Hósíà 5:1-15

  • Éfúrémù àti Júdà gba ìdájọ́ (1-15)

5  “Ẹ gbọ́ èyí, ẹ̀yin àlùfáà,+Ẹ fiyè sí i, ilé Ísírẹ́lì,Fetí sílẹ̀, ilé ọba, Torí ìdájọ́ yìí kàn yín;Torí pé ẹ jẹ́ pańpẹ́ fún MísípàẸ sì jẹ́ àwọ̀n tí ó bo Tábórì.+   Àwọn ọlọ̀tẹ̀* ti lọ jìnnà nínú* ìpakúpa,Mo sì ń kìlọ̀ fún gbogbo wọn.*   Mo mọ Éfúrémù,Ísírẹ́lì kì í sì í ṣe àjèjì sí mi. Ní báyìí, ìwọ Éfúrémù, o ti ṣe ìṣekúṣe;*Ísírẹ́lì sì ti sọ ara rẹ̀ di ẹlẹ́gbin.+   Ìṣe wọn kò jẹ́ kí wọ́n pa dà sọ́dọ̀ Ọlọ́run wọn,Torí ẹ̀mí ìṣekúṣe* wà ní àárín wọn;+Wọn ò sì ka Jèhófà sí.   Ìwà Ísírẹ́lì ti jẹ́rìí sí i* pé ó gbéra ga;+Àṣìṣe Ísírẹ́lì àti Éfúrémù ti mú kí wọ́n kọsẹ̀,Júdà sì ti kọsẹ̀ pẹ̀lú wọn.+   Agbo ẹran wọn àti ọ̀wọ́ ẹran wọn ni wọ́n fi ń wá Jèhófà,Ṣùgbọ́n wọn kò rí i. Ó ti kúrò lọ́dọ̀ wọn.+   Wọ́n ti hùwà àìṣòótọ́ sí Jèhófà,+Torí wọ́n ti bí àwọn ọmọ àjèjì. Ní báyìí, kò ní ju oṣù kan lọ tí àwọn àti ìpín* wọn á fi pa run.   Ẹ fun ìwo+ ní Gíbíà àti kàkàkí ní Rámà! + Ẹ kígbe ogun ní Bẹti-áfénì,+ a ó tẹ̀ lé ọ, ìwọ Bẹ́ńjámínì!   Éfúrémù, ìwọ yóò di ohun àríbẹ̀rù ní ọjọ́ ìjìyà.+ Mo ti sọ ohun tó dájú pé ó máa ṣẹlẹ̀ láàárín àwọn ẹ̀yà Ísírẹ́lì. 10  Àwọn olórí Júdà dà bí àwọn tó ń sún ààlà sẹ́yìn.+ Èmi yóò da ìbínú ńlá mi sórí wọn bí omi. 11  Éfúrémù rí ìdààmú, ó gba ìdájọ́ tó yẹ,Nítorí ó ti pinnu láti tẹ̀ lé ọ̀tá rẹ̀.+ 12  Torí náà, mo dà bí òólá* sí ÉfúrémùMo sì dà bí ìdíbàjẹ́ sí ilé Júdà. 13  Nígbà tí Éfúrémù rí i pé òun ń ṣàìsàn, tí Júdà sì rí i pé egbò wà lára òun,Éfúrémù lọ sí Ásíríà,+ ó sì ránṣẹ́ sí ọba ńlá. Ṣùgbọ́n kò lè mú un lára dá,Kò sì lè wo egbò rẹ̀ sàn. 14  Màá dà bí ọmọ kìnnìún sí ÉfúrémùÀti bíi kìnnìún* alágbára sí ilé Júdà. Èmi fúnra mi á fà wọ́n ya pẹ́rẹpẹ̀rẹ, màá sì lọ;+Màá gbé wọn lọ, kò sì sí ẹni tó máa gbà wọ́n sílẹ̀.+ 15  Màá lọ, màá sì pa dà sí ipò mi títí wọ́n á fi gba ìyà ẹ̀bi wọn,Nígbà náà, wọ́n á wá ojú rere* mi.+ Nígbà tí wọ́n bá wà nínú ìdààmú, wọ́n á wá mi.”+

Àlàyé Ìsàlẹ̀ Ìwé

Tàbí “Àwọn tó yapa.”
Tàbí “jingíri sínú.”
Tàbí “Màá bá gbogbo wọn wí.”
Tàbí “iṣẹ́ aṣẹ́wó.”
Tàbí “iṣẹ́ aṣẹ́wó.”
Ní Héb., “fi hàn lójú rẹ̀.”
Tàbí “ilẹ̀.”
Tàbí “kòkòrò.”
Tàbí “ọmọ kìnnìún tó tó ọdẹ ṣe (onígọ̀gọ̀).”
Ní Héb., “ojú.”