Hósíà 4:1-19
4 Ẹ gbọ́ ọ̀rọ̀ Jèhófà, ẹ̀yin èèyàn Ísírẹ́lì,Jèhófà yóò pe àwọn tó ń gbé ilẹ̀ náà lẹ́jọ́,+Nítorí kò sí òtítọ́ tàbí ìfẹ́ tí kì í yẹ̀ ní ilẹ̀ náà, bẹ́ẹ̀ ni kò sí ìmọ̀ Ọlọ́run.+
2 Ìbúra èké, irọ́ pípa+ àti ìpànìyàn+Olè jíjà àti àgbèrè+ ti gbilẹ̀,Ìtàjẹ̀sílẹ̀ ń gorí ìtàjẹ̀sílẹ̀.+
3 Ìdí nìyẹn tí ilẹ̀ náà á fi ṣọ̀fọ̀+Tí gbogbo àwọn tó ń gbé orí rẹ̀ á sì gbẹ dà nù;Àwọn ẹran inú igbó àti ẹyẹ ojú ọ̀run,Àní títí kan àwọn ẹja inú òkun, yóò ṣègbé.
4 “Àmọ́, kí ẹnikẹ́ni má ṣe bá wọn jiyàn tàbí kó bá wọn wí,+Torí àwọn èèyàn rẹ dà bí àwọn tó ń bá àlùfáà jiyàn.+
5 Torí náà, wọ́n á fẹsẹ̀ kọ ní ọ̀sán gangan,Wòlíì á sì fẹsẹ̀ kọ pẹ̀lú wọn, bíi pé alẹ́ ni.
Màá sì pa ìyá wọn lẹ́nu mọ́.*
6 A ó pa àwọn èèyàn mi lẹ́nu mọ́,* torí pé wọn kò ní ìmọ̀.
Nítorí pé wọ́n ti kọ̀ láti mọ̀ mí,+Èmi náà á kọ̀ wọ́n pé kí wọ́n má ṣe àlùfáà mi mọ́;Àti nítorí pé wọ́n gbàgbé òfin* Ọlọ́run wọn,+Èmi náà á gbàgbé àwọn ọmọ wọn.
7 Bí wọ́n ṣe ń pọ̀ sí i, bẹ́ẹ̀ ni wọ́n ṣe túbọ̀ ń ṣẹ̀ mí.+
Màá sọ ògo wọn di ìtìjú.*
8 Wọ́n* ń bọ́ ara wọn nípasẹ̀ ẹ̀ṣẹ̀ àwọn èèyàn mi,Àṣìṣe wọn ni wọ́n sì ń fẹ́.*
9 Bó ṣe rí fún àwọn èèyàn náà ló ṣe máa rí fún àwọn àlùfáà;Màá pè wọ́n wá jíhìn nítorí ìwà wọn,Màá sì san èrè iṣẹ́ wọn pa dà fún wọn.+
10 Wọ́n á jẹun, ṣùgbọ́n wọn kò ní yó.+
Wọ́n á di oníṣekúṣe,* síbẹ̀ wọn kò ní rí ọmọ bí,+Torí pé wọn kò bọ̀wọ̀ fún Jèhófà.
11 Ìṣekúṣe* àti wáìnì àti wáìnì tuntunMáa ń mú èrò rere kúrò lọ́kàn ẹni.*+
12 Àwọn èèyàn mi ń wádìí lọ́dọ̀ àwọn òrìṣà tí wọ́n fi igi ṣe,Wọ́n ń ṣe ohun tí ọ̀pá* wọn sọ fún wọn;Nítorí pé ẹ̀mí ìṣekúṣe* ti mú kí wọ́n ṣìnà,Ìṣekúṣe* wọn ni kò jẹ́ kí wọ́n tẹrí ba fún Ọlọ́run wọn.
13 Orí àwọn òkè ńlá ni wọ́n ti ń rúbọ,+Orí àwọn òkè kéékèèké ni wọ́n sì ti ń mú àwọn ẹbọ rú èéfín,Lábẹ́ àwọn igi ràgàjì* àti àwọn igi tórásì àti onírúurú igi ńlá,+Torí pé ibòji àwọn igi náà dára.
Ìdí nìyẹn tí àwọn ọmọbìnrin yín fi ń ṣe ìṣekúṣe*Tí aya àwọn ọmọ yín sì ń ṣe àgbèrè.
14 Èmi kì yóò mú kí àwọn ọmọbìnrin yín jíhìn torí pé wọ́n ṣe ìṣekúṣe*Àti aya àwọn ọmọ yín torí pé wọ́n ṣe àgbèrè.
Nítorí pé àwọn ọkùnrin yín ń bá àwọn aṣẹ́wó kẹ́gbẹ́Wọ́n sì ń rúbọ pẹ̀lú àwọn aṣẹ́wó tẹ́ńpìlì;Àwọn èèyàn tí kò lóye+ yìí yóò pa run.
15 Bí o tilẹ̀ ń ṣe ìṣekúṣe,* ìwọ Ísírẹ́lì,+Má ṣe jẹ́ kí Júdà jẹ̀bi.+
Má ṣe wá sí Gílígálì+ tàbí Bẹti-áfénì,+Má sì ṣe búra pé, ‘Bí Jèhófà ti wà láàyè!’+
16 Nítorí Ísírẹ́lì ti di alágídí bíi màlúù tó lágídí.+
Ǹjẹ́ Jèhófà yóò ṣe olùṣọ́ àgùntàn wọn bí ọmọ àgbò nínú ibi ìjẹko tó tẹ́jú?*
17 Éfúrémù ti dara pọ̀ mọ́ àwọn òrìṣà.+
Ẹ fi í sílẹ̀!
18 Nígbà tí ọtí bíà wọn* tán,Wọ́n di oníṣekúṣe.*
Àwọn alákòóso* rẹ̀ sì nífẹ̀ẹ́ àbùkù.+
19 Afẹ́fẹ́ yóò gbá a lọ,Àwọn ẹbọ wọn yóò sì kó ìtìjú bá wọn.”
Àlàyé Ìsàlẹ̀ Ìwé
^ Tàbí “pa ìyá wọn run.”
^ Tàbí “pa àwọn èèyàn mi run.”
^ Tàbí “ìtọ́ni.”
^ Tàbí kó jẹ́, “Wọ́n ti fi ìtìjú rọ́pò ògo mi.”
^ Ìyẹn, àwọn àlùfáà.
^ Tàbí “gbé ọkàn sókè sí.” Wo Àlàyé Ọ̀rọ̀, “Ọkàn.”
^ Tàbí “oníṣekúṣe paraku; aṣẹ́wó.”
^ Ní Héb., “ń mú ọkàn kúrò.”
^ Tàbí “Iṣẹ́ aṣẹ́wó.”
^ Tàbí “ọ̀pá woṣẹ́woṣẹ́.”
^ Tàbí “iṣẹ́ aṣẹ́wó.”
^ Tàbí “Iṣẹ́ aṣẹ́wó.”
^ Tàbí “igi óákù.”
^ Tàbí “iṣẹ́ aṣẹ́wó.”
^ Tàbí “iṣẹ́ aṣẹ́wó.”
^ Tàbí “iṣẹ́ aṣẹ́wó.”
^ Ní Héb., “ibi aláyè gbígbòòrò?”
^ Tàbí “bíà tí wọ́n fi wíìtì ṣe.”
^ Tàbí “oníṣekúṣe paraku; aṣẹ́wó.”
^ Ní Héb., “Àwọn apata.”