “aláìlóbìí.”
^ Wo Àlàyé Ọ̀rọ̀, “Ọkàn.”
^ Tàbí “tó ṣeyebíye.”