Jẹ́nẹ́sísì 10:1-32
10 Ìtàn àwọn ọmọ Nóà nìyí, Ṣémù,+ Hámù àti Jáfẹ́tì.
Wọ́n bí àwọn ọmọ lẹ́yìn Ìkún Omi.+
2 Àwọn ọmọ Jáfẹ́tì ni Gómérì,+ Mágọ́gù,+ Mádáì, Jáfánì, Túbálì,+ Méṣékì+ àti Tírásì.+
3 Àwọn ọmọ Gómérì ni Áṣíkénásì,+ Rífátì àti Tógámà.+
4 Àwọn ọmọ Jáfánì ni Élíṣáhì,+ Táṣíṣì,+ Kítímù+ àti Dódánímù.
5 Ọ̀dọ̀ wọn ni àwọn tó ń gbé àwọn erékùṣù ti tàn ká àwọn ilẹ̀ wọn, gẹ́gẹ́ bí èdè wọn, ìdílé wọn àti orílẹ̀-èdè wọn.
6 Àwọn ọmọ Hámù ni Kúṣì, Mísíráímù,+ Pútì+ àti Kénáánì.+
7 Àwọn ọmọ Kúṣì ni Sébà,+ Háfílà, Sábítà, Ráámà+ àti Sábítékà.
Àwọn ọmọ Ráámà sì ni Ṣébà àti Dédánì.
8 Kúṣì bí Nímírọ́dù. Òun ló kọ́kọ́ di alágbára ní ayé.
9 Ó di ọdẹ alágbára tó ń ta ko Jèhófà. Ìdí nìyẹn tí wọ́n fi máa ń sọ pé: “Bíi Nímírọ́dù ọdẹ alágbára tó ta ko Jèhófà.”
10 Ibi tí ìjọba rẹ̀ ti bẹ̀rẹ̀ ni* Bábélì,+ Érékì,+ Ákádì àti Kálínè, ní ilẹ̀ Ṣínárì.+
11 Láti ibẹ̀, ó lọ sí Ásíríà,+ ó sì kọ́ Nínéfè,+ Rehoboti-Írì, Kálà
12 àti Résénì, láàárín Nínéfè àti Kálà: Èyí ni ìlú ńlá náà.*
13 Mísíráímù bí Lúdímù,+ Ánámímù, Léhábímù, Náfítúhímù,+
14 Pátírúsímù,+ Kásílúhímù (ọ̀dọ̀ rẹ̀ ni àwọn Filísínì+ ti wá) àti Káfítórímù.+
15 Kénáánì bí Sídónì+ àkọ́bí rẹ̀ àti Hétì+
16 àti àwọn ará Jébúsì,+ àwọn Ámórì,+ àwọn Gẹ́gáṣì,
17 àwọn Hífì,+ àwọn Ákì, àwọn Sáínì,
18 àwọn Áfádì,+ àwọn Sémárì àti àwọn Hámátì.+ Lẹ́yìn náà, àwọn ìdílé àwọn ọmọ Kénáánì tàn káàkiri.
19 Ààlà àwọn ọmọ Kénáánì bẹ̀rẹ̀ láti Sídónì títí lọ dé Gérárì,+ nítòsí Gásà,+ títí lọ dé Sódómù, Gòmórà,+ Ádímà àti Sébóíímù,+ nítòsí Láṣà.
20 Àwọn ọmọ Hámù nìyí, bí wọ́n ṣe wà nínú ìdílé wọn, èdè wọn, ilẹ̀ wọn àti orílẹ̀-èdè wọn.
21 Ṣémù náà bímọ, òun ni baba ńlá gbogbo àwọn ọmọ Ébérì,+ òun sì ni arákùnrin Jáfẹ́tì tó jẹ́ ẹ̀gbọ́n pátápátá.*
22 Àwọn ọmọ Ṣémù ni Élámù,+ Áṣúrì,+ Ápákíṣádì,+ Lúdì àti Árámù.+
23 Àwọn ọmọ Árámù ni Úsì, Húlì, Gétérì àti Máṣì.
24 Ápákíṣádì bí Ṣélà,+ Ṣélà sì bí Ébérì.
25 Ọmọ méjì ni Ébérì bí. Ọ̀kan ń jẹ́ Pélégì,*+ torí pé ìgbà ayé rẹ̀ ni ayé* pín sọ́tọ̀ọ̀tọ̀. Orúkọ arákùnrin rẹ̀ ni Jókítánì.+
26 Jókítánì bí Álímódádì, Ṣéléfì, Hásámáfétì, Jérà,+
27 Hádórámù, Úsálì, Díkílà,
28 Óbálì, Ábímáélì, Ṣébà,
29 Ófírì,+ Háfílà àti Jóbábù; gbogbo wọn jẹ́ ọmọ Jókítánì.
30 Ibi tí wọ́n ń gbé bẹ̀rẹ̀ láti Méṣà títí lọ dé Séfárì, agbègbè olókè Ìlà Oòrùn.
31 Àwọn ọmọ Ṣémù nìyí bí wọ́n ṣe wà nínú ìdílé wọn, èdè wọn, ilẹ̀ wọn àti orílẹ̀-èdè wọn.+
32 Ìwọ̀nyí ni ìdílé àwọn ọmọ Nóà, bí wọ́n ṣe wà nínú ìdílé kálukú wọn àti orílẹ̀-èdè wọn. Ọ̀dọ̀ wọn ni àwọn orílẹ̀-èdè ti tàn káàkiri ayé lẹ́yìn Ìkún Omi.+
Àlàyé Ìsàlẹ̀ Ìwé
^ Tàbí “Àwọn ìlú tó kọ́kọ́ wà lábẹ́ ìjọba rẹ̀ ni.”
^ Tàbí kó jẹ́, “Wọ́n para pọ̀ di ìlú ńlá náà.”
^ Tàbí kó jẹ́, “òun sì ni ẹ̀gbọ́n Jáfẹ́tì.”
^ Ó túmọ̀ sí “Pín Sọ́tọ̀.”
^ Tàbí “aráyé.”