Hósíà 11:1-12
11 “Nígbà tí Ísírẹ́lì wà ní ọmọdé, mo nífẹ̀ẹ́ rẹ̀,+Láti Íjíbítì ni mo sì ti pe ọmọkùnrin mi.+
2 Bí wọ́n* ti ń pe àwọn èèyàn Ísírẹ́lì,Bẹ́ẹ̀ ni wọ́n ń sá fún wọn.+
Àwọn ère Báálì ni wọ́n ń rúbọ sí+Wọ́n sì ń rúbọ sí àwọn ère gbígbẹ́.+
3 Bẹ́ẹ̀ èmi ni mo kọ́ Éfúrémù ní ìrìn,+ tí mo gbé wọn sí apá mi;+Síbẹ̀ wọn ò gbà pé mo ti mú wọn lára dá.
4 Mo fi okùn inú rere* àti okùn ìfẹ́ fà wọ́n mọ́ra;+Mo sì dà bí ẹni tó ń yọ àjàgà kúrò ní ọrùn* wọn,Lẹ́sọ̀lẹsọ̀ sì ni mo gbé oúnjẹ wá fún ẹnì kọ̀ọ̀kan.
5 Wọn ò ní pa dà sí ilẹ̀ Íjíbítì, Ásíríà ló sì máa jẹ́ ọba wọn,+Torí pé wọ́n kọ̀ láti pa dà sọ́dọ̀ mi.+
6 Idà á máa jù fìrìfìrì ní àwọn ìlú rẹ̀+Yóò run ọ̀pá ìdábùú rẹ̀, yóò sì pa àwọn ará ìlú rẹ̀ run nítorí ètekéte wọn.+
7 Àwọn èèyàn mi ti pinnu láti jẹ́ aláìṣòótọ́ sí mi.+
Bó tilẹ̀ jẹ́ pé wọ́n pè wọ́n sókè,* kò sí ẹnì kankan tó dìde.
8 Ṣé ó yẹ kí n yọwọ́ lọ́rọ̀ rẹ, ìwọ Éfúrémù?+
Ṣé ó yẹ kí n fà ọ́ lé ọ̀tá lọ́wọ́, ìwọ Ísírẹ́lì?
Ṣé ó yẹ kí n ṣe ọ́ bí Ádímà?
Ṣé ó yẹ kí n ṣe ọ́ bíi Sébóíímù?+
Mo ti yí ọkàn mi pa dà;Lẹ́sẹ̀ kan náà, inú mi ti yọ́* sí wọn.+
9 Mi ò ní tú ìbínú mi tó ń jó fòfò jáde.
Mi ò ní pa Éfúrémù run mọ́,+Nítorí Ọlọ́run ni mí, èmi kì í ṣe èèyàn,Ẹni Mímọ́ tó wà láàárín rẹ;Mi ò sì ní fi ìbínú wá sọ́dọ̀ rẹ.
10 Wọ́n á máa tẹ̀ lé Jèhófà, á sì ké ramúramù bíi kìnnìún;+Nígbà tó bá ké ramúramù, àwọn ọmọ rẹ̀ á gbọ̀n jìnnìjìnnì wá láti ìwọ̀ oòrùn.+
11 Wọ́n á gbọ̀n jìnnìjìnnì bí ẹyẹ nígbà tí wọ́n bá jáde kúrò ní ÍjíbítìÀti bí àdàbà tí wọ́n bá kúrò ní ilẹ̀ Ásíríà;+Màá sì fìdí wọn kalẹ̀ ní ilé wọn,” ni Jèhófà wí.+
12 “Irọ́ ni Éfúrémù ń pa fún mi ṣáá,Ẹ̀tàn sì ni ilé Ísírẹ́lì ń ṣe sí mi nígbà gbogbo.+
Àmọ́ Júdà ṣì ń bá Ọlọ́run rìn,Ó sì jẹ́ olóòótọ́ sí Ẹni Mímọ́ Jù Lọ.”+
Àlàyé Ìsàlẹ̀ Ìwé
^ Ìyẹn, àwọn wòlíì àti àwọn míì tí Ọlọ́run rán láti tọ́ Ísírẹ́lì sọ́nà.
^ Ní Héb., “okùn èèyàn.”
^ Ní Héb., “ẹ̀rẹ̀kẹ́.”
^ Ìyẹn, ìjọsìn tó ga.
^ Ní Héb., “ìyọ́nú mi ti gbóná.”