Sí Àwọn Hébérù 13:1-25
13 Ẹ túbọ̀ máa ní ìfẹ́ ará.+
2 Ẹ má gbàgbé láti máa ṣe aájò àlejò,*+ torí àwọn kan ti tipa bẹ́ẹ̀ ṣe àwọn áńgẹ́lì lálejò láìmọ̀.+
3 Ẹ máa rántí àwọn tó wà nínú ẹ̀wọ̀n,*+ bí ẹni pé ẹ jọ wà lẹ́wọ̀n+ àti àwọn tí wọ́n ń fìyà jẹ, torí pé ẹ̀yin fúnra yín náà wà nínú ara.*
4 Kí ìgbéyàwó ní ọlá láàárín gbogbo èèyàn, kí ibùsùn ìgbéyàwó má sì ní ẹ̀gbin,+ torí Ọlọ́run máa dá àwọn oníṣekúṣe* àti àwọn alágbèrè lẹ́jọ́.+
5 Ẹ yẹra fún ìfẹ́ owó nínú ìgbésí ayé yín,+ bí ẹ ṣe ń jẹ́ kí àwọn nǹkan tó wà báyìí tẹ́ yín lọ́rùn.+ Torí ó ti sọ pé: “Mi ò ní fi ọ́ sílẹ̀ láé, mi ò sì ní pa ọ́ tì láé.”+
6 Ká lè nígboyà gidigidi, ká sì sọ pé: “Jèhófà* ni olùrànlọ́wọ́ mi; mi ò ní bẹ̀rù. Kí ni èèyàn lè fi mí ṣe?”+
7 Ẹ máa rántí àwọn tó ń mú ipò iwájú láàárín yín,+ tí wọ́n ti sọ ọ̀rọ̀ Ọlọ́run fún yín, bí ẹ sì ṣe ń ṣàyẹ̀wò bí ìwà wọn ṣe rí, ẹ máa tẹ̀ lé àpẹẹrẹ ìgbàgbọ́ wọn.+
8 Ọ̀kan náà ni Jésù Kristi lánàá, lónìí àti títí láé.
9 Ẹ má ṣe jẹ́ kí wọ́n fi oríṣiríṣi ẹ̀kọ́ àtàwọn ẹ̀kọ́ tó ṣàjèjì ṣì yín lọ́nà, torí ó sàn kí inú rere àìlẹ́tọ̀ọ́sí fún ọkàn lókun ju oúnjẹ* lọ, èyí tí kì í ṣàǹfààní fún àwọn tó gbà lọ́kàn.+
10 A ní pẹpẹ kan, tí àwọn tó ń ṣe iṣẹ́ ìsìn mímọ́ níbi àgọ́ kò láṣẹ láti jẹ níbẹ̀.+
11 Torí wọ́n máa ń sun ara àwọn ẹran tí àlùfáà àgbà máa ń mú ẹ̀jẹ̀ wọn wọnú ibi mímọ́ láti fi rú ẹbọ ẹ̀ṣẹ̀ lẹ́yìn ibùdó.+
12 Torí náà, Jésù náà jìyà lẹ́yìn odi* ìlú+ kó lè fi ẹ̀jẹ̀ ara rẹ̀ sọ àwọn èèyàn di mímọ́.+
13 Tó bá rí bẹ́ẹ̀, ẹ jẹ́ ká lọ bá a lẹ́yìn ibùdó, ká ru ẹ̀gàn tó rù,+
14 torí a ò ní ìlú kan níbí tó ṣì máa wà, àmọ́ à ń fi gbogbo ọkàn wá èyí tó ń bọ̀.+
15 Ẹ jẹ́ ká máa rú ẹbọ ìyìn sí Ọlọ́run nípasẹ̀ rẹ̀ nígbà gbogbo,+ ìyẹn èso ètè wa+ tó ń kéde orúkọ rẹ̀ ní gbangba.+
16 Bákan náà, ẹ má gbàgbé láti máa ṣe rere, kí ẹ sì máa pín ohun tí ẹ ní pẹ̀lú àwọn ẹlòmíì,+ torí inú Ọlọ́run máa ń dùn gan-an sí irú àwọn ẹbọ bẹ́ẹ̀.+
17 Ẹ máa ṣègbọràn sí àwọn tó ń mú ipò iwájú láàárín yín,+ kí ẹ sì máa tẹrí ba,+ torí wọ́n ń ṣọ́ ẹ̀ṣọ́ lórí yín* bí àwọn tó máa jíhìn,+ kí wọ́n lè ṣe é tayọ̀tayọ̀, kì í ṣe pẹ̀lú ẹ̀dùn ọkàn, torí èyí máa pa yín lára.
18 Ẹ túbọ̀ máa gbàdúrà fún wa, torí ó dá wa lójú pé a ní ẹ̀rí ọkàn rere,* bó ṣe ń wù wá láti jẹ́ olóòótọ́ nínú ohun gbogbo.+
19 Àmọ́ ní pàtàkì, mo rọ̀ yín pé kí ẹ máa gbàdúrà, kí n lè tètè pa dà sọ́dọ̀ yín.
20 Kí Ọlọ́run àlàáfíà, tó jí Jésù Olúwa wa dìde, olùṣọ́ àgùntàn ńlá+ fún àwọn àgùntàn, pẹ̀lú ẹ̀jẹ̀ májẹ̀mú àìnípẹ̀kun,
21 fi gbogbo ohun rere mú yín gbára dì láti ṣe ìfẹ́ rẹ̀, kí ó máa ṣe ohun tó dáa gan-an nínú wa lójú rẹ̀ nípasẹ̀ Jésù Kristi, ẹni tí ògo jẹ́ tiẹ̀ títí láé àti láéláé. Àmín.
22 Ẹ̀yin ará, mò ń rọ̀ yín pé kí ẹ fara balẹ̀ tẹ́tí sí ọ̀rọ̀ ìṣírí yìí, torí lẹ́tà kúkúrú ni mo kọ sí yín.
23 Mo fẹ́ kí ẹ mọ̀ pé wọ́n ti tú Tímótì arákùnrin wa sílẹ̀. Tó bá tètè dé, a jọ máa wá nígbà tí mo bá fẹ́ wá rí yín.
24 Ẹ bá mi kí gbogbo àwọn tó ń mú ipò iwájú láàárín yín àti gbogbo àwọn ẹni mímọ́. Àwọn tó wà ní Ítálì+ kí yín.
25 Kí inú rere àìlẹ́tọ̀ọ́sí wà pẹ̀lú gbogbo yín.
Àlàyé Ìsàlẹ̀ Ìwé
^ Tàbí “ṣe inúure sí àwọn àjèjì.”
^ Ní Grk., “àwọn tí a dè; àwọn tó wà nínú ìdè.”
^ Tàbí kó jẹ́, “bí ẹni pé ẹ jọ ń jìyà.”
^ Wo Àlàyé Ọ̀rọ̀, “Ìṣekúṣe.”
^ Ìyẹn, àwọn òfin nípa oúnjẹ.
^ Tàbí “nítòsí ẹnubodè.”
^ Tàbí “ọkàn yín.”
^ Tàbí “aláìlábòsí.”