Sí Àwọn Hébérù 6:1-20
6 Torí náà, ní báyìí tí a ti kọjá àwọn ẹ̀kọ́ àkọ́bẹ̀rẹ̀+ nípa Kristi, ẹ jẹ́ ká tẹ̀ síwájú, ká dàgbà nípa tẹ̀mí,+ ká má ṣe tún máa fi ìpìlẹ̀ lélẹ̀ mọ́, ìyẹn ìrònúpìwàdà kúrò nínú àwọn òkú iṣẹ́ àti ìgbàgbọ́ nínú Ọlọ́run,
2 ẹ̀kọ́ nípa ìrìbọmi àti gbígbé ọwọ́ léni,+ àjíǹde àwọn òkú+ àti ìdájọ́ àìnípẹ̀kun.
3 A sì máa ṣe èyí, tó bá jẹ́ pé ohun tí Ọlọ́run fẹ́ ká ṣe nìyẹn lóòótọ́.
4 Torí ní ti àwọn tí a ti là lóye rí,+ tí wọ́n ti tọ́ ẹ̀bùn ọ̀fẹ́ ti ọ̀run wò, tí wọ́n sì ti ní ìpín nínú ẹ̀mí mímọ́,
5 tí wọ́n ti tọ́ ọ̀rọ̀ Ọlọ́run tó jẹ́ ọ̀rọ̀ àtàtà wò àti agbára ètò àwọn nǹkan tó ń bọ̀,*
6 àmọ́ tí wọ́n yẹsẹ̀,+ kò ṣeé ṣe láti tún mú wọn sọ jí kí wọ́n lè ronú pìwà dà, torí ṣe ni wọ́n tún kan Ọmọ Ọlọ́run mọ́gi* fún ara wọn, wọ́n sì dójú tì í ní gbangba.+
7 Ilẹ̀ máa ń gba ìbùkún Ọlọ́run tó bá fa omi òjò tó ń rọ̀ sí i déédéé mu, ó sì máa mú ewéko jáde, èyí tó máa wúlò fún àwọn tí wọ́n ń ro ó fún.
8 Àmọ́ tó bá jẹ́ ẹ̀gún àti òṣùṣú ló ń mú jáde, a máa pa á tì, ó sì ṣeé ṣe ká gégùn-ún fún un, a sì máa dáná sun ún nígbẹ̀yìn-gbẹ́yín.
9 Àmọ́ ní tiyín, ẹ̀yin ará mi ọ̀wọ́n, bí a tiẹ̀ ń sọ̀rọ̀ lọ́nà yìí, àwọn ohun tó dáa jù ló dá wa lójú, àwọn ohun tó jẹ mọ́ ìgbàlà.
10 Torí Ọlọ́run kì í ṣe aláìṣòdodo tó fi máa gbàgbé iṣẹ́ yín àti ìfẹ́ tí ẹ fi hàn fún orúkọ rẹ̀ + bí ẹ ṣe ń ṣe ìránṣẹ́ fún àwọn ẹni mímọ́, tí ẹ sì ń bá a lọ láti ṣe ìránṣẹ́.
11 Àmọ́, ó wù wá kí ẹnì kọ̀ọ̀kan yín máa ṣiṣẹ́ kára bẹ́ẹ̀, kí ìrètí náà lè dá yín lójú+ ní ẹ̀kúnrẹ́rẹ́ títí dé òpin,+
12 kí ẹ má bàa máa lọ́ra,+ àmọ́ kí ẹ lè máa tẹ̀ lé àpẹẹrẹ àwọn tí ìgbàgbọ́ àti sùúrù mú kí wọ́n jogún àwọn ìlérí náà.
13 Torí nígbà tí Ọlọ́run ṣe ìlérí fún Ábúráhámù, ó fi ara rẹ̀ búra, nígbà tó jẹ́ pé kò sí ẹlòmíì tó tóbi jù ú lọ tó lè fi búra,+
14 ó sọ pé: “Ó dájú pé màá bù kún ọ, ó sì dájú pé màá mú kí o di púpọ̀.”+
15 Torí náà, lẹ́yìn tí Ábúráhámù ní sùúrù, ó rí ìlérí yìí gbà.
16 Torí àwọn èèyàn máa ń fi ẹni tó tóbi jù wọ́n lọ búra, ìbúra wọn sì máa ń fòpin sí gbogbo awuyewuye, torí ó ń fìdí ọ̀rọ̀ wọn múlẹ̀ lábẹ́ òfin.+
17 Lọ́nà kan náà, nígbà tí Ọlọ́run pinnu láti jẹ́ kó túbọ̀ ṣe kedere sí àwọn ajogún ìlérí+ náà pé ohun tí òun ní lọ́kàn* kò lè yí pa dà, ó búra* kó lè fìdí rẹ̀ múlẹ̀,
18 kó lè jẹ́ pé nípasẹ̀ àwọn nǹkan méjì tí kò lè yí pa dà, tí Ọlọ́run ò ti lè parọ́,+ àwa tí a ti sá sí ibi ààbò máa lè rí ìṣírí tó lágbára gbà láti di ìrètí tó wà níwájú wa mú ṣinṣin.
19 A ní ìrètí yìí+ bí ìdákọ̀ró fún ọkàn,* ó dájú, ó fìdí múlẹ̀, ó sì wọlé sẹ́yìn aṣọ ìdábùú,+
20 níbi tí aṣíwájú kan ti wọ̀ nítorí wa, ìyẹn Jésù,+ ẹni tó ti di àlùfáà àgbà ní ọ̀nà ti Melikisédékì títí láé.+
Àlàyé Ìsàlẹ̀ Ìwé
^ Tàbí “àsìkò tó ń bọ̀.” Wo Àlàyé Ọ̀rọ̀.
^ Tàbí “mọ́ òpó igi.” Wo Àlàyé Ọ̀rọ̀.
^ Tàbí “pé ìpinnu òun.”
^ Tàbí “ó mú ìbúra kan wọ̀ ọ́.” Ní Grk., “ó fi ìbúra kan ṣe alárinà.”
^ Tàbí “fún ẹ̀mí wa.”