Sí Àwọn Hébérù 10:1-39

  • Fífi ẹran rúbọ ò gbéṣẹ́ (1-4)

    • Òfin jẹ́ òjìji (1)

  • Kristi rúbọ lẹ́ẹ̀kan ṣoṣo láìtún ní ṣe é mọ́ láé (5-18)

  • Ọ̀nà àbáwọlé tuntun tó jẹ́ ọ̀nà ìyè (19-25)

    • Ká má ṣe máa kọ ìpàdé wa sílẹ̀ (24, 25)

  • Ìkìlọ̀ nípa ẹ̀ṣẹ̀ tí a mọ̀ọ́mọ̀ dá (26-31)

  • Ìgboyà àti ìgbàgbọ́ máa jẹ́ ká lè fara dà á (32-39)

10  Nígbà tó jẹ́ pé Òfin ní òjìji+ àwọn nǹkan rere tó ń bọ̀,+ àmọ́ tí kì í ṣe bí àwọn nǹkan náà ṣe máa rí gan-an, kò lè* sọ àwọn tó ń wá sí tòsí di pípé láé nípasẹ̀ àwọn ẹbọ kan náà tí wọ́n ń rú léraléra láti ọdún dé ọdún.+  Tí kò bá rí bẹ́ẹ̀, ṣé wọn ò ti ní dáwọ́ rírú àwọn ẹbọ náà dúró? Torí tí a bá ti wẹ àwọn tó ń ṣe iṣẹ́ ìsìn mímọ́ mọ́ lẹ́ẹ̀kan ṣoṣo, wọn ò ní mọ̀ ọ́n lára pé àwọn jẹ́ ẹlẹ́ṣẹ̀ mọ́.  Kàkà bẹ́ẹ̀, ṣe ni àwọn ẹbọ yìí ń ránni létí àwọn ẹ̀ṣẹ̀ láti ọdún dé ọdún,+  torí ẹ̀jẹ̀ àwọn akọ màlúù àti ti àwọn ewúrẹ́ kò lè mú àwọn ẹ̀ṣẹ̀ kúrò.  Torí náà, nígbà tó wá sí ayé, ó sọ pé: “‘Ẹbọ àti ọrẹ kọ́ ni ohun tí o fẹ́, àmọ́ ìwọ pèsè ara kan fún mi.  O ò fọwọ́ sí àwọn odindi ẹbọ sísun àti ẹbọ ẹ̀ṣẹ̀.’+  Lẹ́yìn náà, mo sọ pé: ‘Wò ó! Mo ti dé (a ti kọ ọ́ nípa mi sínú àkájọ ìwé*) láti ṣe ìfẹ́ rẹ, Ọlọ́run.’”+  Lẹ́yìn tó kọ́kọ́ sọ pé: “O ò fẹ́ àwọn ẹbọ, ọrẹ, odindi ẹbọ sísun àti ẹbọ ẹ̀ṣẹ̀, o ò sì fọwọ́ sí i”—àwọn ẹbọ tí wọ́n ń rú, bí Òfin ṣe sọ—  ó wá sọ pé: “Wò ó! Mo ti dé láti ṣe ìfẹ́ rẹ.”+ Ó fi òpin sí èyí àkọ́kọ́ kó lè fìdí ìkejì múlẹ̀. 10  Nípasẹ̀ “ìfẹ́” yìí,+ a ti fi ara Jésù Kristi tó fi rúbọ lẹ́ẹ̀kan ṣoṣo láìtún ní ṣe é mọ́ láé sọ wá di mímọ́.+ 11  Bákan náà, gbogbo àwọn àlùfáà máa ń lọ sẹ́nu iṣẹ́ wọn lójoojúmọ́ kí wọ́n lè ṣe iṣẹ́ ìsìn mímọ́,*+ kí wọ́n sì lè rú àwọn ẹbọ kan náà léraléra,+ èyí tí kò lè mú ẹ̀ṣẹ̀ kúrò pátápátá.+ 12  Àmọ́ ẹbọ kan ṣoṣo ni ọkùnrin yìí rú fún ẹ̀ṣẹ̀ láìtún ní ṣe é mọ́ láé, ó sì jókòó ní ọwọ́ ọ̀tún Ọlọ́run,+ 13  látìgbà yẹn, ó ń dúró de ìgbà tí a máa fi àwọn ọ̀tá rẹ̀ ṣe àpótí ìtìsẹ̀ rẹ̀.+ 14  Torí ẹbọ kan ṣoṣo tó rú ló fi sọ àwọn tí à ń sọ di mímọ́ di pípé+ láìtún ní ṣe é mọ́ láé. 15  Bákan náà, ẹ̀mí mímọ́ náà ń jẹ́rìí fún wa, torí lẹ́yìn tó sọ pé: 16  “‘Májẹ̀mú tí màá bá wọn dá lẹ́yìn ìgbà yẹn nìyí,’ ni Jèhófà* wí. ‘Màá fi àwọn òfin mi sínú ọkàn wọn, inú èrò wọn ni màá sì kọ ọ́ sí.’”+ 17  Ó wá sọ pé: “Mi ò sì ní rántí àwọn ẹ̀ṣẹ̀ wọn mọ́ àti àwọn ìwà wọn tí kò bófin mu.”+ 18  Torí náà, tí a bá ti dárí àwọn ẹ̀ṣẹ̀ yìí jini, kò tún sí ẹbọ nítorí ẹ̀ṣẹ̀ mọ́. 19  Torí náà, ẹ̀yin ará, nígbà tó jẹ́ pé a ní ìgboyà* láti wá sí ọ̀nà tó wọnú ibi mímọ́+ nípasẹ̀ ẹ̀jẹ̀ Jésù, 20  èyí tó ṣí sílẹ̀* fún wa bí ọ̀nà tuntun, tó sì jẹ́ ọ̀nà ìyè tó la aṣọ ìdábùú kọjá,+ ìyẹn ẹran ara rẹ̀, 21  nígbà tó sì jẹ́ pé a ní àlùfáà ńlá lórí ilé Ọlọ́run,+ 22  ẹ jẹ́ ká fi ọkàn tòótọ́ àti ìgbàgbọ́ tó kún rẹ́rẹ́ wá, nígbà tí a ti wẹ ọkàn wa mọ́ kúrò nínú ẹ̀rí ọkàn burúkú,+ tí a sì ti fi omi tó mọ́ wẹ ara wa.+ 23  Ẹ jẹ́ ká tẹra mọ́ ìkéde ìrètí wa ní gbangba* láìṣiyèméjì,+ torí pé olóòótọ́ ni ẹni tó ṣèlérí. 24  Ẹ sì jẹ́ ká gba ti ara wa rò* ká lè máa fún ara wa níṣìírí* láti ní ìfẹ́ àti láti ṣe àwọn iṣẹ́ rere,+ 25  ká má ṣe máa kọ ìpàdé wa sílẹ̀,+ bí àṣà àwọn kan, àmọ́ ká máa gba ara wa níyànjú,+ ní pàtàkì jù lọ bí ẹ ṣe ń rí i pé ọjọ́ náà ń sún mọ́lé.+ 26  Torí tí a bá mọ̀ọ́mọ̀ sọ ẹ̀ṣẹ̀ dàṣà lẹ́yìn tí a ti gba ìmọ̀ tó péye nípa òtítọ́,+ kò tún sí ẹbọ kankan fún ẹ̀ṣẹ̀ mọ́,+ 27  àfi ká máa fi ìbẹ̀rù retí ìdájọ́ àti ìbínú tó le, tó sì máa jó àwọn tó ń ṣàtakò run.+ 28  A kì í ṣàánú ẹnikẹ́ni tí kò bá ka Òfin Mósè sí, ó máa kú tí ẹni méjì tàbí mẹ́ta bá ti jẹ́rìí sí i.+ 29  Báwo lẹ ṣe wá rò pé ó yẹ kí ìyà tó máa jẹ ẹni tó tẹ Ọmọ Ọlọ́run mọ́lẹ̀ pọ̀ tó, tó ti ka ẹ̀jẹ̀ májẹ̀mú+ tí a fi sọ ọ́ di mímọ́ sí nǹkan yẹpẹrẹ, tó sì fi ìwà àfojúdi mú ẹ̀mí inú rere àìlẹ́tọ̀ọ́sí bínú?+ 30  Torí a mọ Ẹni tó sọ pé: “Tèmi ni ẹ̀san; màá gbẹ̀san.” Àti pé: “Jèhófà* máa dá ẹjọ́ àwọn èèyàn rẹ̀.”+ 31  Ohun tó ń bani lẹ́rù ló jẹ́ láti kó sí ọwọ́ Ọlọ́run alààyè. 32  Àmọ́, ẹ máa rántí àwọn ọjọ́ àtijọ́, tí ẹ fara da ìjàkadì ńlá pẹ̀lú ìyà, lẹ́yìn tí a là yín lóye.+ 33  Nígbà míì, wọ́n máa ń tú yín síta gbangba* fún ẹ̀gàn àti ìpọ́njú, nígbà míì sì rèé, ẹ máa ń ṣe alábàápín pẹ̀lú* àwọn tí irú nǹkan bẹ́ẹ̀ ṣẹlẹ̀ sí. 34  Torí ẹ bá àwọn tó wà ní ẹ̀wọ̀n kẹ́dùn, ẹ sì fi ayọ̀ gba bí wọ́n ṣe kó ẹrù yín,+ torí ẹ mọ̀ pé ẹ̀yin fúnra yín ní ohun ìní tó dáa jù, tó sì wà pẹ́ títí.+ 35  Torí náà, ẹ má sọ ìgboyà yín* nù, èyí tí a máa torí rẹ̀ fún yín ní èrè tó kún rẹ́rẹ́.+ 36  Nítorí ẹ nílò ìfaradà,+ pé lẹ́yìn tí ẹ ti ṣe ìfẹ́ Ọlọ́run, kí ẹ lè rí ohun tí ó ṣèlérí náà gbà. 37  Torí ní “ìgbà díẹ̀ sí i”+ àti pé “ẹni tó ń bọ̀ máa dé, kò sì ní pẹ́.”+ 38  “Àmọ́ ìgbàgbọ́ yóò mú kí olódodo mi wà láàyè”+ àti pé “tó bá fà sẹ́yìn, inú mi* ò ní dùn sí i.”+ 39  Ní báyìí, a kì í ṣe irú àwọn tó ń fà sẹ́yìn sí ìparun,+ àmọ́ irú àwọn tó ní ìgbàgbọ́ kí a lè dá ẹ̀mí* wa sí.

Àlàyé Ìsàlẹ̀ Ìwé

Tàbí kó jẹ́, “àwọn èèyàn kò lè.”
Ní Grk., “àkájọ ìwé inú ìwé náà.”
Tàbí “iṣẹ́ ìsìn gbogbo èèyàn.”
Tàbí “ìdánilójú.”
Ní Grk., “tó fi lọ́lẹ̀.”
Ní Grk., “ká di ìkéde ìrètí wa ní gbangba mú ṣinṣin.”
Tàbí “kí ọ̀rọ̀ ara wa jẹ wá lógún; kíyè sí ara wa.”
Tàbí “máa mú kó wù wá; máa ru ara wa sókè.”
Ní Grk., “síta bíi ti gbọ̀ngàn ìwòran.”
Tàbí “ẹ máa ń dúró ti.”
Ní Grk., “òmìnira yín láti sọ̀rọ̀ fàlàlà.”
Tàbí “ọkàn mi.”
Tàbí “ọkàn.”