Hágáì 2:1-23
2 Ní ọjọ́ kọkànlélógún, oṣù keje, Jèhófà rán wòlíì Hágáì+ níṣẹ́ pé:
2 “Jọ̀ọ́, bi Serubábélì+ ọmọ Ṣéálítíẹ́lì, gómìnà Júdà+ àti Jóṣúà+ ọmọ Jèhósádákì,+ àlùfáà àgbà àti àwọn tó ṣẹ́ kù nínú àwọn èèyàn náà pé:
3 ‘Ta ló ṣẹ́ kù nínú yín tó rí ilé* yìí nígbà tó ṣì rẹwà?+ Báwo ló ṣe rí lójú yín báyìí? Tí ẹ bá fi wé ti tẹ́lẹ̀, ǹjẹ́ ó ṣì já mọ́ nǹkan kan?’+
4 “‘Àmọ́ ní báyìí, ìwọ Serubábélì, jẹ́ onígboyà. Kí ìwọ Jóṣúà ọmọ Jèhósádákì, àlùfáà àgbà pẹ̀lú sì jẹ́ onígboyà,’ ni Jèhófà wí.
“‘Kí gbogbo ẹ̀yin èèyàn ilẹ̀ náà pẹ̀lú jẹ́ onígboyà,+ kí ẹ sì ṣiṣẹ́’ ni Jèhófà wí.
“‘Torí mo wà pẹ̀lú yín,’+ ni Jèhófà Ọlọ́run àwọn ọmọ ogun wí.
5 ‘Ẹ rántí ìlérí tí mo ṣe fún yín nígbà tí ẹ kúrò ní Íjíbítì,+ tí ẹ̀mí mi wà láàárín yín.*+ Ẹ má bẹ̀rù.’”+
6 “Torí ohun tí Jèhófà Ọlọ́run àwọn ọmọ ogun sọ nìyí, ‘Lẹ́ẹ̀kan sí i, màá mi ọ̀run, ayé, òkun àti ilẹ̀ gbígbẹ jìgìjìgì;+ kò ní pẹ́ mọ́.’
7 “‘Èmi yóò mi gbogbo orílẹ̀-èdè jìgìjìgì, àwọn ohun iyebíye* nínú gbogbo orílẹ̀-èdè yóò sì wọlé wá;+ èmi yóò sì fi ògo kún ilé yìí,’+ ni Jèhófà Ọlọ́run àwọn ọmọ ogun wí.
8 “‘Tèmi ni fàdákà, tèmi sì ni wúrà,’ ni Jèhófà Ọlọ́run àwọn ọmọ ogun wí.
9 “‘Ògo tí ilé yìí máa ní yóò ju ti tẹ́lẹ̀ lọ,’+ ni Jèhófà Ọlọ́run àwọn ọmọ ogun wí.
“‘Èmi yóò sì fún yín ní àlàáfíà ní ibí yìí,’+ ni Jèhófà Ọlọ́run àwọn ọmọ ogun wí.”
10 Ní ọjọ́ kẹrìnlélógún, oṣù kẹsàn-án, ọdún kejì ìjọba Dáríúsì, Jèhófà sọ fún wòlíì Hágáì+ pé:
11 “Ohun tí Jèhófà Ọlọ́run àwọn ọmọ ogun sọ nìyí, ‘Jọ̀ọ́, bi àwọn àlùfáà nípa òfin,+ pé:
12 “Tí èèyàn bá gbé ẹran mímọ́ sí etí aṣọ rẹ̀, tí aṣọ rẹ̀ sì kan búrẹ́dì tàbí ọbẹ̀ tàbí wáìnì tàbí òróró tàbí oúnjẹ èyíkéyìí, ṣé ó máa di mímọ́?”’”
Àwọn àlùfáà fèsì pé: “Rárá!”
13 Hágáì wá béèrè pé: “Tí ẹnì kan tó ti di aláìmọ́ torí pé ó fara kan òkú* bá fọwọ́ kan èyíkéyìí nínú nǹkan wọ̀nyí, ṣé ó máa di aláìmọ́?”+
Àwọn àlùfáà fèsì pé: “Ó máa di aláìmọ́.”
14 Hágáì wá sọ pé: “‘Bí àwọn èèyàn yìí ṣe rí nìyẹn, bí orílẹ̀-èdè yìí sì ṣe rí níwájú mi nìyẹn,’ ni Jèhófà wí, ‘bẹ́ẹ̀ náà ni gbogbo iṣẹ́ ọwọ́ wọn rí; ohunkóhun tí wọ́n bá mú wá síbẹ̀ jẹ́ aláìmọ́.’
15 “‘Àmọ́ ní báyìí, ẹ jọ̀ọ́, ẹ kíyè sí* èyí láti òní lọ: Kí wọ́n tó gbé òkúta kan lé òmíràn ní tẹ́ńpìlì Jèhófà,+
16 báwo ni nǹkan ṣe rí nígbà yẹn? Tí ẹnì kan bá wá síbi tí wọ́n ń kó ọkà jọ sí, tó ń retí ogún (20) òṣùwọ̀n, mẹ́wàá péré ló máa rí; tí ẹnì kan bá sì wá láti bu àádọ́ta (50) òṣùwọ̀n nínú ọpọ́n wáìnì, ogún (20) péré ló máa rí;+
17 mo fi ooru tó ń jó nǹkan gbẹ àti èbíbu+ àti yìnyín kọ lù yín, àní gbogbo iṣẹ́ ọwọ́ yín, àmọ́ ẹnì kankan lára yín ò pa dà sọ́dọ̀ mi,’ ni Jèhófà wí.
18 “‘Ẹ jọ̀ọ́, ẹ kíyè sí* èyí láti òní lọ, láti ọjọ́ kẹrìnlélógún oṣù kẹsàn-án, láti ọjọ́ tí wọ́n ti fi ìpìlẹ̀ tẹ́ńpìlì Jèhófà lélẹ̀;+ ẹ kíyè sí ọ̀rọ̀ yìí:
19 Ṣé irúgbìn ṣì wà nínú ilé ìkẹ́rùsí?*+ Àjàrà, igi ọ̀pọ̀tọ́, pómégíránétì àti ólífì kò tíì so, àbí wọ́n ti so? Láti òní lọ, èmi yóò bù kún yín.’”+
20 Jèhófà tún bá Hágáì sọ̀rọ̀ lẹ́ẹ̀kejì ní ọjọ́ kẹrìnlélógún oṣù náà,+ ó ní:
21 “Sọ fún Serubábélì, gómìnà Júdà pé, ‘Èmi yóò mi ọ̀run àti ayé jìgìjìgì.+
22 Èmi yóò bi ìtẹ́ àwọn ìjọba ṣubú, èmi yóò sì gba agbára lọ́wọ́ ìjọba àwọn orílẹ̀-èdè;+ èmi yóò bi kẹ̀kẹ́ ẹṣin àti àwọn tó gùn ún ṣubú, àwọn ẹṣin àti àwọn tó gùn wọ́n yóò sì ṣubú, kálukú wọn yóò sì fi idà pa arákùnrin rẹ̀.’”+
23 “‘Ní ọjọ́ yẹn,’ ni Jèhófà Ọlọ́run àwọn ọmọ ogun wí, ‘èmi yóò mú ìwọ ìránṣẹ́ mi, Serubábélì+ ọmọ Ṣéálítíẹ́lì,’+ ni Jèhófà wí, ‘èmi yóò sì ṣe ọ́ bí òrùka èdìdì, torí ìwọ ni ẹni tí mo yàn,’ ni Jèhófà Ọlọ́run àwọn ọmọ ogun wí.”
Àlàyé Ìsàlẹ̀ Ìwé
^ Tàbí “tẹ́ńpìlì.”
^ Tàbí kó jẹ́, “nígbà tí ẹ̀mí mi dúró sáàárín yín.”
^ Tàbí “ohun tó fani lọ́kàn mọ́ra.”
^ Tàbí “nípasẹ̀ ọkàn kan.” Wo Àlàyé Ọ̀rọ̀.
^ Tàbí “ẹ fara balẹ̀ ronú nípa.”
^ Tàbí “ẹ fara balẹ̀ ronú nípa.”
^ Tàbí “kòtò ọkà.”