Hósíà 10:1-15
10 “Ísírẹ́lì jẹ́ igi àjàrà tí kò dáa* tó ń so èso.+
Bí èso rẹ̀ ṣe ń pọ̀ sí i, bẹ́ẹ̀ ló ń mú kí àwọn pẹpẹ rẹ̀ pọ̀ sí i;+Bí ilẹ̀ rẹ̀ ṣe ń méso jáde, bẹ́ẹ̀ ló ń mú kí àwọn ọwọ̀n òrìṣà rẹ̀ dára sí i.+
2 Àgàbàgebè* kún inú ọkàn wọn;Ní báyìí, wọ́n á jẹ̀bi.
Ẹnì kan wà tó máa fọ́ àwọn pẹpẹ wọn, tó sì máa wó àwọn òpó wọn.
3 Wọ́n á sọ pé, ‘Torí a kò bẹ̀rù Jèhófà ni a kò fi ní ọba.+
Kí ni ọba lè ṣe fún wa?’
4 Wọ́n ń sọ ọ̀rọ̀ asán, wọ́n ń búra èké,+ wọ́n sì ń dá májẹ̀mú;Torí náà, ìdájọ́ wọn dà bí ewéko onímájèlé tó hù jáde láàárín àwọn ebè inú oko.+
5 Ẹ̀rù máa ba àwọn tó ń gbé ní Samáríà torí òrìṣà ọmọ màlúù tó wà ní Bẹti-áfénì.+
Àwọn èèyàn rẹ̀ máa ṣọ̀fọ̀ rẹ̀,Bẹ́ẹ̀ ni àwọn àlùfáà ọlọ́run àjèjì ibẹ̀, tó máa ń yọ̀ lórí rẹ̀ àti ògo rẹ̀, máa ṣọ̀fọ̀,Nítorí pé a ó mú un kúrò lọ́dọ̀ wọn lọ sí ìgbèkùn.
6 A ó mú un wá sí Ásíríà, láti fi ta ọba ńlá lọ́rẹ.+
Ojú á ti Éfúrémù,Ìtìjú á sì bá Ísírẹ́lì nítorí ìmọ̀ràn tó tẹ̀ lé.+
7 Ó dájú pé Samáríà àti ọba rẹ̀ máa pa run,*+Bí ẹ̀ka igi tó dá gbáú sí ojú omi.
8 Àwọn ibi gíga Bẹti-áfénì+ tó jẹ́ ẹ̀ṣẹ̀ Ísírẹ́lì,+ máa pa run pátápátá.+
Ẹ̀gún àti òṣùṣú yóò hù jáde lórí pẹpẹ wọn.+
Àwọn èèyàn yóò sọ fún àwọn òkè ńlá pé, ‘Ẹ bò wá mọ́lẹ̀!’
Wọ́n á sì sọ fún àwọn òkè kéékèèké pé, ‘Ẹ wó lù wá!’+
9 Láti ìgbà àwọn ará Gíbíà ni o ti ṣẹ̀,+ ìwọ Ísírẹ́lì.
Síbẹ̀, ìwọ kò jáwọ́.
Ogun kò pa àwọn aláìṣòdodo tó wà ní Gíbíà run pátápátá.
10 Màá bá wọn wí nígbà tí mo bá fẹ́.
Àwọn èèyàn á sì pé lé wọn lórí,Nígbà tí mo bá so wọ́n mọ́ àṣìṣe wọn méjèèjì.*
11 “Éfúrémù jẹ́ abo ọmọ màlúù tí a fi iṣẹ́ kọ́, tó fẹ́ràn láti máa pa ọkà,Torí náà, mo dá ọrùn rẹ̀ tó dáa sí.
Ní báyìí, màá mú kí ẹnì kan gun* Éfúrémù.+
Júdà á túlẹ̀; Jékọ́bù á fọ́ ògúlùtu fún un.
12 Ẹ fúnrúgbìn òdodo, kí ẹ sì kórè ìfẹ́ tí kì í yẹ̀.
Ẹ tú ilẹ̀ tó dáa fún ọ̀gbìn,+Nígbà tí àkókò ṣì wà láti wá Jèhófà,+Títí yóò fi wá, tí yóò sì kọ́ yín nínú òdodo.+
13 Àmọ́, ẹ ti túlẹ̀ ìwà burúkú,Ẹ ti kórè àìṣòdodo,+Ẹ sì ti jẹ èso ẹ̀tàn;Nítorí ẹ ti gbẹ́kẹ̀ lé ọ̀nà yínÀti àwọn jagunjagun yín.
14 Ariwo ogun máa sọ láàárín àwọn èèyàn rẹ,Gbogbo ìlú olódi rẹ á sì pa run,+Bí ìgbà tí Ṣálímánì pa ilé Áríbélì run,Ní ọjọ́ ogun tí a fọ́ àwọn ìyá mọ́lẹ̀ lẹ́gbẹ̀ẹ́ àwọn ọmọ wọn.
15 Ohun tí a ó ṣe sí ọ nìyí, ìwọ Bẹ́tẹ́lì,+ nítorí ìwà búburú rẹ tó bùáyà.
Ní àfẹ̀mọ́jú, ó dájú pé a ó pa ọba Ísírẹ́lì.”*+
Àlàyé Ìsàlẹ̀ Ìwé
^ Tàbí kó jẹ́, “tó ń gbalẹ̀.”
^ Tàbí “Ẹ̀tàn.”
^ Ní Héb., “ni a ó pa lẹ́nu mọ́.”
^ Ìyẹn, nígbà tí wọ́n bá ru ìyà wọn bí àjàgà.
^ Tàbí “fi ìjánu sí.”
^ Ní Héb., “pa ọba Ísírẹ́lì lẹ́nu mọ́.”